Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ámósì 7:1-17

7  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ mú kí n rí, sì wò ó! ó ń ṣẹ̀dá eéṣú agbáyìn-ìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tí irúgbìn àgbìnkẹ́yìn yọ. Sì wò ó! ó jẹ́ irúgbìn àgbìnkẹ́yìn+ lẹ́yìn koríko ọba tí a gé.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó parí jíjẹ ewéko ilẹ̀ náà tán, mo tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, dárí jì.+ Ta ni yóò dìde nínú Jékọ́bù? Nítorí ó kéré!”+  Jèhófà pèrò dà lórí èyí.+ “Kì yóò ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà wí.  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ mú kí n rí, sì wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń pe ipè fún fífi iná jà;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lá alagbalúgbú ibú omi gbẹ, ó sì jẹ abá ilẹ̀ tán.  Mo sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró.+ Ta ni yóò dìde nínú Jékọ́bù? Nítorí ó kéré!”+  Jèhófà pèrò dà+ lórí èyí. “Ìyẹn, pẹ̀lú, kì yóò ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.  Èyí ni ohun tí ó mú kí n rí, sì wò ó! Jèhófà dúró lórí ògiri tí a fi okùn ìwọ̀n ṣe,+ okùn ìwọ̀n sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún mi pé: “Ámósì, kí ni ìwọ rí?” Nítorí náà, mo wí pé: “Okùn ìwọ̀n.” Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kíyèsí i, èmi yóò ta okùn ìwọ̀n sáàárín àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.+ Èmi kì yóò tún fàyè gbà á síwájú sí i mọ́.+  Àwọn ibi gíga Ísákì+ ni a ó sì sọ di ahoro dájúdájú, àwọn ibùjọsìn+ Ísírẹ́lì ni a ó sì pa run di ahoro;+ èmi yóò si fi idà dìde sí ilé Jèróbóámù.”+ 10  Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì+ sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ sí Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì, pé: “Ámósì ti di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí ọ nínú ilé Ísírẹ́lì+ gan-an. Ilẹ̀ náà kò lè rí ara gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 11  Nítorí èyí ni ohun tí Ámósì wí, ‘Jèróbóámù yóò tipa idà kú; àti ní ti Ísírẹ́lì, láìsí àní-àní, yóò lọ sí ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.’”+ 12  Amasááyà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Ámósì pé: “Ìwọ olùríran,+ máa lọ, sá lọ sí ilẹ̀ Júdà, ibẹ̀ ni kí o sì ti máa jẹ oúnjẹ, ibẹ̀ sì ni o ti lè sọ tẹ́lẹ̀. 13  Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ mọ́ ní Bẹ́tẹ́lì,+ nítorí ibùjọsìn ọba ni,+ ilé ìjọba sì ni.” 14  Nígbà náà ni Ámósì dáhùn, ó sì wí fún Amasááyà pé: “Èmi kì í ṣe wòlíì tẹ́lẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì;+ ṣùgbọ́n olùṣọ́ agbo ẹran+ ni mí àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè. 15  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti mú mi kúrò lẹ́nu títọ agbo ẹran lẹ́yìn, Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé, ‘Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 16  Wàyí o, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ‘Ìwọ ha ń sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Ísírẹ́lì,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́+ lòdì sí ilé Ísákì”? 17  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ní ti aya rẹ, yóò di kárùwà+ ní ìlú ńlá yìí. Àti ní ti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ, wọn yóò tipa idà ṣubú. Àti ní ti ilẹ̀ rẹ, ìjàrá tí a fi ń wọn nǹkan ni a ó fi pín in. Àti ní ti ìwọ alára, orí ilẹ̀ àìmọ́ ni ìwọ yóò kú sí;+ àti ní ti Ísírẹ́lì, láìsí àní-àní, yóò lọ sí ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé