Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 8:1-35

8  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Éfúráímù wí fún un pé: “Irú ohun wo nìyí tí o ṣe sí wa ní ṣíṣàìpè wá nígbà tí o lọ bá Mídíánì jà?”+ Wọ́n sì gbìyànjú kíkankíkan láti bẹ̀rẹ̀ aáwọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+  Níkẹyìn, ó wí fún wọn pé: “Kí ni mo ṣe nísinsìnyí ní ìfiwéra pẹ̀lú yín?+ Èéṣẹ́ Éfúráímù+ kò ha sàn ju ìkójọ èso àjàrà Abi-ésérì?+  Ẹ̀yin ni Ọlọ́run fi Órébù àti Séébù,+ àwọn ọmọ aládé Mídíánì, lé lọ́wọ́, kí sì ni mo tíì ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú yín?” Ìgbà náà ni ẹ̀mí wọn rọ̀ wọ̀ọ̀ sí i nígbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Gídíónì wá sí Jọ́dánì, wọ́n sọdá rẹ̀, òun àti ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó ti rẹ̀ wọ́n ṣùgbọ́n wọ́n ń bá ìlépa náà nìṣó.  Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ọkùnrin Súkótù+ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún àwọn ènìyàn tí ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ mi+ ní àwọn ìṣù búrẹ́dì ribiti, nítorí tí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Séébà+ àti Sálímúnà,+ àwọn ọba Mídíánì.”  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ aládé Súkótù wí pé: “Àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà ha ti wà ní ọwọ́ rẹ nísinsìnyí tí a ó fi fi búrẹ́dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ?”+  Látàrí èyí, Gídíónì wí pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí Jèhófà bá fi Séébà àti Sálímúnà lé mi lọ́wọ́, dájúdájú, èmi yóò fi àwọn ẹ̀gún aginjù àti ẹ̀gún ọ̀gàn+ pa ẹran ara yín bí ẹni pakà.”  Ó sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ gòkè lọ láti ibẹ̀ sí Pénúélì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ ní irú ọ̀nà kan náà yìí, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Pénúélì dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin Súkótù ti dá a lóhùn gan-an.  Nítorí náà, ó wí fún àwọn ọkùnrin Pénúélì pẹ̀lú pé: “Nígbà tí mo bá padà ní àlàáfíà, èmi yóò bi ilé gogoro yìí wó.”+ 10  Wàyí o, Séébà àti Sálímúnà+ wà ní Kákórì, àwọn ibùdó wọn sì wà pẹ̀lú wọn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni gbogbo ẹni tí ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ibùdó àwọn Ará Ìlà-Oòrùn+ pátá; àwọn tí ó sì ti ṣubú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà ọkùnrin tí wọ́n máa ń fa idà yọ.+ 11  Gídíónì sì ń tẹ̀ síwájú gòkè lọ gba ti ọ̀nà àwọn tí ń gbé inú àgọ́ níhà ìlà-oòrùn Nóbà àti Jógíbéhà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ibùdó náà nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ pé ibùdó náà kò fura.+ 12  Nígbà tí Séébà àti Sálímúnà fẹsẹ̀ fẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn ní kíá, ó sì mú ọba Mídíánì méjèèjì , Séébà àti Sálímúnà;+ ó sì fi gbogbo ibùdó náà sínú ìwárìrì. 13  Gídíónì ọmọkùnrin Jóáṣì sì padà láti ojú ogun náà gba ọ̀nà àbákọjá tí ó gòkè lọ sí Hérésì. 14  Lójú ọ̀nà, ó mú ọ̀dọ́kùnrin kan lára àwọn ọkùnrin Súkótù,+ ó sì wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.+ Nítorí náà, ó kọ orúkọ àwọn ọmọ aládé+ Súkótù àti àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ fún un, ọkùnrin mẹ́tà-dín-lọ́gọ́rin. 15  Pẹ̀lú ìyẹn, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Súkótù, ó sì wí pé: “Séébà àti Sálímúnà tí ẹ tìtorí wọn ṣáátá mi rèé, pé, ‘Àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà ha ti wà ní ọwọ́ rẹ nísinsìnyí tí a o fi fi búrẹ́dì fún àwọn ọkùnrin rẹ tí àárẹ̀ ti mú?’”+ 16  Nígbà náà ni ó mú àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà àti àwọn ẹ̀gún aginjù àti ẹ̀gún ọ̀gàn, ó sì fi wọ́n kọ́ àwọn ọkùnrin Súkótù lọ́gbọ́n.+ 17  Ilé gogoro Pénúélì+ ni ó sì bì wó,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà. 18  Wàyí o, ó wí fún Séébà àti Sálímúnà+ pé: “Irú àwọn ọkùnrin wo ni àwọn ẹni tí ẹ pa ní Tábórì?”+ Wọ́n fèsì pé: “Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí, olúkúlùkù, bí ọmọkùnrin ọba ní ìrísí.” 19  Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Arákùnrin mi ni wọ́n, ọmọ ìyá mi. Bí Jèhófà ti ń bẹ, ká ní ẹ pa wọ́n mọ́ láàyè ni, èmi kì bá ní láti pa yín.”+ 20  Nígbà náà, ó wí fún Jétà àkọ́bí rẹ̀ pé: “Dìde, pa wọ́n.” Ọ̀dọ́kùnrin náà kò sì fa idà rẹ̀ yọ, nítorí tí àyà ń fò ó, nítorí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin.+ 21  Nítorí náà, Séébà àti Sálímúnà wí pé: “Dìde fúnra rẹ kí o sì fipá kọlù wá, nítorí bí ọkùnrin bá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni agbára ńlá rẹ̀ ṣe ń rí.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Gídíónì dìde, ó sì pa+ Séébà àti Sálímúnà, ó sì bọ́ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí òṣùpá tí ó wà ni ọrùn àwọn ràkúnmí wọn. 22  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé: “Ṣàkóso lórí wa,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá là lọ́wọ́ Mídíánì.”+ 23  Ṣùgbọ́n Gídíónì wí fún wọn pé: “Èmi fúnra mi kì yóò ṣàkóso lórí yín,+ bẹ́ẹ̀ ni ọmọkùnrin mi kì yóò ṣàkóso lórí yín, Jèhófà ni ẹni tí yóò ṣàkóso lórí yín.”+ 24  Gídíónì sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí ń tọrọ kiní kan lọ́wọ́ yín: Olúkúlùkù yín, ẹ fún mi ní òrùka imú+ tí ó wà nínú ẹrù àkótogunbọ̀ rẹ̀.” (Nítorí tí wọ́n ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, nítorí pé ọmọ Íṣímáẹ́lì+ ni wọ́n.) 25  Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “A ó fi wọ́n fún ọ dájúdájú.” Pẹ̀lú ìyẹn, wọ́n tẹ́ aṣọ àlàbora kan, olúkúlùkù wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ òrùka imú tí ó wà nínú ẹrù àkótogunbọ̀ rẹ̀ sínú rẹ̀. 26  Ìwọ̀n òrùka imú tí a fi wúrà ṣe tí ó sì béèrè fún jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ṣékélì wúrà, yàtọ̀ sí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí òṣùpá+ àti àwọn yẹtí jọlọjọlọ àti àwọn ẹ̀wù irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró,+ tí ó wà lára àwọn ọba Mídíánì, àti yàtọ̀ sí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí.+ 27  Gídíónì sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe éfódì+ kan, ó sì fi í hàn ní Ọ́fírà+ ìlú ńlá rẹ̀; gbogbo Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀,+ tí ó fi wá jẹ́ ìdẹkùn fún Gídíónì àti fún agbo ilé rẹ̀.+ 28  Bí a ṣe tẹ Mídíánì+ lórí ba nìyẹn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn kò sì gbé orí wọn sókè mọ́ rárá; ilẹ̀ náà kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan mọ́ fún ogójì  ọdún ní àwọn ọjọ́ Gídíónì.+ 29  Jerubáálì+ ọmọkùnrin Jóáṣì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ilé rẹ̀. 30  Gídíónì sì wá ní àádọ́rin ọmọkùnrin+ tí ó jáde wá láti òkè itan rẹ̀, nítorí tí ó ní aya púpọ̀. 31  Ní ti wáhàrì rẹ̀ tí ó wà ní Ṣékémù, òun pẹ̀lú bí ọmọkùnrin kan fún un. Nítorí náà, ó sọ ọ́ ní Ábímélékì.+ 32  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Gídíónì ọmọkùnrin Jóáṣì kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, a sì sin ín sí ibi ìsìnkú Jóáṣì baba rẹ̀ ní Ọ́fírà ti àwọn ọmọ Abi-ésérì.+ 33  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Gídíónì kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn Báálì,+ tí wọ́n fi yan Baali-bérítì ṣe ọlọ́run wọn.+ 34  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì rántí Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ ẹni tí ó dá wọn nídè kúrò ní ọwọ́ gbogbo ọ̀tá wọn yíká-yíká;+ 35  Wọn kò sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí agbo ilé Jerubáálì, Gídíónì, ní ìsanpadà fún gbogbo oore tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé