Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ámósì 9:1-15

9  Mo rí i tí Jèhófà dúró lórí pẹpẹ,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Lu orí ọwọ̀n, kí àwọn ibi àbáwọlé lè mì jìgìjìgì. Kí o sì ké orí wọn kúrò, gbogbo wọn.+ Apá tí ó kẹ́yìn nínú wọn ni èmi yóò sì fi idà pa. Kò sí ẹni tí ń sá lọ nínú wọn tí sísá rẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí, kò sì sí ẹni tí ń sá àsálà nínú wọn tí yóò sá lọ gbé.+  Bí wọ́n bá walẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n;+ bí wọ́n bá sì gòkè lọ sí ọ̀run, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀ kalẹ̀.+  Bí wọ́n bá sì fi ara wọn pa mọ́ sí téńté Kámẹ́lì, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti fẹ̀sọ̀ wá wọn kiri, èmi yóò sì mú wọn dájúdájú.+ Bí wọ́n bá sì fi ara wọn pa mọ́ níkọ̀kọ̀ kúrò níwájú mi ní ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ òkun,+ ìsàlẹ̀ níbẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò, yóò sì bù wọ́n ṣán.  Bí wọ́n bá sì lọ sí oko òǹdè níwájú àwọn ọ̀tá wọn, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà, yóò sì pa wọ́n;+ èmi yóò sì kọjú sí wọn fún búburú, kì í sì í ṣe fún rere.+  Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, sì ni Ẹni tí ó fọwọ́ kan ilẹ̀ náà, tí ó fi yọ́;+ gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀;+ dájúdájú, yóò gòkè wá gẹ́gẹ́ bí Náílì, gbogbo rẹ̀, yóò sì rì wọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Náílì Íjíbítì.+  “‘Ẹni tí ó ṣe àwọn àtẹ̀gùn rẹ̀ sí ọ̀run,+ àti ohun ìgbékalẹ̀ rẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé tí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀;+ ẹni tí ń pe omi òkun,+ kí ó lè dà á sórí ilẹ̀ ayé+—Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.’+  “‘Ẹ kò ha dà bí àwọn ọmọ Kúṣì sí mi, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi kò ha mú Ísírẹ́lì alára gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ àti àwọn Filísínì+ láti Kírétè, àti Síríà láti Kírì?’+  “‘Wò ó! Ojú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára ìjọba tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,+ dájúdájú, òun yóò sì pa á rẹ́ kúrò lójú ilẹ̀.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi kì yóò pa ilé Jékọ́bù rẹ́ ráúráú,’+ ni àsọjáde Jèhófà.  ‘Nítorí, wò ó! èmi yóò pàṣẹ, dájúdájú, èmi yóò gbọn ilé Ísírẹ́lì pẹ̀pẹ̀ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti ń gbọn ajọ̀ pẹ̀pẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé òkúta róbótó kan kì yóò bọ́ sílẹ̀. 10  Wọn yóò tipa idà kú—gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ènìyàn mi,+ àwọn tí ń sọ pé: “Ìyọnu àjálù kì yóò sún mọ́ wa tàbí kí ó dé ọ̀dọ̀ wa.”’+ 11  “‘Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò gbé àtíbàbà+ Dáfídì tí ó ti wó+ dìde,+ èmi yóò sì tún àwọn àlàfo wọn ṣe dájúdájú. Àwókù rẹ̀ ni èmi yóò sì gbé dìde, dájúdájú, èmi yóò gbé e ró bí ti àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ 12  kí wọ́n lè gba ohun tí ó ṣẹ́ kù nínú Édómù,+ àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a fi orúkọ mi pè,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ẹni tí ń ṣe èyí. 13  “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘atulẹ̀ yóò sì lé olùkórè bá+ ní ti tòótọ́, ẹni tí ń fẹsẹ̀ tẹ èso àjàrà yóò sì lé ẹni tí ń ru irúgbìn bá;+ àwọn òkè ńlá yóò sì kán tótó fún wáìnì dídùn,+ gbogbo àwọn òkè kéékèèké gan-an yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ́.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò sì kó òǹdè àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jọ padà,+ ní ti tòótọ́, wọn yóò sì kọ́ àwọn ìlú ńlá tí ó ti di ahoro, wọn yóò sì máa gbé inú wọn,+ wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu wáìnì wọn, wọn yóò sì ṣe ọgbà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.’+ 15  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì gbìn wọ́n sórí ilẹ̀ wọn, a kì yóò sì tún fà wọ́n tu mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ wọn tí mo ti fún wọn,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ wí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé