Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 10:1-29

10  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, nítorí pé èmi—èmi ti jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ̀ àti ọkàn-àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gíràn-án,+ kí èmi bàa lè gbé àwọn iṣẹ́ àmì tèmi wọ̀nyí kalẹ̀ níwájú rẹ̀ gan-an,+  àti pé kí ìwọ bàa lè polongo ní etí ọmọ rẹ àti ọmọ-ọmọ rẹ bí mo ti bá Íjíbítì lò lọ́nà mímúná tó àti àwọn iṣẹ́ àmì mi tí mo gbé kalẹ̀ láàárín wọn;+ ẹ ó sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.”+  Nítorí náà, Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù wí, ‘Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀ fún mi?+ Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.  Nítorí bí ìwọ bá ń bá a lọ ní kíkọ̀ láti rán àwọn ènìyàn mi lọ, kíyè sí i, èmi yóò mú àwọn eéṣú wá sínú àwọn ààlà rẹ lọ́la.+  Dájúdájú, wọn yóò sì bo ojú ibi tí a lè rí lórí ilẹ̀, kò sì ní ṣeé ṣe láti rí ilẹ̀; wọn yóò sì wulẹ̀ jẹ ìyókù ohun tí ó yèbọ́, ohun tí yìnyín ṣẹ́ kù fún yín, dájúdájú, wọn yóò sì jẹ gbogbo igi yín tí ń rú jáde nínú pápá.+  Àwọn ilé rẹ àti ilé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ilé gbogbo Íjíbítì yóò kún dé ìwọ̀n tí baba rẹ àti baba baba rẹ kò tíì rí láti ọjọ́ tí wọ́n ti wà lórí ilẹ̀ títí di òní yìí.’”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó yí padà, ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò.+  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Fáráò wí fún un pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ọkùnrin yìí yóò fi máa jẹ́ bí ìdẹkùn fún wa?+ Rán àwọn ọkùnrin náà lọ kí wọ́n lè sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ṣé ìwọ kò tíì mọ̀ síbẹ̀ pé Íjíbítì ti ṣègbé ni?”+  Nítorí náà, a mú Mósè àti Áárónì padà wá sọ́dọ̀ Fáráò, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ sin Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Àwọn wo gan-an ni wọ́n ń lọ?”  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Àti àwọn ọ̀dọ́ wa àti àwọn arúgbó wa ni yóò lọ. Àti àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa,+ àti àwọn àgùntàn wa àti àwọn màlúù wa ni yóò lọ,+ nítorí a ní àjọyọ̀ fún Jèhófà.”+ 10  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀, kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín nígbà tí èmi yóò rán ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké lọ!+ Wò ó, dípò èyí, ohun tí ó jẹ́ ibi ni ìfojúsùn yín.+ 11  Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ abarapá ọkúnrin, ẹ lọ, kí ẹ sì sin Jèhófà, nítorí ohun tí ẹ ń wá nìyẹn.” Pẹ̀lú ìyẹn, a lé wọn jáde kúrò níwájú Fáráò.+ 12  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Na+ ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Íjíbítì fún àwọn eéṣú, kí wọ́n lè jáde wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì kí wọ́n sì jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà tán, ohun gbogbo tí yìnyín ṣẹ́ kù.”+ 13  Lójú-ẹsẹ̀, Mósè na ọ̀pá rẹ̀ jáde sórí ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà sì mú kí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn+ fẹ́ sórí ilẹ̀ náà ní gbogbo ọ̀sán yẹn àti gbogbo òru. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn sì gbé àwọn eéṣú dé. 14  Àwọn eéṣú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá sórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n sì balẹ̀ sórí gbogbo ìpínlẹ̀ Íjíbítì.+ Ìnira gbáà ni wọ́n jẹ́.+ Ṣáájú wọn, kò tíì sí eéṣú tí ó wá báyìí bí tiwọn rí, kò sì ní sí èyíkéyìí tí yóò wá báyìí lẹ́yìn wọn láé. 15  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bo ojú ibi tí a lè rí lórí gbogbo ilẹ̀ náà pátá,+ ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn;+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà tán àti gbogbo èso àwọn igi tí yìnyín ṣẹ́ kù;+ a kò sì ṣẹ́ ohun tútù yọ̀yọ̀ kankan kù lára igi tàbí lára ewéko pápá ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 16  Nítorí náà, wàrà-wéré ni Fáráò pe Mósè àti Áárónì, ó sì wí pé: “Mo ti ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín àti sí yín.+ 17  Nísinsìnyí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì+ ní ẹ̀ẹ̀kan yìí péré, kí ẹ sì pàrọwà+ sí Jèhófà Ọlọ́run yín kí ó lè mú kìkì ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani yìí lọ kúrò lórí mi.” 18  Nítorí náà, ó jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì pàrọwà sí Jèhófà.+ 19  Nígbà náà ni Jèhófà ṣe ìṣípòpadà sí ẹ̀fúùfù ìwọ̀-oòrùn líle gan-an, ó sì gbé àwọn eéṣú náà lọ, ó sì gbá wọn sínú Òkun Pupa. Kò sí ẹyọ eéṣú kan ṣoṣo tí ó ṣẹ́ kù ní gbogbo ìpínlẹ̀ Íjíbítì. 20  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kò sì rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. 21  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sí ọ̀run,+ kí òkùnkùn lè ṣú bo ilẹ̀ Íjíbítì, òkùnkùn tí a lè fọwọ́ bà.” 22  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí ọ̀run, òkùnkùn ṣíṣú dùdù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì fún ọjọ́ mẹ́ta.+ 23  Wọn kò rí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, kò sì sí ẹnì kan nínú wọn tí ó dìde kúrò ní àyè rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta; ṣùgbọ́n fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì, ìmọ́lẹ̀ wà ní ibùgbé wọn.+ 24  Lẹ́yìn ìyẹn, Fáráò pe Mósè, ó sì wí pé: “Ẹ lọ, ẹ sin Jèhófà.+ Kìkì àwọn àgùntàn àti àwọn màlúù yín ni a óò dá dúró. Àwọn ọmọ yín kéékèèké pẹ̀lú lè bá yín lọ.”+ 25  Ṣùgbọ́n Mósè wí pé: “Ìwọ fúnra rẹ pẹ̀lú yóò fi àwọn ẹbọ àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun lé wa lọ́wọ́, níwọ̀n bí a ó ti fi wọ́n rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ 26  Àwọn ohun ọ̀sìn wa yóò bá wa lọ pẹ̀lú.+ A kò ní gbà kí pátákò kan ṣẹ́ kù sílẹ̀, nítorí lára wọn ni a ó ti mú láti fi jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run wa,+ àwa fúnra wa kò sì mọ ohun tí a ó lò nínú ìjọsìn sí Jèhófà títí a ó fi dé ibẹ̀.”+ 27  Látàrí èyí, Jèhófà jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun, kò sì gbà láti rán wọn lọ.+ 28  Nítorí náà, Fáráò wí fún un pé: “Jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!+ Ṣọ́ ara rẹ! Má gbìyànjú láti rí ojú mi mọ́, nítorí ní ọjọ́ tí o bá rí ojú mi ìwọ yóò kú.”+ 29  Mósè fèsì pé: “Bí o ṣe sọ nìyẹn. Èmi kì yóò gbìyànjú láti rí ojú rẹ mọ́ rárá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé