Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ámósì 4:1-13

4  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin abo màlúù Báṣánì,+ tí ó wà lórí òkè ńlá Samáríà,+ tí ó ń lu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì,+ tí ó ń ni àwọn òtòṣì lára, tí ó ń sọ fún ọ̀gá wọn pé, ‘Ẹ gbé e wá, kí a sì mu!’  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra+ pé, ‘“Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀ wá sórí yín, yóò sì fi àwọn ìkọ́ alápatà gbé+ yín sókè dájúdájú, yóò sì fi àwọn ìwọ̀ ẹja gbé apá tí ó kẹ́yìn lára yín.  Àwọn àlàfo ni ẹ̀yin yóò sì gbà jáde lọ,+ olúkúlùkù sí ọ̀kánkán tààrà; a ó sì sọ yín sí Hámọ́nì dájúdájú,” ni àsọjáde Jèhófà.’  “‘ Ẹ wá sí Bẹ́tẹ́lì, kí ẹ sì lọ́wọ́ nínú ìrélànàkọjá.+ Ẹ lọ́wọ́ nínú ìrélànàkọjá+ lemọ́lemọ́ ní Gílígálì, kí ẹ sì mú àwọn ẹbọ yín wá ní òwúrọ̀; àti ìdá mẹ́wàá yín,+ ní ọjọ́ kẹta.  Ẹ sì mú èéfín ẹbọ ìdúpẹ́ rú+ láti inú ohun tí ó ní ìwúkàrà, kí ẹ sì pòkìkí àwọn ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe;+ ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́, nítorí bí ẹ ṣe fẹ́ nìyẹn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.  “‘Èmi pẹ̀lú, ní tèmi, sì fún yín ní ìmọ́tónítóní eyín+ ní gbogbo àwọn ìlú ńlá yín àti àìní oúnjẹ ní gbogbo àyè yín;+ ṣùgbọ́n ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà.  “‘Ní tèmi, mo sì tún fawọ́ eji wọwọ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín nígbà tí ìkórè ṣì ku oṣù mẹ́ta;+ mo sì mú kí òjò rọ̀ sórí ìlú ńlá kan, ṣùgbọ́n èmi kò mú kí òjò rọ̀ sórí ìlú ńlá mìíràn. Abá ilẹ̀ kan wà tí òjò rọ̀ sórí rẹ̀, ṣùgbọ́n abá ilẹ̀ ti èmi kò mú kí òjò rọ̀ sórí rẹ̀ a gbẹ dànù.+  Ìlú ńlá méjì tàbí mẹ́ta sì ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sí ìlú ńlá kan kí wọ́n bàa lè mu omi,+ kò sì tẹ́ wọn lọ́rùn; ṣùgbọ́n ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà.  “‘Mo fi ìjógbẹ àti èbíbu+ kọlù yín. A sọ àwọn ọgbà àjàrà yín àti àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ yín di púpọ̀, ṣùgbọ́n àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ yín àti àwọn igi ólífì yín ni kòkòrò wùkúwùkú yóò jẹ run;+ síbẹ̀, ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 10  “‘Mo rán àjàkálẹ̀ àrùn bí irú ti Íjíbítì+ sáàárín yín. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín,+ pa pọ̀ pẹ̀lú mímú àwọn ẹṣin+ yín ní òǹdè. Mo sì ń mú kí àyán ibùdó yín gòkè ṣáá àní sínú àwọn ihò imú yín;+ ṣùgbọ́n ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 11  “‘Mo fa ìbìṣubú láàárín yín, bí Ọlọ́run ṣe bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú.+ Ẹ sì wá dà bí ìtì igi tí a fà yọ kúrò nínú iná tí ń jó;+ ṣùgbọ́n ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 12  “Nítorí náà, ohun tí èmi yóò ṣe sí ọ nìyẹn, ìwọ Ísírẹ́lì. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde òtítọ́ náà pé èmi yóò ṣe ohun yìí gan-an sí ọ, múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ,+ ìwọ Ísírẹ́lì. 13  Nítorí, wò ó! Aṣẹ̀dá àwọn òkè ńlá+ àti Ẹlẹ́dàá ẹ̀fúùfù,+ àti Ẹni tí ó ń sọ fún ará ayé ohun tí ìdàníyàn èrò orí rẹ̀ jẹ́,+ Ẹni tí ó ń ṣe ọ̀yẹ̀ ní òkùnkùn ṣíṣú,+ àti Ẹni tí ó ń rìn lórí àwọn ibi gíga+ ilẹ̀ ayé, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé