Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 5:1-31

5  Ní ọjọ́ náà, Dèbórà+ pa pọ̀ pẹ̀lú Bárákì+ ọmọkùnrin Ábínóámù+ sì bú sí orin+ pé:  “Nítorí jíjẹ́ kí irun tú sílẹ̀ jọwọrọ fún ogun ní Ísírẹ́lì, Nítorí tí àwọn ènìyàn náà fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn,+ Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+  Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọba;+ ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin onípò àṣẹ gíga-gíga: Èmi, bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò kọrin sí Jèhófà. Èmi yóò kọ orin atunilára+ sí Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+  Jèhófà, nígbà ìjáde lọ rẹ láti Séírì,+ Nígbà lílọ rẹ láti pápá Édómù,+ Ìlẹ̀ ayé mì jì gìjì gì,+ ọ̀run pẹ̀lú kán tótó,+ Awọsánmà pẹ̀lú kán omi tótó.  Àwọn òkè ńlá ṣàn lọ kúrò ní ojú Jèhófà,+ Sínáì yìí+ lọ kúrò ní ojú Jèhófà,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+  Ní àwọn ọjọ́ Ṣámúgárì+ ọmọkùnrin Ánátì, Ní àwọn ọjọ́ Jáẹ́lì,+ kò sí èrò ní ọ̀nà Àwọn arìnrìn-àjò ní àwọn òpópónà a sì rin ìrìn àjò gba àwọn ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ.+  Àwọn olùgbé ilẹ̀ gbalasa kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n kásẹ̀ nílẹ̀ ní Ísírẹ́lì,+ Títí èmi, Dèbórà,+ fi dìde, Títí mo fi dìde gẹ́gẹ́ bí ìyá ní Ísírẹ́lì.+  Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn ọlọ́run tuntun.+ Ìgbà náà ni ogun wà ní àwọn ẹnubodè.+ A kò rí apata kan, tàbí aṣóró kan, Láàárín ọ̀kẹ́ méjì ní Ísírẹ́lì.+  Ọkàn-àyà mi wà fún àwọn ọ̀gágun Ísírẹ́lì,+ Tí wọ́n fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láàárín àwọn ènìyàn náà.+ Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ 10  Ẹ̀yin olùgun abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláwọ̀ pupa àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò,+ Ẹ̀yin tí ó jókòó sórí àwọn kápẹ́ẹ̀tì tí ó gbówó lórí, Àti ẹ̀yin tí ń rìn lójú ọ̀nà, Ẹ gbà á rò!+ 11  Ohùn bí mélòó kan lára ohùn àwọn olùpín omi fúnni ní àwọn ibi ìpọnmi,+ Ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn àwọn ìṣe òdodo Jèhófà lẹ́sẹẹsẹ,+ Àwọn ìṣe òdodo àwọn olùgbé ilẹ̀ gbalasa ní Ísírẹ́lì. Ìgbà náà ni àwọn ènìyàn Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà wọn sí àwọn ẹnubodè. 12  Jí, jí, ìwọ Dèbórà;+ Jí, jí, kọ orin kan!+ Dìde, Bárákì,+ kí o sì kó àwọn òǹdè rẹ lọ, ìwọ ọmọkùnrin Ábínóámù!+ 13  Ìgbà náà ni àwọn olùlàájá sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́lá ọba; Àwọn ènìyàn Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi lòdì sí àwọn alágbára ńlá. 14  Láti inú Éfúráímù ni wọ́n ti pilẹ̀ṣẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀,+ Pẹ̀lú rẹ, ìwọ Bẹ́ńjámínì, lára àwọn ènìyàn rẹ. Láti inú Mákírù+ ni àwọn ọ̀gágun ti sọ̀ kalẹ̀ lọ, Àti láti inú Sébúlúnì àwọn tí ń lo ohun ìṣiṣẹ́ akọ̀wé òfin.+ 15  Àwọn ọmọ aládé ní Ísákárì+ sì wà pẹ̀lú Dèbórà, Bí Ísákárì sì ti rí, bẹ́ẹ̀ ni Bárákì+ rí. A rán an pé kí ó lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ní rírinsẹ̀.+ Láàárín àwọn ìpín Rúbẹ́nì a ṣe ọ̀pọ̀ wíwá inú ọkàn-àyà.+ 16  Èé ṣe tí o fi jókòó sáàárín àpò gàárì méjì , Láti fetí sí orin àwọn fèrè ape fún àwọn agbo ẹran?+ Fún àwọn ìpín Rúbẹ́nì a ṣe ọ̀pọ̀ wíwá inú ọkàn-àyà.+ 17  Gílíádì jókòó pa sí ibùgbé rẹ̀ ní ìhà kejì Jọ́dánì;+ Àti Dánì, èé ṣe tí ó fi ń bá a lọ ní gbígbé nínú àwọn ọkọ̀ òkun ní àkókò náà?+ Áṣérì jókòó gẹlẹtẹ sí etíkun, Ẹ̀bá àwọn ibi ìgúnlẹ̀sí rẹ̀ ni ó sì ń gbé nìṣó.+ 18  Sébúlúnì ni àwọn ènìyàn tí ó pẹ̀gàn ọkàn ara wọn títí dé ojú ikú;+ Náfútálì+ pẹ̀lú, lórí àwọn ibi gíga pápá.+ 19  Àwọn ọba wá, wọ́n jà; Ìgbà náà ni àwọn ọba Kénáánì jà+ Ní Táánákì+ lẹ́bàá omi Mẹ́gídò.+ Wọn kò gba èrè fàdákà kankan.+ 20  Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run,+ Láti àwọn ipa ọ̀nà ìyípo wọn ni wọ́n ti bá Sísérà jà. 21  Ọ̀gbàrá Kíṣónì gbá wọn lọ,+ Ọ̀gbàrá àwọn ọjọ́ ìgbàanì, ọ̀gbàrá Kíṣónì.+ Ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí tẹ okun+ mọ́lẹ̀, ìwọ ọkàn mi. 22  Ìgbà náà ni àwọn pátákò ẹṣin talẹ̀+ Nítorí ìrọ́gììrì tẹ̀ lé ìrọ́gììrì àwọn akọ ẹṣin rẹ̀. 23  ‘Ẹ gégùn-ún+ fún Mérósì,’ ni áńgẹ́lì Jèhófà wí,+ ‘Ẹ gégùn-ún fún àwọn olùgbé rẹ̀ láìdábọ̀, Nítorí tí wọn kò wá sí ìrànwọ́ Jèhófà, Sí ìrànwọ́ Jèhófà pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá.’ 24  Jáẹ́lì+ aya Hébà tí í ṣe Kénì+ yóò jẹ́ alábùkún jù lọ láàárín àwọn obìnrin, Láàárín àwọn obìnrin inú àgọ́, yóò jẹ́ alábùkún jù lọ.+ 25  Omi ni ó béèrè, wàrà ni ó fún un; Àwokòtò ńlá fún àsè ọlọ́lá ọba ni ó fi gbé wàrà dídì wá.+ 26  Nígbà náà ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ìkànlẹ̀ àgọ́, Àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òòlù igi ti àwọn òṣìṣẹ́ kára.+ Ó sì fi òòlù lu Sísérà, ó dá orí rẹ̀ lu,+ Ó fọ́ àwọn ẹ̀bátí rẹ̀ sí wẹ́wẹ́, ó sì gé e yánnayànna. 27  Àárín ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó wó lulẹ̀ sí, ó ṣubú, ó dùbúlẹ̀; Àárín ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó wó lulẹ̀ sí, ó ṣubú; Ibi tí ó wó lulẹ̀ sí, ibẹ̀ ni ó ṣubú sí ní ẹni tí a ṣẹ́pá.+ 28  Obìnrin kan yọjú lójú fèrèsé, ó sì ń fojú sọ́nà fún un, Ìyá Sísérà láti ibi àgánrándì fèrèsé,+ ‘Èé ṣe tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ fi jáfara ní dídé?+ Èé ṣe tí gìrìgìrì ìró pátákò àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ fi ní láti pẹ́ tó bẹ́ẹ̀?’+ 29  Àwọn ọlọ́gbọ́n lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú ìyáàfin+ rẹ̀ yóò dá a lóhùn, Bẹ́ẹ̀ ni, òun pẹ̀lú yóò fi àwọn àsọjáde òun tìkára rẹ̀ fèsì padà fún ara rẹ̀, 30  ‘Kò ha yẹ kí wọ́n rí, kò ha yẹ kí wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ,+ Ilé ọlẹ̀ kan—ilé ọlẹ̀ méjì fún olúkúlùkù abarapá ọkùnrin,+ Ohun ìfiṣèjẹ ti àwọn aṣọ tí a pa láró fún Sísérà, ohun ìfiṣèjẹ ti àwọn aṣọ tí a pa láró, Ẹ̀wù kan tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára, aṣọ tí a pa láró, ẹ̀wù méjì tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára Fún ọrùn àwọn ènìyàn afohunṣèjẹ?’ 31  Báyìí ni kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé,+ Jèhófà, Kí àwọn olùfẹ́+ rẹ sì rí bí ìgbà tí oòrùn bá jáde lọ nínú agbára ńlá+ rẹ̀.” Ilẹ̀ náà kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan mọ́ fún ogójì ọdún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé