Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 13:1-22

13  Jèhófà sì sọ fún Mósè síwájú sí i, pé:  “Sọ gbogbo àkọ́bí tí ó jẹ́ akọ tí ó ṣí olúkúlùkù ilé ọlẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láàárín ènìyàn àti ẹranko, di mímọ́ fún mi. Tèmi ni.”+  Mósè sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Kí ẹ máa rántí ọjọ́ yìí tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú, nítorí pé nípa okun ọwọ́ ni Jèhófà fi mú yín jáde kúrò níhìn-ín.+ Nítorí náà, ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà ni a kò gbọ́dọ̀ jẹ.+  Ẹ ń jáde lọ lónìí ní oṣù Ábíbù.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jèhófà bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì àti àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ èyí tí ó búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fi fún ọ,+ ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ nígbà náà, ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ní oṣù yìí.  Ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ àkàrà aláìwú,+ ọjọ́ keje sì ni àjọyọ̀ yóò wà fún Jèhófà.+  Àkàrà aláìwú ni kí o jẹ fún ọjọ́ méje;+ kí a má sì ṣe rí ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ,+ kí a má sì ṣe rí ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan èyíkéyìí pẹ̀lú rẹ láàárín gbogbo ààlà rẹ.+  Kí o sì sọ fún ọmọ rẹ ní ọjọ́ yẹn, pé, ‘Ó jẹ́ nítorí ohun tí Jèhófà ṣe fún mi nígbà tí mo jáde kúrò ní Íjíbítì.’+  Yóò sì jẹ́ àmì fún ọ lára ọwọ́ rẹ àti ìrántí láàárín ojú rẹ,+ kí òfin Jèhófà bàa lè wà ní ẹnu rẹ;+ nítorí pé nípa ọwọ́ líle ni Jèhófà fi mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì.+ 10  Kí o sì pa ìlànà àgbékalẹ̀ yìí mọ́ láti ọdún dé ọdún ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀.+ 11  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jèhófà bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti búra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ,+ nígbà tí ó bá fi í fún ọ, 12  nígbà náà, kí o ya olúkúlùkù ẹni tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà,+ àti gbogbo àkọ́bí, ọmọ ẹranko,+ èyí tí yóò wá jẹ́ tìrẹ. Àwọn akọ jẹ́ ti Jèhófà.+ 13  Gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ìwọ yóò sì fi àgùntàn tún rà padà, bí ìwọ kò bá sì ní tún un rà padà, nígbà náà, kí o ṣẹ́ ọrùn rẹ̀.+ Gbogbo àkọ́bí ènìyàn láàárín àwọn ọmọkùnrin rẹ ni kí o sì tún rà padà.+ 14  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ọmọ rẹ bá wádìí lọ́wọ́ rẹ nígbà tí ó bá yá,+ pé, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ nígbà náà, kí ìwọ sọ́ fún un pé, ‘Nípa okun ọwọ́ ni Jèhófà fi mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú.+ 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé Fáráò ṣe orí kunkun ní ti rírán wa lọ,+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ láti orí àkọ́bí ènìyàn dórí àkọ́bí ẹranko.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi gbogbo akọ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀+ rúbọ sí Jèhófà, àti gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin mi ni mo sì ń tún rà padà.’+ 16  Yóò sì jẹ́ àmì lára ọwọ́ rẹ àti ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú rẹ,+ nítorí pé nípa okun ọwọ́ ni Jèhófà fi mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì.”+ 17  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní àkókò tí Fáráò ń rán àwọn ènìyàn náà lọ, Ọlọ́run kò mú wọn gba ti ilẹ̀ àwọn Filísínì kìkì nítorí pé ó wà nítòsí, nítorí Ọlọ́run wí pé: “Ó lè jẹ́ pé àwọn ènìyàn náà yóò pèrò dà nígbà tí wọ́n bá rí ogun, tí wọn yóò sì padà dájúdájú sí Íjíbítì.”+ 18  Nítorí èyí, Ọlọ́run mú kí àwọn ènìyàn náà lọ yí ká gba ti aginjù Òkun Pupa.+ Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtẹ́gun ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè lọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 19  Mósè sì kó àwọn egungun Jósẹ́fù dání pẹ̀lú rẹ̀, nítorí ó ti mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀, pé: “Láìkùnà, Ọlọ́run yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí yín,+ kí ẹ sì kó àwọn egungun mi dání gòkè kúrò níhìn-ín pẹ̀lú yín.”+ 20  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde kúrò ní Súkótù, wọ́n sì dó sí Étámù ní etí aginjù.+ 21  Jèhófà sì ń lọ níwájú wọn ní ìgbà ọ̀sán nínú ọwọ̀n àwọsánmà láti ṣamọ̀nà wọn lójú ọ̀nà náà,+ àti ní òru nínú ọwọ̀n iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ láti máa lọ ní ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru.+ 22  Ọwọ̀n àwọsánmà náà kì í ṣí kúrò níwájú àwọn ènìyàn náà ní ìgbà ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọwọ̀n iná náà ní ìgbà òru.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé