Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ámósì 5:1-27

5  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí èmi yóò sọ fún yín bí orin arò,+ ilé Ísírẹ́lì, pé:   “Wúńdíá náà,+ Ísírẹ́lì, ti ṣubú;+ Kò lè dìde mọ́.+ A ti pa á tì sórí ilẹ̀ rẹ̀; Kò sí ẹnì kankan tí yóò gbé e dìde.+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ìlú ńlá náà gan-an tí ń jáde lọ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún yóò ṣẹ́ ku ọgọ́rùn-ún; èyí tí ó sì ń jáde lọ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún yóò ṣẹ́ ku mẹ́wàá, fún ilé Ísírẹ́lì.’+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Wá mi,+ kí o sì máa wà láàyè nìṣó.+  Ẹ má sì wá Bẹ́tẹ́lì lọ,+ kí ẹ má sì wá sí Gílígálì,+ kí ẹ má sì ré kọjá lọ sí Bíá-ṣébà;+ nítorí pé Gílígálì pàápàá yóò lọ sí ìgbèkùn láìsí àní-àní;+ àti ní ti Bẹ́tẹ́lì, yóò di ohun abàmì.+  Wá Jèhófà, kí o sì máa wà láàyè nìṣó,+ kí ó má bàa bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí iná,+ ìwọ ilé Jósẹ́fù,+ kí ó má bàa jẹ run ní ti tòótọ́, kí Bẹ́tẹ́lì má bàa wà láìsí ẹnì kankan tí yóò pa iná náà,+  ẹ̀yin tí ń sọ ìdájọ́ òdodo di iwọ+ lásán-làsàn, àti ẹ̀yin tí ẹ ti ju òdodo pàápàá sí ilẹ̀.+  Olùṣẹ̀dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà+ àti àgbájọ ìràwọ̀+ Késílì,+ àti Ẹni tí ń sọ ibú òjìji+ di òwúrọ̀, àti Ẹni tí ó ti mú ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+ Ẹni tí ń pe omi òkun, kí ó lè dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé+—Jèhófà ni orúkọ rẹ̀;+  ẹni tí ń mú kí ìfiṣèjẹ kọ mànà lórí ẹni tí ó lágbára, kí ìfiṣèjẹ bàa lè dé bá ibi olódi pàápàá. 10  “‘Wọ́n kórìíra olùfi ìbáwí tọ́ni sọ́nà+ ní ẹnubodè, wọ́n sì ṣe họ́ọ̀ sí olùsọ àwọn ohun pípé.+ 11  Nítorí èyí, fún ìdí náà pé ẹ ń fi ipá gba ohun sísan fún híháyà oko lọ́wọ́ ẹni rírẹlẹ̀, owó òde ọkà ni ẹ̀yin sì ń gbà lọ́wọ́ rẹ̀;+ ẹ ti kọ́ àwọn ilé òkúta gbígbẹ́,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò máa bá a nìṣó ní gbígbé inú wọn; àwọn ọgbà àjàrà fífani-lọ́kàn-mọ́ra ni ẹ ti gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò máa bá a nìṣó ní mímu wáìnì wọn.+ 12  Nítorí mo ti mọ bí àwọn ìdìtẹ̀ yín+ ti pọ̀ tó àti bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ ti pọ̀ yanturu tó, ẹ̀yin tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí olódodo,+ ẹ̀yin tí ń gba owó mẹ́numọ́,+ àti ẹ̀yin tí ó ti yí àwọn òtòṣì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan+ àní ní ẹnubodè.+ 13  Nítorí náà, ẹni náà tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yẹn, nítorí yóò jẹ́ àkókò tí ó kún fún ìyọnu àjálù.+ 14  “‘Ẹ máa wá ohun rere, kì í sì í ṣe ohun búburú,+ kí ẹ bàa lè máa wà láàyè nìṣó;+ nípa báyìí kí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì lè wà pẹ̀lú yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí.+ 15  Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere,+ kí ẹ sì fún ìdájọ́ òdodo láyè ní ẹnubodè.+ Ó lè jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò fi ojú rere hàn+ sí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára Jósẹ́fù.’+ 16  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Jèhófà, wí, ‘Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ojúde ìlú,+ àti ní gbogbo ojú pópó àwọn ènìyàn yóò máa sọ pé: “Áà! Áà!” Wọn yóò sì ní láti pe àgbẹ̀ sí ìṣọ̀fọ̀,+ àti àwọn tí ó ní ìrírí nínú ìdárò sí ìpohùnréré ẹkún.’+ 17  ‘Ìpohùnréré ẹkún yóò sì wà ní gbogbo ọgbà àjàrà;+ nítorí èmi yóò la àárín rẹ kọjá,’+ ni Jèhófà wí. 18  “‘Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọ́n ń fà sí ọjọ́ Jèhófà!+ Kí wá ni ọjọ́ Jèhófà yóò túmọ̀ sí fún yín?+ Yóò jẹ́ òkùnkùn, kì í sì í ṣe ìmọ́lẹ̀,+ 19  gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọkùnrin kan bá sá nítorí kìnnìún, tí béárì sì pàdé rẹ̀ ní ti tòótọ́; àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó lọ sínú ilé, tí ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ ti ògiri, tí ejò sì bù ú ṣán.+ 20  Ọjọ́ Jèhófà kì yóò ha jẹ́ òkùnkùn, tí kì í sì í ṣe ìmọ́lẹ̀; kì yóò ha sì ní ìṣúdùdù, tí kì í sì í ṣe ìtànyòò?+ 21  Mo kórìíra, mo kọ àwọn àjọyọ̀ yín,+ èmi kì yóò sì gbádùn òórùn àwọn àpéjọ ọ̀wọ̀ yín.+ 22  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi odindi àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ rúbọ sí mi, àní èmi kì yóò ní inú dídùn+ sí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn yín, èmi kì yóò si wo àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ ti ẹran àbọ́pa yín.+ 23  Mú yánpọnyánrin àwọn orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi; kí n má sì gbọ́ ìró orin atunilára àwọn ohun èlò ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín.+ 24  Sì jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde gan-an gẹ́gẹ́ bí omi,+ àti òdodo bí ọ̀gbàrá tí ń ṣàn nígbà gbogbo.+ 25  Ṣé àwọn ẹbọ àti àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn ní ẹ mú wá fún mi ní aginjù fún ogójì ọdún, ilé Ísírẹ́lì?+ 26  Dájúdáju, ẹ ó sì gbé Sákútì ọba yín+ àti Káíwánì, àwọn ère yín, ìràwọ̀ ọlọ́run yín, tí ẹ ṣe fún ara yín.+ 27  Dájúdájú, èmi yóò sì mú kí ẹ lọ sí ìgbèkùn ré kọja Damásíkù,’+ ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé