Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 12:1-51

12  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè àti Áárónì ní ilẹ̀ Íjíbítì pé:  “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù fún yín. Òun ni yóò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn oṣù ọdún fún yín.+  Sọ fún gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì pátá, pé, ‘Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí kí wọ́n mú àgùntàn kan+ fún ara wọn, olúkúlùkù fún ilé baba ńlá ìgbàanì, àgùntàn kan fún ilé kan.  Ṣùgbọ́n bí agbo ilé náà bá kéré jù fún àgùntàn kan, nígbà náà, kí òun àti aládùúgbò rẹ̀ tí ó wà nítòsí mú un sínú ilé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú iye àwọn ọkàn náà; kí ẹ fi ìṣírò pinnu ti olúkúlùkù ní ìwọ̀n bí ó ṣe lè jẹ tó ní ti àgùntàn náà.  Kí àgùntàn náà jẹ́ alára dídá ṣáṣá,+ akọ, ọlọ́dún kan, fún yín.+ Ẹ lè mú nínú àwọn ẹgbọrọ àgbò tàbí nínú àwọn ewúrẹ́.  Kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ nìṣó títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí,+ kí gbogbo ìjọ àpéjọ Ísírẹ́lì sì pa á láàárín alẹ́ méjèèjì náà.+  Kí wọ́n sì mú lára ẹ̀jẹ̀ náà, kí wọ́n sì fi wọ́n ara òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn àwọn ilé tí wọn yóò ti jẹ ẹ́.+  “‘Kí wọ́n sì jẹ ẹran náà ní òru yìí.+ Kí wọ́n fi iná sun ún jẹ pẹ̀lú àkàrà aláìwú+ pa pọ̀ pẹ̀lú ewébẹ̀ kíkorò.+  Má ṣe jẹ èyíkéyìí nínú rẹ̀ ní tútù tàbí ní bíbọ̀, ní fífi omi sè é, bí kò ṣe ní sísun ún nínú iná, orí rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tete rẹ̀ àti àwọn apá ara rẹ̀ ti inú. 10  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣẹ́ èyíkéyìí nínú rẹ̀ kù sílẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ó bá ṣẹ́ kù nínú rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ni kí ẹ fi iná jó.+ 11  Báyìí sì ni ẹ ó ṣe jẹ ẹ́, ti ẹ̀yin ti ìgbáròkó yín tí a dì lámùrè,+ sálúbàtà+ ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ní ọwọ́ yín; kí ẹ sì jẹ ẹ́ kánkán. Ìrékọjá Jèhófà ni.+ 12  Èmi yóò sì la ilẹ̀ Íjíbítì kọjá ní òru yìí,+ èmi yóò sì kọlu gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì, láti orí ènìyàn dórí ẹranko;+ èmi yóò sì mú àwọn ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún+ sórí gbogbo ọlọ́run Íjíbítì. Èmi ni Jèhófà.+ 13  Ẹ̀jẹ̀ náà yóò sì jẹ́ àmì yín lára àwọn ilé tí ẹ wà; èmi yóò sì rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò sì ré yín kọjá,+ ìyọnu àjàkálẹ̀ náà kì yóò sì wá sórí yín bí ìparun nígbà tí mo bá kọlu ilẹ̀ Íjíbítì. 14  “‘Ọjọ́ yìí yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín, ẹ ó sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ fún Jèhófà jálẹ̀ ìran-ìran yín. Kí ẹ sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin. 15  Ọjọ́ méje ni ẹ ó fi jẹ àkàrà aláìwú. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ọjọ́ kìíní, ẹ óò mú ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan kúrò ní ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ní ìwúkàrà, láti ọjọ́ kìíní títí dé ìkeje,+ ọkàn yẹn ni a óò ké kúrò ní Ísírẹ́lì.+ 16  Ní ọjọ́ kìíní, àpéjọpọ̀ mímọ́ yóò sì wà fún yín, àti ní ọjọ́ keje, àpéjọpọ̀ mímọ́.+ A kì yóò ṣe iṣẹ́ kankan nínú wọn.+ Kìkì ohun tí olúkúlùkù ọkàn nílò láti jẹ, ìyẹn nìkan ni a lè ṣe fún yín.+ 17  “‘Kí ẹ sì pa àjọyọ̀ àkàrà aláìwú+ mọ́, nítorí ọjọ́ yìí gan-an ni èmi yóò mú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ sì máa pa ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ ìran-ìran yín gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin. 18  Ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, ní alẹ́, ẹ ó jẹ àkàrà aláìwú títí di ọjọ́ kọkànlélógún oṣù náà ní alẹ́.+ 19  Ọjọ́ méje ni a kò fi ní rí ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan èyíkéyìí ní ilé yín, nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ́ ohun tí ó ní ìwúkàrà wò, yálà ó jẹ́ àtìpó tàbí ọmọ ìbílẹ̀,+ ọkàn yẹn ni a óò ké kúrò nínú àpéjọ Ísírẹ́lì.+ 20  Ẹ má jẹ ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà. Ní gbogbo ibùgbé yín, àkàrà aláìwú ni kí ẹ jẹ.’” 21  Ní kánmọ́, Mósè pe gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì,+ ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ fa àgùntàn àti ewúrẹ́ jáde, kí ẹ sì mú wọn fún ara yín ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ìrékọjá.+ 22  Kí ẹ sì mú ìdìpọ̀ hísópù,+ kí ẹ sì tẹ̀ ẹ́ bọ ẹ̀jẹ̀ inú bàsíà, kí ẹ sì fi lára ẹ̀jẹ̀ inú bàsíà náà wọ́n apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn àti ara àwọn òpó méjèèjì ilẹ̀kùn náà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má sì ṣe jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ títí di òwúrọ̀. 23  Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jèhófà bá kọjá láti kọlu àwọn ará Íjíbítì tí ó sì rí ẹ̀jẹ̀ náà ní apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn àti lára àwọn òpó méjèèjì ilẹ̀kùn, dájúdájú, Jèhófà yóò ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kì yóò sì jẹ́ kí ìparun náà wọnú ilé yín láti kọlù yín.+ 24  “Kí ẹ sì pa nǹkan yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà+ fún ọ àti fún àwọn ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 25  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fi fún yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, nígbà náà, kí ẹ pa iṣẹ́ ìsìn+ yìí mọ́. 26  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn ọmọ yín bá wí fún yín pé, ‘Kí ni iṣẹ́ ìsìn yìí túmọ̀ sí fún yín?’+ 27  nígbà náà, kí ẹ wí pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá ni sí Jèhófà,+ ẹni tí ó ré ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tí ó mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ará Íjíbítì, ṣùgbọ́n ó dá ilé wa nídè.’” Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n sì wólẹ̀.+ 28  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, wọ́n sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè àti Áárónì.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní ọ̀gànjọ́ òru Jèhófà kọlu gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ láti orí àkọ́bí Fáráò tí ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ títí dórí àkọ́bí òǹdè tí ó wà nínú ihò ẹ̀wọ̀n, àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.+ 30  Nígbà náà ni Fáráò dìde ní òru, òun àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ará Íjíbítì yòókù; igbe ẹkún ńláǹlà sì bẹ́ láàárín àwọn ará Íjíbítì,+ nítorí pé kò sí ilé kan tí ẹnì kan kò ti kú. 31  Ní kíá, ó pe+ Mósè àti Áárónì ní òru, ó sì wí pé: “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ní àárín àwọn ènìyàn mi, àti ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, ẹ lọ, kí ẹ sì sin Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sọ.+ 32  Ẹ mú àwọn agbo ẹran yín àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sọ,+ kí ẹ sì lọ. Ní àfikún, kí ẹ súre fún mi pẹ̀lú.” 33  Àwọn ará Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ àwọn ènìyàn náà kí wọ́n bàa lè tètè+ rán wọn lọ kúrò ní ilẹ̀ náà, wọ́n wí pé, “nítorí gbogbo wa fẹ́rẹ̀ẹ́ má sàn ju òkú lọ!”+ 34  Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà gbé ìyẹ̀fun àpòrọ́ wọn kí ó tó di wíwú, pẹ̀lú ọpọ́n ìpo-nǹkan wọn tí wọ́n fi aṣọ àlàbora wé sórí èjìká wọn. 35  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Mósè ní ti pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn aṣọ àlàbora+ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. 36  Jèhófà sì fi ojú rere fún àwọn ènìyàn náà ní ojú àwọn ará Íjíbítì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn wọ̀nyí fi yọ̀ǹda ohun tí wọ́n béèrè;+ wọ́n sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.+ 37  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde kúrò ní Rámésésì+ lọ sí Súkótù,+ ní iye tí ó jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ abarapá ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ kéékèèké.+ 38  Àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata+ sì tún gòkè lọ pẹ̀lú wọn, títí kan àwọn agbo ẹran àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran, àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀ níye gan-an. 39  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìyẹ̀fun àpòrọ́ tí wọ́n ti mú jáde kúrò ní Íjíbítì yan àkàrà ribiti, àkàrà aláìwú, nítorí pé kò tíì di wíwú, nítorí pé a lé wọn jáde kúrò ní Íjíbítì, wọn kò sì lè dúró pẹ́ àti pé wọn kò tíì pèsè àwọn ìpèsè oúnjẹ èyíkéyìí sílẹ̀ fún ara wọn.+ 40  Gbígbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n gbé+ ní Íjíbítì,+ sì jẹ́ irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n.+ 41  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n náà, àní ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yìí gan-an pé, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 42  Ó jẹ́ òru kan láti pa mọ́ fún Jèhófà fún mímú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Fún Jèhófà, òru yìí jẹ́ èyí tí ó wà fún pípa mọ́ fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì jálẹ̀ ìran-ìran wọn.+ 43  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè àti Áárónì pé: “Èyí ni ìlànà àgbékalẹ̀ ti ìrékọjá:+ Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kankan kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+ 44  Ṣùgbọ́n níbi tí a bá ti ní ẹrúkùnrin èyíkéyìí tí a fi owó rà, kí o dádọ̀dọ́ rẹ̀.+ Nígbà náà ni ó tó lè ṣe àjọpín nínú jíjẹ ẹ́. 45  Olùtẹ̀dó àti lébìrà tí a háyà kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 46  Inú ilé kan ni kí a ti jẹ ẹ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé lọ sí ibi kan ní òde. Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fọ́ egungun kan nínú rẹ̀.+ 47  Gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì ni kí ó ṣe ayẹyẹ rẹ̀.+ 48  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ tí òun ní ti gidi yóò sì ṣe ayẹyẹ ìrékọjá fún Jèhófà, kí gbogbo ọkùnrin rẹ̀ dádọ̀dọ́.+ Lẹ́yìn náà ni ó tó lè sún mọ́ tòsí láti ṣe ayẹyẹ rẹ̀; òun yóò sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀. Ṣùgbọ́n aláìdádọ̀dọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 49  Òfin kan ni kí ó wà fún ọmọ ìbílẹ̀ àti fún àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín.”+ 50  Nítorí náà, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè àti Áárónì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.+ 51  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yìí gan-an pé Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn+ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé