Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 11:1-10

11  Jèhófà sì tẹ̀ síwájù láti wí fún Mósè pé: “Ìyọnu àjàkálẹ̀ kan sí i ni èmi yóò mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn ìyẹn, òun yóò rán yín lọ kúrò níhìn-ín.+ Ní àkókò tí òun yóò rán yín lọ pátápátá, òun yóò lé yín jáde ní ti gidi kúrò níhìn-ín.+  Wàyí o, sọ̀rọ̀, ní etí àwọn ènìyàn náà, pé kí wọ́n béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà,+ kí olúkúlùkù ọkùnrin béèrè lọ́wọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ àti olúkúlùkù obìnrin lọ́wọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fi ojú rere fún àwọn ènìyàn náà ní ojú àwọn ará Íjíbítì.+ Ọkùnrin náà, Mósè, pẹ̀lú jẹ́ ẹni ńlá gan-an ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní ojú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti ní ojú àwọn ènìyàn náà.+  Mósè sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní nǹkan bí ọ̀gànjọ́ òru, èmi yóò jáde lọ sí àárín Íjíbítì,+  olúkúlùkù àkọ́bí+ ní ilẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú, láti orí àkọ́bí Fáráò tí ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ títí dórí àkọ́bí ìránṣẹ́bìnrin tí ó wà nídìí ọlọ ọlọ́wọ́ àti olúkúlùkù àkọ́bí ẹranko.+  Dájúdájú, igbe ẹkún ńláǹlà yóò sì wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, àti irú èyí tí a kì yóò tún mú kí ó ṣẹlẹ̀ mọ́ láé.+  Ṣùgbọ́n ajá kankan kì yóò fi ìháragàgà yọ ahọ́n rẹ̀ sí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti orí ènìyàn títí dórí ẹranko;+ kí ẹ bàa lè mọ̀ pé Jèhófà lè fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’+  Gbogbo ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí yóò sì sọ̀ kalẹ̀ wá bá mi, wọn yóò sì wólẹ̀ fún mi,+ pé, ‘Lọ, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ.’ Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò sì jáde lọ.” Pẹ̀lú ìyẹn, ó jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò nínú ìgbóná ìbínú.  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Fáráò kì yóò fetí sí yín,+ nítorí kí iṣẹ́ ìyanu mi lè pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 10  Mósè àti Áárónì sì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Fáráò;+ ṣùgbọ́n Jèhófà jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé