Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ámósì 8:1-14

8  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ mú kí n rí, sì wò ó! apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn+ kan wà.  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ámósì, kí ni ìwọ rí?”+ Nítorí náà, mo wí pé: “Apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.”+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Òpin ti dé bá àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.+ Èmi kì yóò tún fàyè gbà wọ́n mọ́.+  ‘Àwọn orin tẹ́ńpìlì yóò sì di híhu ní ọjọ́ yẹn+ ní ti tòótọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. ‘Òkú púpọ̀ yóò wà.+ Ní ibi gbogbo, ènìyàn yóò sọ wọ́n síta dájúdájú—ṣe wọ̀ọ̀!’  “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń kù gìrì mọ́ àwọn òtòṣì,+ àní láti mú kí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé kásẹ̀ nílẹ̀,+  ẹ̀yin tí ń wí pé, ‘Yóò ti pẹ́ tó kí òṣùpá tuntun tó kọjá,+ kí a lè ta àwọn hóró ọkà?+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, sábáàtì,+ kí a lè mú ọkà wá fún títà; kí a lè sọ òṣùwọ̀n eéfà di kékeré,+ kí a sì mú kí ṣékélì di ńlá, kí a sì ṣèké nípa àwọn òṣùwọ̀n ẹ̀tàn;+  kí a sì lè fi fàdákà lásán-làsàn ra àwọn ẹni rírẹlẹ̀, kí a sì fi iye owó sálúbàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra àwọn òtòṣì, kí a sì lè ta pàǹtírí ọkà lásán-làsàn?’+  “Jèhófà ti fi Ìlọ́lájù Jékọ́bù búra,+ ‘Èmi kì yóò gbàgbé gbogbo iṣẹ́ wọn+ láé.  Kì í ha ṣe tìtorí èyí ni a ó fi kó ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ náà,+ tí gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀+ dájúdájú; tí yóò sì gòkè wá dájúdájú, gbogbo rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Náílì, tí a ó sì bì í síwá bì í sẹ́yìn, tí yóò sì rì wọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Náílì Íjíbítì?’+  “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘pé èmi yóò mú kí oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán ganrínganrín,+ dájúdájú, èmi yóò sì mú kí òkùnkùn bo ilẹ̀ náà ní ọjọ́ mímọ́lẹ̀ yòò. 10  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ àwọn àjọyọ̀ yín di ọ̀fọ̀+ àti gbogbo orin yín di orin arò, èmi yóò sì mú aṣọ àpò ìdọ̀họ wá sára gbogbo ìgbáròkó àti ìpárí bá gbogbo orí;+ èmi yóò sì mú kí ipò náà dà bí ti ṣíṣọ̀fọ̀ nítorí ọmọkùnrin kan ṣoṣo,+ àti àbájáde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kíkorò.’ 11  “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 12  Dájúdájú, wọn yóò sì ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ láti òkun títí lọ dé òkun, láti àríwá àní títí dé yíyọ oòrùn. Wọn yóò máa lọ káàkiri bí wọ́n ti ń wá ọ̀rọ̀ Jèhófà kiri, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.+ 13  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn arẹwà wúńdíá yóò dákú lọ gbári, àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin pẹ̀lú, nítorí òùngbẹ náà;+ 14  àwọn tí ń fi ẹ̀bi Samáríà búra,+ tí wọ́n sì ń sọ ní ti tòótọ́ pé: “Bí ọlọ́run rẹ ti ń bẹ láàyè, ìwọ Dánì!”+ àti pé, “Bí ọ̀nà Bíá-ṣébà+ ti ń bẹ láàyè!” Dájúdájú, wọn yóò sì ṣubú, wọn kì yóò sì tún dìde mọ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé