Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ámósì 2:1-16

2  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘“Ní tìtorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Móábù,+ àti ní tìtorí mẹ́rin, èmi kì yóò yí i padà, ní tìtorí jíjó tí ó jó àwọn egungun ọba Édómù láti fi ṣe ẹfun.+  Èmi yóò sì rán iná sí Móábù dájúdájú, yóò sì jẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé Kéríótì run;+ Móábù yóò sì kú pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì, pẹ̀lú ìró ìwo.+  Èmi yóò sì ké onídàájọ́ kúrò ní àárín rẹ̀ dájúdájú, gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ̀ ni èmi yóò sì pa pẹ̀lú rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní tìtorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Júdà,+ àti ní tìtorí mẹ́rin, èmi kì yóò yí i padà, ní tìtorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ òfin Jèhófà,+ àti nítorí pé wọn kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́; bí kò ṣe àwọn irọ́ wọn,+ èyí tí àwọn baba ńlá wọn ti tọ̀ lẹ́yìn, tí ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère ṣáá.+  Èmi yóò sì rán iná sí Júdà dájúdájú, yóò sì jẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé Jerúsálẹ́mù run.’+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní tìtorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Ísírẹ́lì,+ àti ní tìtorí mẹ́rin, èmi kì yóò yí i padà, ní tìtorí títà tí wọ́n ta olódodo fún fàdákà lásán-làsàn, àti òtòṣì fún iye owó sálúbàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.+  Wọ́n ń fi ìháragàgà ṣàfẹ́rí ekuru ilẹ̀ lórí àwọn ẹni rírẹlẹ̀;+ ọ̀nà àwọn ọlọ́kàn tútù ni wọ́n sì yí padà;+ ọkùnrin kan àti baba rẹ̀ sì ti lọ sọ́dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan náà,+ fún ète sísọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.+  Àwọn ẹ̀wù tí wọ́n fi ipá gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò ni wọ́n sì nà gbalaja lé+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo pẹpẹ;+ wáìnì àwọn tí a bu ìtanràn lé ni wọ́n sì ń mu nínú ilé àwọn ọlọ́run wọn.’+  “‘Ṣùgbọ́n ní tèmi, mo ti pa Ámórì rẹ́ ráúráú+ ní tìtorí wọn, ẹni tí gíga rẹ̀ dà bí gíga àwọn kédárì, ẹni tí ó sì ní okun inú bí àwọn igi ràgàjì;+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa èso rẹ̀ rẹ́ ráúráú lókè àti àwọn gbòǹgbò rẹ̀ nísàlẹ̀.+ 10  Èmi fúnra mi sì mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ mo sì ń bá a nìṣó láti mú yín rìn la aginjù já ní ogójì ọdún,+ kí ẹ bàa lè gba ilẹ̀ Ámórì.+ 11  Mo sì ń bá a nìṣó láti gbé lára àwọn ọmọkùnrin yín dìde gẹ́gẹ́ bí wòlíì+ àti lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín gẹ́gẹ́ bí Násírì.+ Kò ha yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ti tòótọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni àsọjáde Jèhófà. 12  “‘Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń bá a nìṣó láti fún àwọn Násírì ní wáìnì mu,+ ẹ̀yin sì gbé àṣẹ kalẹ̀ fún àwọn wòlíì, pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀.”+ 13  Kíyè sí i, èmi yóò mú ohun tí ó wà lábẹ́ yín fì síhìn-ín sọ́hùn-ún, gan-an gẹ́gẹ́ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ẹsẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé ṣe ń fì síhìn-ín sọ́hùn-ún. 14  Ibi ìsásí yóò sì ṣègbé kúrò lọ́dọ̀ ẹni yíyára,+ kò sì sí alágbára tí yóò mú agbára rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, kò sì sí alágbára ńlá tí yóò pèsè àsálà fún ọkàn ara rẹ̀.+ 15  Kò sì sí ẹni tí ń mú ọrun lò tí yóò dúró, kò sì sí ẹni yíyára lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti yóò sá àsálà, kò sì sí ẹni tí ń gun ẹṣin tí yóò pèsè àsálà fún ọkàn ara rẹ̀.+ 16  Ní ti ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ le lára àwọn alágbára ńlá, ìhòòhò ni yóò sá lọ ní ọjọ́ yẹn,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé