Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 7:1-25

7  Nígbà náà ni Jerubáálì,+ èyíinì ni, Gídíónì,+ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, dìde ní kùtùkùtù, wọ́n sì dó síbi kànga Háródù; ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ibùdó Mídíánì wà ní àríwá rẹ̀, ní òkè kékeré Mórè, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.  Wàyí o, Jèhófà wí fún Gídíónì pé: “Àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ ti pọ̀ jù fún mi láti fi Mídíánì lé wọn lọ́wọ́.+ Ó ṣeé ṣe kí Ísírẹ́lì fọ́nnu+ nípa ara rẹ̀ sí mi pé, ‘Ọwọ́ mi ni ó gbà mí là.’+  Wàyí o, ké jáde, jọ̀wọ́, ní etí-ìgbọ́ àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ta ní ń bẹ níbẹ̀ tí ń fòyà tí ó sì ń wárìrì? Kí ó padà sẹ́yìn.’”+ Nítorí náà, Gídíónì dán wọn wò. Pẹ̀lú ìyẹn, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá lára àwọn ènìyàn náà padà sẹ́yìn, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni ó sì ṣẹ́ kù.  Síbẹ̀, Jèhófà wí fún Gídíónì pé: “Àwọn ènìyàn ṣì pọ̀ jù síbẹ̀síbẹ̀.+ Mú kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi omi kí n lè dán wọn wò fún ọ níbẹ̀. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ẹnì yòówù tí èmi bá wí nípa rẹ̀ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí ni yóò bá ọ lọ,’ òun ni ẹni tí yóò bá ọ lọ, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí èmi bá wí nípa rẹ̀ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí kì yóò bá ọ lọ,’ òun ni ẹni tí kò ní bá ọ lọ.”  Nítorí náà, ó mú kí àwọn ènìyàn náà sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi omi.+ Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Gídíónì pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi ahọ́n rẹ̀ lá lára omi náà gẹ́gẹ́ bí ajá ti ń lá omi gan-an, ìwọ yóò dá a yà sọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá tẹ̀ ba lórí eékún rẹ̀ láti mu pẹ̀lú.”+  Iye àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ wọn bu omi sẹ́nu lá wá jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin. Ní ti gbogbo ìyókù àwọn ènìyàn náà, wọ́n tẹ̀ ba lórí eékún wọn láti mu omi.  Wàyí o, Jèhófà wí fún Gídíónì pé: “Nípasẹ̀ ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò gbà yín là, èmi yóò sì fi Mídíánì lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú.+ Ní ti gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, jẹ́ kí wọ́n lọ, olúkúlùkù sí ipò rẹ̀.”  Nítorí náà, wọ́n gba ìpèsè oúnjẹ àwọn ènìyàn náà ní ọwọ́ wọn, àti ìwo wọn,+ gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì ni ó sì rán lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ó sì dá ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà dúró. Ní ti ibùdó Mídíánì, ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà nísàlẹ̀ rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru+ yẹn pé Jèhófà tẹ̀ síwájú láti wí fún un pé: “Dìde, sọ̀ kalẹ̀ sórí ibùdó náà, nítorí tí mo ti fi í lé ọ lọ́wọ́.+ 10  Ṣùgbọ́n bí o bá ń fòyà láti sọ̀ kalẹ̀ lọ, sọ̀ kalẹ̀ lọ, ìwọ pẹ̀lú Púrà ẹmẹ̀wà rẹ, sí ibùdó náà.+ 11  Kí ìwọ sì fetí sí ohun tí wọn yóò sọ,+ lẹ́yìn ìgbà náà, ọwọ́ rẹ yóò di alágbára dájúdájú,+ ìwọ yóò sì sọ̀ kalẹ̀ sórí ibùdó náà dájúdájú.” Látàrí ìyẹn, òun àti Púrà ẹmẹ̀wà rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí etí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó tẹ́gun tí ó wà ní ibùdó. 12  Wàyí o, Mídíánì àti Ámálékì àti gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn+ kó jọpọ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ní iye tí ó pọ̀ bí eéṣú;+ àwọn ràkúnmí+ wọn kò sì níye, wọ́n pọ̀ níye bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun. 13  Gídíónì dé wàyí, sì wò ó! ọkùnrin kan ń rọ́ àlá fún alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Àlá tí mo lá rèé.+ Sì  wò ó! búrẹ́dì ribiti tí a fi ọkà bálì ṣe ń yí gbirigbiri bọ̀ wá sínú ibùdó Mídíánì. Nígbà náà ni ó dé àgọ́ kan, ó sì kọlù ú tí ó fi ṣubú,+ ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì ṣubú lulẹ̀ bẹẹrẹ.” 14  Látàrí èyí, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dáhùn+ ó sì wí pé: “Èyí kì í ṣe nǹkan mìíràn bí kò ṣe idà Gídíónì+ ọmọkùnrin Jóáṣì, ọkùnrin kan láti Ísírẹ́lì. Ọlọ́run tòótọ́+ ti fi Mídíánì àti gbogbo ibùdó náà lé e lọ́wọ́.”+ 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Gídíónì gbọ́ rírọ́ àlá náà àti àlàyé rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn.+ Lẹ́yìn náà, ó padà sí ibùdó Ísírẹ́lì, ó sì wí pé: “Ẹ dìde,+ nítorí tí Jèhófà ti fi ibùdó Mídíánì lé yín lọ́wọ́.” 16  Nígbà náà ni ó pín ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà sí àwùjọ ọmọ ogun mẹ́ta, ó sì fi ìwo+ lé gbogbo wọn lọ́wọ́ àti òfìfo ìṣà títóbi, àti ògùṣọ̀ nínú àwọn ìṣà títóbi náà. 17  Ó sì tẹ̀ síwájú láti wí fún wọn pé: “Kí ẹ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwò mí, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí mo bá sì dé etí ibùdó náà, yóò ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé gẹ́gẹ́ bí mo bá ti ṣe gan-an, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin ṣe. 18  Nígbà tí mo bá ti fun ìwo, èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi, kí ẹ̀yin náà fun ìwo, ẹ̀yin pẹ̀lú, yíká-yíká gbogbo ibùdó náà,+ kí ẹ sì wí pé, ‘Ti Jèhófà+ àti ti Gídíónì!’” 19  Nígbà tí ó ṣe, Gídíónì dé pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sí etí ibùdó ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣọ́ àárín òru.+ Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yíyan àwọn ológun adènà sáyè iṣẹ́ wọn ni. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo,+ wọ́n sì fọ́ ìṣà omi títóbi tí ó wà ní ọwọ́ wọn+ túútúú. 20  Látàrí ìyẹn, àwùjọ ọmọ ogun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà fun ìwo,+ wọ́n sì fọ́ àwọn ìṣà títóbi náà túútúú, wọ́n sì fi ọwọ́ òsì wọn di ògùṣọ̀ mú lákọ̀tun àti ọwọ́ ọ̀tún wọn lára ìwo láti fun ún, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde pé: “Idà Jèhófà+ àti ti Gídíónì!” 21  Ní gbogbo àkókò náà, wọ́n dúró, olúkúlùkù ní àyè rẹ̀ yí ibùdó náà ká, gbogbo ibùdó náà sì ki iré mọ́lẹ̀, wọ́n sì ń hó yèè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.+ 22  Àwọn ọ̀ọ́dúnrún náà+ sì ń bá a lọ láti fun ìwo,+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí yí idà olúkúlùkù padà sí ẹnì kejì  rẹ̀ ní gbogbo ibùdó náà;+ ibùdó náà sì ń bá a nìṣó ní fífẹsẹ̀ fẹ títí dé Bẹti-ṣítà, lọ dé Sérérà, títí dé ẹ̀yìn odi Ebẹli-méhólà+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tábátì. 23  Láàárín àkókò náà, a pe àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ láti Náfútálì+ àti Áṣérì+ àti gbogbo Mánásè,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ Mídíánì. 24  Gídíónì sì rán àwọn ońṣẹ́ sí gbogbo ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù+ pé: “Ẹ sọ̀ kalẹ̀ lọ pàdé Mídíánì, kí ẹ sì gba àwọn omi náà ṣáájú wọn títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì.” Nítorí náà, a pe gbogbo àwọn ọkùnrin Éfúráímù jọ, wọ́n sì gba àwọn omi+ náà títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì. 25  Wọ́n sì mú àwọn ọmọ aládé Mídíánì méjèèjì , èyíinì ni, Órébù àti Séébù;+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pa Órébù lórí àpáta Órébù,+ wọ́n sì pa Séébù ní ẹkù wáìnì Séébù. Wọ́n sì ń bá a níṣò ní lílépa Mídíánì,+ wọ́n sì gbé orí Órébù àti ti Séébù wá fún Gídíónì ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé