Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 15:1-27

15  Ní àkókò yẹn, Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin yìí sí Jèhófà, wọ́n sì sọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí:+ “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti di gbígbéga fíofío.+ Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó gbé sọ sínú òkun.+  Okun mi àti agbára ńlá mi ni Jáà,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìgbàlà mi.+ Èyí ni Ọlọ́run mi, èmi yóò sì gbé e lárugẹ;+ Ọlọ́run baba mi,+ èmi yóò sì gbé e ga sókè.+  Jèhófà jẹ́ akin lójú ogun.+ Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.+  Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ni ó sọ sínú òkun,+ Ààyò àwọn jagunjagun rẹ̀ sì ni a ti rì sínú Òkun Pupa.+  Omi ríru bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n;+ wọ́n lọ sísàlẹ̀ inú ibú bí òkúta.+  Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń fi ara rẹ̀ hàn ní alágbára nínú agbára ìlèṣe-nǹkan,+ Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú.+  Àti nínú ọ̀pọ̀ yanturu ìlọ́lájù rẹ ni ìwọ lè wó àwọn tí ó dìde sí ọ palẹ̀;+ Ìwọ rán ìbínú rẹ jíjófòfò jáde, ó jẹ wọ́n tán bí àgékù pòròpórò.+  Àti nípa èémí kan ṣoṣo láti ihò imú+ rẹ ni a wọ́ omi jọpọ̀; Wọ́n dúró jẹ́ẹ́ bí ìsédò àwọn ìkún omi; Omi ríru dì ní àárín òkun.  Ọ̀tá wí pé, ‘Èmi yóò lépa!+ Èmi yóò bá!+ Èmi yóò pín ohun ìfiṣèjẹ!+ Ọkàn mi yóò kún fún wọn! Èmi yóò fa idà mi yọ! Ọwọ́ mi yóò lé wọn lọ!’+ 10  Ìwọ fi èémí rẹ fẹ́ atẹ́gùn,+ òkun bò wọ́n;+ Wọ́n rì bí òjé nínú omi ọlọ́lá ńlá.+ 11  Jèhófà, ta ní dà bí rẹ láàárín àwọn ọlọ́run?+ Ta ní dà bí rẹ, tí o ń fi ara rẹ hàn ní alágbára ńlá ní ìjẹ́mímọ́?+ Ẹni tí ó yẹ kí a fi àwọn orin ìyìn+ bẹ̀rù,+ Ẹni tí ń ṣe àwọn ohun ìyanu.+ 12  Ìwọ na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,+ ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn mì.+ 13  Nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ìwọ ti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn tí ìwọ gbà sílẹ̀;+ Ìwọ nínú okun rẹ yóò darí wọn lọ sí ibi gbígbé rẹ mímọ́+ dájúdájú. 14  Àwọn ènìyàn yóò gbọ́,+ ṣìbáṣìbo yóò bá wọn;+ Ìroragógó ìbímọ+ yóò gbá àwọn olùgbé Filísíà mú. 15  Ní àkókò yẹn, àwọn séríkí Édómù ni a ó yọ lẹ́nu ní tòótọ́; Ní ti àwọn abàṣẹwàá Móábù, ìwárìrì yóò gbá wọn mú.+ Gbogbo olùgbé Kénáánì ni ọkàn wọn yóò domi ní tòótọ́.+ 16  Jìnnìjìnnì àti ìbẹ̀rùbojo yóò ṣubú tẹ̀ wọ́n.+ Nítorí títóbi apá rẹ, wọn yóò dúró sójú kan bí òkúta, Títí àwọn ènìyàn rẹ+ yóò fi kọjá lọ, Jèhófà, Títí àwọn ènìyàn tí o mú jáde+ yóò fi kọjá lọ.+ 17  Ìwọ yóò mú wọn wá, ìwọ yóò sì gbìn wọ́n sí òkè ńlá ogún rẹ,+ Ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀ fún ara rẹ láti máa gbé,+ Jèhófà, Ibùjọsìn+ kan tí ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Jèhófà. 18  Jèhófà yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+ 19  Nígbà tí àwọn ẹṣin Fáráò+ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣinjagun rẹ̀ wọnú òkun lọ,+ Nígbà náà ni Jèhófà mú omi òkun padà wá sórí wọn,+ Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ la àárín òkun kọjá.”+ 20  Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Áárónì,+ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìlù tanboríìnì ní ọwọ́;+ gbogbo obìnrin sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ pẹ̀lú rẹ̀ pẹ̀lú ìlù tanboríìnì, tijótijó.+ 21  Míríámù sì ń bá a lọ láti dáhùn padà sí àwọn ọkùnrin náà pé:+ “Kọrin sí Jèhófà,+ nítorí ó ti di gbígbéga fíofío.+ Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó gbé sọ sínú òkun.”+ 22  Lẹ́yìn náà, Mósè mú kí Ísírẹ́lì kúrò ní Òkun Pupa, wọ́n sì lọ sí aginjù Ṣúrì,+ wọ́n sì rìn fún ọjọ́ mẹ́ta nínú aginjù, ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.+ 23  Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé Márà,+ ṣùgbọ́n wọn kò lè mu omi Márà nítorí ó korò. Ìdí nìyẹn tí ó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Márà.+ 24  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè,+ pé: “Kí ni àwa yóò mu?” 25  Nígbà náà ni ó ké jáde sí Jèhófà.+ Nítorí náà, Jèhófà darí rẹ̀ sí igi kan, ó sì sọ ọ́ sínú omi náà, omi náà sì di dídùn.+ Ibẹ̀ ni Ó ti gbé ìlànà kan àti ọ̀ràn kan kalẹ̀ fún wọn fún ìdájọ́, ibẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.+ 26  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Bí ìwọ yóò bá fetí sílẹ̀ délẹ̀délẹ̀ sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tí ìwọ yóò sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú rẹ̀, tí ìwọ yóò sì fi etí sí àwọn àṣẹ rẹ̀ ní tòótọ́, tí o sì pa gbogbo ìlànà rẹ̀ mọ́,+ èmi kì yóò fi èyíkéyìí nínú àwọn àrùn tí mo fi sára àwọn ará Íjíbítì sára rẹ;+ nítorí pé èmi ni Jèhófà tí ń mú ọ lára dá.”+ 27  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dé Élímù, níbi tí ìsun omi méjìlá àti àádọ́rin igi ọ̀pẹ wà.+ Nítorí náà, wọ́n dó síbẹ̀ lẹ́bàá omi náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé