Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 14:1-31

14  Wàyí o, Jèhófà sọ fún Mósè, pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé kí wọ́n yí padà, kí wọ́n sì dó sí àtidé Píháhírótì láàárín Mígídólì àti òkun ní ìdojúkọ Baali-séfónì.+ Iwájú rẹ̀ ni ẹ óò dó sí lẹ́bàá òkun.  Nígbà náà ni Fáráò yóò sọ dájúdájú nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Wọ́n ń rìn gbéregbère nínú ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ náà. Aginjù ti ká wọn mọ́ pinpin.’+  Nítorí náà, èmi, ní tòótọ́, yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ òun yóò sì lépa wọn dájúdájú, èmi yóò sì gba ògo fún ara mi nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀;+ àwọn ará Íjíbítì yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.”+ Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.  Lẹ́yìn náà, a ròyìn rẹ̀ fún ọba Íjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti fẹsẹ̀ fẹ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkàn-àyà Fáráò àti ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà nípa àwọn ènìyàn náà,+ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi wí pé: “Kí ni ohun tí a ṣe yìí, ní ti pé a rán Ísírẹ́lì lọ kúrò nínú sísìnrú+ fún wa?”  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí múra àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú ẹgbẹ̀ta àṣàyàn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin yòókù ní Íjíbítì àti àwọn jagunjagun sórí ìkọ̀ọ̀kan wọn.  Jèhófà tipa báyìí jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò ọba Íjíbítì di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ ó sì ń bá a lọ ní lílépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ pẹ̀lú ọwọ́ ríròkè.+  Àwọn ará Íjíbítì sì ń bá a lọ ní lílépa wọn, gbogbo ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn agẹṣinjagun+ rẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ sì dé bá wọn bí wọ́n ti dó sí ẹ̀bá òkun, ní ẹ̀bá Píháhírótì ní ìdojúkọ Baali-séfónì.+ 10  Nígbà tí Fáráò sún mọ́ tòsí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ojú wọn sókè, sì kíyè sí i, àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fòyà gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà.+ 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Mósè pé: “Ṣé tìtorí pé kò sí àwọn ibi ìsìnkú rárá ní Íjíbítì ni o ṣe mú wa wá síhìn-ín láti kú nínú aginjù?+ Kí ni ohun tí o ṣe fún wa yìí ní mímú wa jáde kúrò ní Íjíbítì? 12  Èyí ha kọ́ ni ọ̀rọ̀ tí a sọ fún ọ ní Íjíbítì, pé, ‘Fi wá sílẹ̀ jẹ́ẹ́, kí a lè máa sin àwọn ará Íjíbítì’? Nítorí ó sàn fún wa láti sin àwọn ará Íjíbítì ju kí a kú ní aginjù.”+ 13  Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ má fòyà.+ Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà, èyí tí yóò ṣe fún yín lónìí.+ Nítorí àwọn ará Íjíbítì tí ẹ̀yin ń rí ní ti gidi lónìí, ẹ kì yóò tún rí wọn mọ́, rárá, láéláé.+ 14  Jèhófà yóò fúnra rẹ̀ jà fún yín,+ ẹ̀yin fúnra yín yóò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” 15  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Èé ṣe tí o fi ń ké jáde ṣáá sí mi?+ Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣí ibùdó. 16  Ní tìrẹ, gbé ọ̀pá+ rẹ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà,+ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lé la àárín òkun náà kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.+ 17  Ní tèmi, kíyè sí i, èmi yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà àwọn ará Íjíbítì di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kí wọ́n lè tẹ̀ lé wọ́n lẹ́yìn, kí èmi sì lè gba ògo fún ara mi nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣinjagun rẹ̀.+ 18  Àwọn ará Íjíbítì yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mó bá gba ògo fún ara mi nípasẹ̀ Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣinjagun rẹ̀.”+ 19  Nígbà náà ni áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tòótọ́ tí ń lọ níwájú ibùdó Ísírẹ́lì kúrò, ó sì lọ sí ìhà ẹ̀yìn wọn, ọwọ̀n àwọsánmà náà sì kúrò ní iwájú wọn, ó sì dúró ní ìhà ẹ̀yìn wọn.+ 20  Nítorí náà, ó wá wà láàárín ibùdó àwọn ará Íjíbítì àti ibùdó Ísírẹ́lì.+ Ní ọwọ́ kan, ó jẹ́ àwọsánmà pa pọ̀ pẹ̀lú òkùnkùn. Ní ọwọ́ kejì, ó ń jẹ́ kí òru náà mọ́lẹ̀ kedere.+ Àwùjọ tibí kò sì sún mọ́ àwùjọ tọ̀hún láti òru mọ́jú. 21  Wàyí o, Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle láti òru mọ́jú tí ó sì yí ìsàlẹ̀ òkun padà di ilẹ̀ gbígbẹ,+ a sì pín omi náà níyà.+ 22  Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ bí omi náà ti jẹ́ ògiri fún wọn ní ọwọ́ ọ̀tún wọn àti ní òsì wọn.+ 23  Àwọn ará Íjíbítì sì ń bá ìlépa nìṣó, gbogbo ẹṣin Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣinjagun rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé wọn lẹ́yìn,+ sínú àárín òkun. 24  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ìṣọ́ òwúrọ̀ pé Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bojú wo ibùdó àwọn ará Íjíbítì láti àárín ọwọ̀n iná àti àwọsánmà náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ibùdó àwọn ará Íjíbítì sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 25  Ó sì ń bá a lọ láti máa yọ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ kúrò lára kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, tí ó fi jẹ́ pé ìṣòro ni wọ́n fi ń wà wọ́n;+ àwọn ará Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a sá fún níní ìfarakanra èyíkéyìí pẹ̀lú Ísírẹ́lì, nítorí pé Jèhófà ń jà fún wọn dájúdájú ní ìlòdìsí àwọn ará Íjíbítì.”+ 26  Níkẹyìn, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun,+ kí omi náà lè padà wá sórí àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn àti àwọn agẹṣinjagun wọn.” 27  Lójú-ẹsẹ̀, Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun, òkun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí padà wá sí ipò rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ rí nígbà tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di òwúrọ̀. Ní gbogbo àkókò náà, àwọn ará Íjíbítì ń sá láti má ṣe pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà gbọn àwọn ará Íjíbítì dànù sí àárín òkun náà.+ 28  Omi náà sì ń padà wá ṣáá.+ Níkẹyìn, wọ́n bo àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti àwọn agẹṣinjagun tí ó jẹ́ ti gbogbo ẹgbẹ́ ológun Fáráò àti àwọn tí wọ́n tọ̀ wọ́n lẹ́yìn wọnú òkun.+ Kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan ṣoṣo nínú wọn tí ó ṣẹ́ kù.+ 29  Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín ìsàlẹ̀ òkun,+ omi náà sì jẹ́ ògiri fún wọn ní ọwọ́ ọ̀tún wọn àti ní òsì wọn.+ 30  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tipa báyìí gba Ísírẹ́lì là kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ Ísírẹ́lì sì rí àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n kú sí etíkun.+ 31  Ísírẹ́lì tún rí ọwọ́ ńlá tí Jèhófà lò ní ìlòdìsí àwọn ará Íjíbítì; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé