Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 1:1-22

1  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n wá sí Íjíbítì pẹ̀lú Jékọ́bù; olúkúlùkù ọkùnrin àti agbo ilé rẹ̀ wá:+  Rúbẹ́nì,+ Síméónì,+ Léfì+ àti Júdà,+  Ísákárì,+ Sébúlúnì+ àti Bẹ́ńjámínì,+  Dánì+ àti Náfútálì,+ Gádì+ àti Áṣérì.+  Gbogbo ọkàn tí ó sì jáde wá láti òkè itan Jékọ́bù+ wá jẹ́ àádọ́rin ọkàn, ṣùgbọ́n Jósẹ́fù ti wà ní Íjíbítì ná.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jósẹ́fù kú,+ àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran yẹn pẹ̀lú.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì so èso, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá yìn-ìn; wọ́n sì ń di púpọ̀ sí i, wọ́n sì ń di alágbára ńlá sí i ní ìwọ̀n àrà ọ̀tọ̀ gan-an, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kún ilẹ̀ náà.+  Nígbà tí ó ṣe, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ lórí Íjíbítì.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ níye jù wá, wọ́n sì jẹ́ alágbára ńlá jù wá lọ.+ 10  Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a ta ọgbọ́n fún wọn,+ kí wọ́n má bàa di púpọ̀, kí ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé, bí ogun bá dé bá wa, dájúdájú, nígbà náà, wọn yóò dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra wa, wọn yóò sì bá wa jà, wọn yóò sì gòkè lọ kúrò ní ilẹ̀ yìí.” 11  Nítorí náà, wọ́n yan àwọn olórí tí ń fipá múni ṣòpò lé wọn lórí fún ète níni wọ́n lára nínú ẹrù ìnira tí wọ́n ń rù;+ wọ́n sì ń kọ́ àwọn ìlú ńlá láti fi ṣe àwọn ibi ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ fún Fáráò, èyíinì ni, Pítómù àti Rámísésì.+ 12  Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń ni wọ́n lára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń di púpọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn káàkiri, tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn mú wọn nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 13  Nítorí náà, àwọn ará Íjíbítì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.+ 14  Wọ́n sì ń mú ìgbésí ayé korò fún wọn nípa ìsìnrú nínira nídìí àpòrọ́ tí a fi amọ̀ ṣe+ àti bíríkì àti pẹ̀lú gbogbo oríṣi ìsìnrú nínú pápá,+ bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo oríṣi ìsìnrú wọn nínú èyí tí wọ́n lò wọ́n bí ẹrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.+ 15  Lẹ́yìn náà, ọba Íjíbítì sọ fún àwọn Hébérù agbẹ̀bí,+ tí orúkọ ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Ṣífúrà, tí orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Púà, 16  bẹ́ẹ̀ ni, ó lọ jìnnà débi sísọ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì rí wọn lórí àpótí ìbímọ, bí ó bá jẹ́ ọmọkùnrin ni, kí ẹ fi ikú pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ọmọbìnrin ni, kí ó wà láàyè.” 17  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,+ wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Íjíbítì ti sọ fún wọn,+ ṣùgbọ́n wọn a pa àwọn ọmọkùnrin mọ́ láàyè.+ 18  Nígbà tí ó ṣe, ọba Íjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ṣe ohun yìí, ní ti pé ẹ pa àwọn ọmọkùnrin mọ́ láàyè?”+ 19  Ẹ̀wẹ̀, àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Nítorí pé àwọn obìnrin Hébérù kò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Nítorí pé ara wọ́n le pọ́nkí-pọ́nkí, wọn a ti bímọ kí àwọn agbẹ̀bí tó wọlé dé ọ̀dọ̀ wọn.” 20  Nítorí náà, Ọlọ́run ṣe dáadáa sí àwọn agbẹ̀bí náà;+ àwọn ènìyàn náà sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i níye, wọ́n sì ń di alágbára ńlá gan-an. 21  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nítorí tí àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ó fún wọn ní àwọn ìdílé lẹ́yìn náà.+ 22  Níkẹyìn, Fáráò pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn rẹ̀, pé: “Olúkúlùkù ọmọkùnrin tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni kí ẹ sọ sínú Odò Náílì, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ọmọbìnrin ni kí ẹ pa mọ́ láàyè.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé