Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ámósì 3:1-15

3  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí Jèhófà ti sọ nípa yín,+ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ pé,  ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀+ nínú gbogbo ìdílé tí ń bẹ lórí ilẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ yín fún gbogbo ìṣìnà yín.+  “‘Àwọn méjì ha lè jọ rìn pọ̀ bí kò ṣe pé wọ́n ti pàdé nípasẹ̀ àdéhùn?+  Kìnnìún yóò ha ké ramúramù nínú igbó láìní ẹran ọdẹ lọ́wọ́?+ Ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ yóò ha fọhùn láti ibi ìfarapamọ́ rẹ̀ bí kò bá tíì mú nǹkan kan rárá?  Ẹyẹ ha lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ìdẹkùn fún un?+ Pańpẹ́ ha lè ré kúrò lorí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan rárá?  Bí a bá fun ìwo nínú ìlú ńlá, àwọn ènìyàn kò ha ń wárìrì+ pẹ̀lú bí? Bí ìyọnu àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú ńlá, kì í ha ṣe Jèhófà ni ó tí gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú bí?  Nítorí pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+  Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù!+ Ta ni kì yóò fòyà? Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kì yóò sọ tẹ́lẹ̀?’+  “‘Ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ lórí àwọn ilé gogoro ibùgbé ní Áṣídódì àti lórí àwọn ilé gogoro ibùgbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kí ẹ sì sọ pé: “Ẹ kóra jọpọ̀ lòdì sí òkè ńlá Samáríà,+ kí ẹ sì rí ọ̀pọ̀ rúgúdù tí ó wà ní àárín rẹ̀ àti jìbìtì lílù ní inú rẹ̀.+ 10  Wọn kò sì mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń to ìwà ipá+ àti ìfiṣèjẹ jọ pa mọ́ sínú ilé gogoro ibùgbé wọn.”’ 11  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Elénìní kan wà àní yí ilẹ̀ náà ká,+ yóò sì mú kí okun rẹ rọlẹ̀ lára rẹ dájúdájú, a ó sì piyẹ́ àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ+ ní ti tòótọ́.’ 12  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tí ń já tete méjì tàbí abala etí+ kan gbà kúrò ní ẹnu kìnnìún, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà, àwọn tí ń jókòó sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú ọlọ́lá ńlá+ ní Samáríà àti sórí àga ìnàyìn ará Damásíkù.’+ 13  “‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì jẹ́rìí+ ní ilé Jékọ́bù,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 14  ‘Nítorí pé, ní ọjọ́ ti èmi yóò béèrè ìjíhìn+ fún àwọn ìdìtẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ rẹ̀, ni èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì+ pẹ̀lú; àwọn ìwo pẹpẹ náà ni a ó sì ké kúrò dájúdájú, wọn yóò sì já bọ́ sílẹ̀.+ 15  Dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ilé ìgbà òtútù+ balẹ̀ ní àfikún sí ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.’+ “‘Àwọn ilé eyín erin yóò sì ṣègbé,+ ọ̀pọ̀ ilé yóò sì wá sí òpin wọn dájúdájú,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé