Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ámósì 6:1-14

6  “Ègbé ni fún àwọn tí ó wà ní ìdẹ̀rùn+ ní Síónì àti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé òkè ńlá Samáríà! Àwọn ni ẹni sàràkí-sàràkí lára apá pàtàkì nínú àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn sì ni ilé Ísírẹ́lì ti tọ̀ wá.  Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sí Kálínè, kí ẹ sì wò; kí ẹ sì ti ibẹ̀ lọ sí Hámátì+ elénìyàn púpọ̀, kí ẹ sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Gátì+ ti àwọn Filísínì. Wọ́n ha sàn ju ìjọba wọ̀nyí, tàbí ìpínlẹ̀ wọn ha tóbi ju ìpínlẹ̀ yín?+  Ẹ ha ń mú ọjọ́ tí ó kún fún ìyọnu àjálù kúrò lọ́kàn yín,+ ẹ ha sì ń mú ibùgbé ìwà ipá sún mọ́ tòsí?+  Ẹ̀yin tí ń dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú tí a fi eyín erin ṣe,+ tí ẹ sì ń nà gbalaja sórí àga ìnàyìn wọn, tí ẹ sì ń jẹ àwọn àgbò láti inú agbo ẹran àti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù láti inú àwọn àbọ́sanra ọmọ màlúù;+  tí ń hùmọ̀ orin ní ìbámu pẹ̀lú ìró ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín;+ tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì, wọ́n ti hùmọ̀ ohun èlò orin fún ara wọn;+  tí wọ́n ń mu láti inú àwokòtò wáìnì,+ tí wọ́n sì ń fi òróró tí í ṣe ààyò jù lọ+ ṣe ìfòróróyanni, tí a kò sì mú ṣàìsàn nítorí àjálù ibi Jósẹ́fù.+  “Nítorí náà, wọ́n yóò lọ sí ìgbèkùn wàyí níwájú àwọn tí ń lọ sí ìgbèkùn,+ àríyá aláriwo àwọn tí ń nà gbalaja yóò sì lọ.  “‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ọkàn ara rẹ̀ búra,’+ ni àsọjáde Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘“mo ṣe họ́ọ̀ sí ìyangàn Jékọ́bù,+ mo sì kórìíra àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀,+ èmi yóò sì fa ìlú ńlá náà àti ohun tí ó kún inú rẹ̀ léni lọ́wọ́.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó bá ṣẹ́ ku ọkùnrin mẹ́wàá sílẹ̀ nínú ilé kan, wọn yóò kú pẹ̀lú.+ 10  Arákùnrin baba rẹ̀ yóò sì gbé wọn lọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, yóò sì máa fi iná sun wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, láti bàa lè kó egungun náà jáde kúrò nínú ilé.+ Yóò sì sọ fún ẹnì yòówù tí ó bá wà ní àwọn ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ilé náà pé, ‘Ṣé wọ́n ṣì kù lọ́dọ̀ rẹ?’ Dájúdájú, òun yóò sì sọ pé, ‘Kò sí ẹnikẹ́ni!’ Òun yóò sì sọ pé, ‘Dákẹ́ jẹ́ẹ́! Nítorí kì í ṣe àkókò fún mímẹ́nukan orúkọ Jèhófà rárá.’”+ 11  “‘Nítorí, kíyè sí i, Jèhófà ń pàṣẹ,+ dájúdájú, òun yóò ṣá ilé ńlá balẹ̀ di àlàpà àti ilé kékeré di àwópalẹ̀ túútúú.+ 12  “‘Àwọn ẹṣin yóò ha máa sáré lórí àpáta gàǹgà, tàbí ẹnì kan yóò ha fi màlúù túlẹ̀ níbẹ̀? Nítorí ẹ ti sọ ìdájọ́ òdodo di ọ̀gbìn onímájèlé,+ ẹ sì ti sọ èso òdodo di iwọ, 13  ẹ̀yin tí ẹ ń yọ̀ nínú nǹkan tí kò sí;+ tí ń sọ pé: “A kò ha ti fi okun wa gba àwọn ìwo fún ara wa bí?”+ 14  Wò ó! Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè+ kan dìde sí yín, ilé Ísírẹ́lì,’ ni àsọjáde Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘wọn yóò sì ni yín lára láti àtiwọ Hámátì+ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Árábà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé