Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 9:1-57

9  Nígbà tí ó ṣe, Ábímélékì+ ọmọkùnrin Jerubáálì lọ sí Ṣékémù,+ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn àti gbogbo ìdílé ilé ìyá baba rẹ̀ sọ̀rọ̀, pé:  “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ̀rọ̀ ní etí-ìgbọ́ gbogbo àwọn onílẹ̀ Ṣékémù pé, ‘Èwo ni ó sàn jù fún yín, kí àádọ́rin ọkùnrin,+ gbogbo ọmọkùnrin Jerubáálì, ṣàkóso lé yín lórí tàbí kí ọkùnrin kan ṣoṣo ṣàkóso lé yín lórí? Kí ẹ sì rántí pé egungun yín àti ẹran ara yín ni èmi.’”+  Nítorí náà, àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa rẹ̀ ní etí-ìgbọ́ gbogbo àwọn onílẹ̀ Ṣékémù tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà wọn tẹ̀ síhà Ábímélékì,+ nítorí wọ́n wí pé: “Arákùnrin tiwa ni.”+  Nígbà náà ni wọ́n fún un ní àádọ́rin ẹyọ fàdákà láti inú ilé Baali-bérítì,+ Ábímélékì sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n háyà àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan àti aláfojúdi,+ kí wọ́n lè máa bá a rìn.  Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ọ́fírà,+ ó sì pa àwọn arákùnrin rẹ̀,+ àwọn ọmọkùnrin Jerubáálì, àádọ́rin ọkùnrin, lórí òkúta kan, ṣùgbọ́n ó ṣẹ́ ku Jótámù, ọmọkùnrin tí Jerubáálì bí kẹ́yìn, nítorí pé ó fi ara pa mọ́.  Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn onílẹ̀ Ṣékémù àti gbogbo ilé Mílò+ kóra jọpọ̀, wọ́n sì lọ, wọ́n sì mú kí Ábímélékì jẹ ọba,+ nítòsí igi ńlá náà,+ ọwọ̀n tí ó wà ní Ṣékémù.+  Nígbà tí a ròyìn èyí fún Jótámù, ó lọ kíákíá, ó sì dúró ní orí Òkè Ńlá Gérísímù,+ ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì ké jáde, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin onílẹ̀ Ṣékémù, kí Ọlọ́run sì fetí sí yín:  “Nígbà kan rí, àwọn igi lọ fòróró yan ọba lórí ara wọn. Nítorí náà, wọ́n wí fún igi olífì+ pé, ‘Jẹ ọba lórí wa.’+  Ṣùgbọ́n igi olífì wí fún wọn pé, ‘Ṣé kí n fi ọ̀rá mi sílẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń yin Ọlọ́run àti ènìyàn lógo,+ kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’+ 10  Nígbà náà ni àwọn igi wí fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé,+ ‘Ìwọ wá, jẹ́ ọbabìnrin lórí wa.’ 11  Ṣùgbọ́n igi ọ̀pọ̀tọ́ wí fún wọn pé, ‘Ṣé kí n fi dídùn àti àmújáde mi tí ó dára sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’+ 12  Lẹ́yìn náà, àwọn igi wí fún igi àjàrà pé, ‘Ìwọ wá, jẹ́ ọbabìnrin lórí wa.’ 13  Ẹ̀wẹ̀, àjàrà wí fún wọn pé, ‘Ṣé kí n fi wáìnì tuntun mi tí ń mú kí Ọlọ́run àti ènìyàn máa yọ̀+ sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi?’ 14  Níkẹyìn, gbogbo àwọn igi yòókù wí fún igi ẹlẹ́gún+ pé, ‘Ìwọ wá, jẹ ọba lórí wa.’ 15  Látàrí èyí, igi ẹlẹ́gún wí fún àwọn igi pé, ‘Bí ó bá jẹ́ ní òtítọ́ ni ẹ fi ń fòróró yàn mí ṣe ọba lórí yín, ẹ wá, kí ẹ wá ibi ìsádi lábẹ́ òjì ji mi.+ Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí iná+ jáde wá lára igi ẹlẹ́gún kí ó sì jó àwọn kédárì+ Lẹ́bánónì+ run.’ 16  “Wàyí o, bí ó bá jẹ́ ní òtítọ́ àti ní àìlálèébù ni ẹ gbé ìgbésẹ̀, tí ẹ sì lọ fi Ábímélékì jẹ ọba,+ bí ó bá sì jẹ́ oore ni ẹ ṣe fún Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀, bí ẹ bá sì ti ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, 17  nígbà tí baba mi jà+ fún yín, tí ó sì lọ ń fi ọkàn+ rẹ̀ wewu, kí ó lè dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ Mídíánì;+ 18  tí ẹ̀yin, ní tiyín, sì ti dìde sí agbo ilé baba mi lónìí, kí ẹ lè pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ àádọ́rin ọkùnrin,+ lórí òkúta kan, kí ẹ sì lè fi Ábímélékì, ọmọkùnrin ẹrúbìnrin rẹ̀,+ jẹ ọba+ lórí àwọn onílẹ̀ Ṣékémù, kìkì nítorí pé ó jẹ́ arákùnrin yín; 19  bẹ́ẹ̀ ni, bí ó bá jẹ́ ní òtítọ́ àti ní àìlálèébù ni ẹ gbé ìgbésẹ̀ sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀ ní òní yìí, ẹ yọ̀ lórí Ábímélékì kí òun pẹ̀lú sì yọ̀ lórí yín.+ 20  Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí iná+ ti ọ̀dọ̀ Ábímélékì jáde wá kí ó sì jó àwọn onílẹ̀ Ṣékémù àti ilé Mílò+ run, kí iná+ sì ti ọ̀dọ̀ àwọn onílẹ̀ Ṣékémù àti ilé Mílò jáde wá kí ó sì jó Ábímélékì+ run.” 21  Nígbà náà ni Jótámù+ fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Bíà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀ nítorí Ábímélékì arákùnrin rẹ̀. 22  Ábímélékì sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe bí ọmọ aládé lórí Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta.+ 23  Nígbà náà ni Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí búburú+ dìde láàárín Ábímélékì àti àwọn onílẹ̀ Ṣékémù, àwọn onílẹ̀ Ṣékémù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àdàkàdekè+ sí Ábímélékì, 24  kí ìwà ipá tí a hù sí àwọn àádọ́rin ọmọkùnrin Jerubáálì lè wá,+ kí ó sì lè fi ẹ̀jẹ̀ wọn sórí Ábímélékì arákùnrin wọn, nítorí pé ó pa wọ́n,+ àti sórí àwọn onílẹ̀ Ṣékémù, nítorí pé wọ́n fún ọwọ́+ rẹ̀ lókun láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. 25  Nítorí náà, àwọn onílẹ̀ Ṣékémù dẹ àwọn olùba dè é ní orí àwọn òkè ńlá, wọn a sì ja olúkúlùkù ẹni tí ó bá gba ojú ọ̀nà kọjá lọ̀dọ̀ wọn lólè. Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn rẹ̀ fún Ábímélékì. 26  Nígbà náà ni Gáálì+ ọmọkùnrin Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì sọdá sí Ṣékémù,+ àwọn onílẹ̀ Ṣékémù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀.+ 27  Wọ́n sì jáde lọ sí pápá bí ti tẹ́lẹ̀ rí, wọ́n sì ń kó àwọn èso àjàrà inú àwọn ọgbà àjàrà wọn jọ àti ní títẹ̀ wọ́n àti ní bíbá ayọ̀ ńláǹlà ti àjọyọ̀+ lọ, lẹ́yìn èyí tí wọ́n wọnú ilé ọlọ́run wọn+ lọ, wọ́n sì jẹ, wọ́n sì mu,+ wọ́n sì pe ibi+ wá sórí Ábímélékì. 28  Gáálì ọmọkùnrin Ébédì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ta ni Ábímélékì,+ ta sì ni Ṣékémù tí a ó fi máa sìn ín? Ọmọkùnrin Jerubáálì+ ha kọ́ ni, Sébúlù+ ha sì kọ́ ni kọmíṣọ́nnà rẹ̀? Ẹ máa sin àwọn ọkùnrin Hámórì,+ baba Ṣékémù, ẹ̀yin yòókù, ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwa alára yóò fi máa sìn ín? 29  Àwọn ènìyàn yìí ì bá sì wà ní ọwọ́ mi!+ Nígbà náà ni èmi ì bá mú Ábímélékì kúrò.” Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún Ábímélékì pé: “Mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ pọ̀ níye kí o sì jáde wá.”+ 30  Sébúlù ọmọ aládé ìlú ńlá náà sì wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Gáálì ọmọkùnrin Ébédì.+ Nígbà náà ni ìbínú rẹ̀ ru. 31  Nítorí náà, ó fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí rán àwọn ońṣẹ́ sí Ábímélékì pé: “Wò ó! Gáálì ọmọkùnrin Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti dé sí Ṣékémù+ báyìí, sì kíyè sí i, wọ́n ń wọ́ ìlú ńlá náà jọpọ̀ lòdì sí ọ. 32  Wàyí o, dìde ní òru,+ ìwọ àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì lúgọ+ sí pápá. 33  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé gbàrà tí oòrùn bá ti ràn kí o dìde ní kùtùkùtù, kí o sì rọ́ gììrì lu ìlú ńlá náà; nígbà tí òun àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá sì ń jáde lọ láti gbéjà kò ọ́, kí ìwọ sì ṣe sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ rẹ bá ti rí i pé ó ṣeé ṣe.” 34  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ábímélékì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde ní òru, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lúgọ de Ṣékémù ní àwùjọ ọmọ ogun mẹ́rin. 35  Lẹ́yìn náà, Gáálì+ ọmọkùnrin Ébédì jáde lọ, ó sì dúró ní ibi àbáwọ ẹnubodè ìlú ńlá náà. Nígbà náà ni Ábímélékì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde láti ibùba. 36  Nígbà tí Gáálì tajú kán rí àwọn ènìyàn náà, kíákíá ni ó wí fún Sébúlù pé: “Wò ó! Àwọn ènìyàn ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti orí àwọn òkè ńlá.” Ṣùgbọ́n Sébúlù wí fún un pé: “Òjì ji àwọn òkè ńlá ni ìwọ ń rí bí ẹni pé ènìyàn ni wọ́n.”+ 37  Lẹ́yìn náà, Gáálì sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì wí pé: “Wò ó! Àwọn ènìyàn ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti àárín ilẹ̀, àwùjọ ọmọ ogun kan sì ń gba ọ̀nà igi ńlá Méónẹ́nímù bọ̀.” 38  Látàrí èyí, Sébúlù wí fún un pé: “Ibo ni àsọjáde rẹ yẹn wà nísinsìnyí tí o fi dánnu pé,+ ‘Ta ni Ábímélékì tí a ó fi sìn ín?’+ Kì  í ha ṣe àwọn ènìyàn yìí ni o kọ̀?+ Wàyí o, jáde lọ, jọ̀wọ́, kí o sì bá wọn jà.” 39  Nítorí náà, Gáálì jáde lọ ní iwájú àwọn onílẹ̀ Ṣékémù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Ábímélékì jà. 40  Ábímélékì sì gbá tẹ̀ lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ níwájú rẹ̀; àwọn tí a pa sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣubú ní iye púpọ̀ títí dé ibi àbáwọ ẹnubodè. 41  Ábímélékì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní Árúmà, Sébúlù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí lé Gáálì+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde kúrò ní gbígbé ní Ṣékémù.+ 42  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì  pé àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ sí pápá. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Ábímélékì.+ 43  Nítorí bẹ́ẹ̀, ó kó àwọn ènìyàn náà, ó sì pín wọn sí àwùjọ ọmọ ogun mẹ́ta,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lúgọ sí pápá. Nígbà náà ní ó wò, sì kíyè sí i àwọn ènìyàn ń jáde kúrò nínú ìlú ńlá náà. Ó sì dìde sí wọn wàyí, ó sì ṣá wọn balẹ̀. 44  Ábímélékì àti àwùjọ ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì rọ́ gììrì kí wọ́n lè dúró sí ibi àbáwọ ẹnubodè ìlú ńlá náà, nígbà tí àwùjọ ọmọ ogun méjì  rọ́ gììrì lu gbogbo àwọn tí ó wà ní pápá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn balẹ̀.+ 45  Ábímélékì sì bá ìlú ńlá náà jà ní gbogbo ọjọ́ yẹn, ó sì gba ìlú ńlá náà; ó sì pa àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀,+ lẹ́yìn èyí tí ó bi ìlú ńlá náà wó,+ ó sì fún iyọ̀ sí i.+ 46  Nígbà tí gbogbo àwọn onílẹ̀ ilé gogoro Ṣékémù gbọ́ ọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n lọ sí ihò abẹ́lẹ̀ ilé Eli-bérítì.+ 47  Nígbà náà ni a ròyìn fún Ábímélékì pé gbogbo àwọn onílẹ̀ ilé gogoro Ṣékémù ti kóra jọpọ̀. 48  Látàrí ìyẹn, Ábímélékì gun Òkè Ńlá Sálímónì+ lọ, òun àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Wàyí o, Ábímélékì mú àáké kan lọ́wọ́, ó sì gé ẹ̀ka kan lára àwọn igi, ó gbé e sókè, ó sì gbé e lé èjì ká rẹ̀, ó sì wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ohun tí ẹ rí tí mo ṣe—ní wéréwéré, ẹ ṣe bí tèmi!”+ 49  Nítorí náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú gé ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan, olúkúlùkù fún ara rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ Ábímélékì lẹ́yìn. Nígbá náà ni wọ́n kó wọn ti ihò abẹ́lẹ̀ náà, wọ́n sì dáná ran ihò abẹ́lẹ̀ náà lórí wọn, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn ènìyàn ilé gogoro Ṣékémù kú pẹ̀lú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọkùnrin àti obìnrin.+ 50  Ábímélékì sì tẹ̀ síwájú lọ sí Tébésì+ láti dó ti Tébésì kí ó sì gbà á. 51  Níwọ̀n bí ó ti ṣẹlẹ̀ pé ilé gogoro lílágbára kan wà ní àárín ìlú ńlá náà, ibẹ̀ ni ibi tí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn onílẹ̀ ìlú ńlá náà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, lẹ́yìn èyí tí wọ́n tì í mọ́ ara wọn, wọ́n sì gun orí òrùlé ilé gogoro náà lọ. 52  Ábímélékì sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilé gogoro náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé gogoro náà láti fi iná sun ún.+ 53  Nígbà náà ni obìnrin kan ju ọmọ ọlọ lu orí Ábímélékì, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀.+ 54  Nítorí náà, kíákíá ni ó pe ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ó ru àwọn ohun ìjà rẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Fa idà rẹ yọ kí o sì fi ikú pa mí,+ kí wọ́n má bàa wí nípa mi pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹmẹ̀wà rẹ̀ gún un ní àgúnyọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú.+ 55  Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá rí i pé Ábímélékì ti kú, olúkúlùkù wọ́n wá lọ sí ipò rẹ̀. 56  Bí Ọlọ́run ṣe mú ibi Ábímélékì tí ó ṣe sí baba rẹ̀ nípa pípa àádọ́rin arákùnrin rẹ̀ padà wá nìyẹn.+ 57  Gbogbo ibi àwọn ọkùnrin Ṣékémù sì ni Ọlọ́run mú padà wá sí orí wọn, kí ìfiré+ Jótámù+ ọmọkùnrin Jerubáálì+ lè wá sórí wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé