Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 4:1-24

4  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà nísinsìnyí tí Éhúdù ti kú.+  Nítorí náà, Jèhófà tà+ wọ́n sí ọwọ́ Jábínì ọba Kénáánì, ẹni tí ó jọba ní Hásórì;+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sì ni Sísérà,+ ó sì ń gbé ní Háróṣétì+ ti àwọn orílẹ̀-èdè.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà,+ nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin,+ òun fúnra rẹ̀ sì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ lára lọ́nà lílekoko fún ogún ọdún.  Wàyí o, Dèbórà, wòlíì obìnrin,+ aya Lápídótù, ní ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní àkókò yẹn gan-an.  Ó sì ń gbé lábẹ́ igi ọ̀pẹ Dèbórà, láàárín Rámà+ àti Bẹ́tẹ́lì,+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a sì máa gòkè lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìdájọ́.  Ó sì ránṣẹ́ pe Bárákì+ ọmọkùnrin Ábínóámù wá láti Kedeṣi-náfútálì,+ ó sì wí fún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kò ha ti pàṣẹ? ‘Lọ, kí o sì tan ara rẹ ká orí Òkè Ńlá Tábórì,+ kí o sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin láti inú àwọn ọmọ Náfútálì+ àti láti inú àwọn ọmọ Sébúlúnì+ pẹ̀lú rẹ.  Dájúdájú, èmi yóò sì fa+ Sísérà+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jábínì+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ wá bá ọ ní àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì,+ èmi yóò sì fi í lé ọ lọ́wọ́.’”+  Látàrí èyí, Bárákì wí fún un pé: “Bí ìwọ yóò bá bá mi lọ, èmi yóò lọ dájúdájú; ṣùgbọ́n bí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”  Ó fèsì pé: “Láìkùnà, èmi yóò bá ọ lọ. Àmọ́ ṣá o, ohun ẹwà náà kì yóò di tìrẹ ní ọ̀nà tí ìwọ ń lọ, nítorí ọwọ́ obìnrin+ ni Jèhófà yóò ta Sísérà sí.” Pẹ̀lú ìyẹn, Dèbórà dìde, ó sì bá Bárákì lọ sí Kédéṣì.+ 10  Bárákì sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Sébúlúnì+ àti Náfútálì jọ sí Kédéṣì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin sì gòkè lọ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀;+ Dèbórà sì gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀. 11  Ó ṣẹlẹ̀ pé Hébà+ tí í ṣe Kénì ti pínyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Hóbábù, ẹni tí Mósè jẹ́ ọkọ ọmọ rẹ̀,+ ó sì ti pa àgọ́ rẹ̀ sí tòsí igi ńlá ní Sáánánímù, èyí tí ó wà ní Kédéṣì. 12  Nígbà náà ni wọ́n ròyìn fún Sísérà pé Bárákì ọmọkùnrin Ábínóámù+ ti gòkè lọ sórí Òkè Ńlá Tábórì.+ 13  Kíákíá, Sísérà pe gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ jọ, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin,+ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, láti inú Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè sí àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì.+ 14  Dèbórà wí fún Bárákì wàyí pé: “Dìde, nítorí èyí ni ọjọ́ tí Jèhófà yóò fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú. Jèhófà ha kọ́ ni ó ti jáde lọ níwájú rẹ?”+ Bárákì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Ńlá Tábórì pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin lẹ́yìn rẹ̀. 15  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kó Sísérà àti gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti gbogbo ibùdó náà sínú ìdàrúdàpọ̀+ níwájú Bárákì. Níkẹyìn, Sísérà sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó sì fi ẹsẹ̀ sá lọ. 16  Bárákì sì lépa+ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ àti ibùdó náà títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ibùdó Sísérà ti ojú idà ṣubú. Ẹyọ kan kò ṣẹ́ kù.+ 17  Ní ti Sísérà,+ ó fi ẹsẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáẹ́lì+ aya Hébà tí í ṣe Kénì,+ nítorí àlàáfíà wà láàárín Jábínì ọba Hásórì+ àti agbo ilé Hébà tí í ṣe Kénì. 18  Nígbà náà ni Jáẹ́lì jáde wá pàdé Sísérà, ó sì wí fún un pé: “Yà síhìn-ín, olúwa mi, yà síhìn-ín lọ́dọ̀ mi. Má fòyà.” Nítorí náà, ó yà sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àgọ́. Lẹ́yìn náà, ó fi kúbùsù bò ó. 19  Nígbà tí ó ṣe, ó wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu, nítorí òùngbẹ ń gbẹ mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣí ìgò awọ+ wàrà, ó sì fún un mu,+ lẹ́yìn èyí tí ó bò ó. 20  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ, tí ó sì wí pé, ‘Ọkùnrin kankan ha wà níhìn-ín bí?’ nígbà náà, kí o sọ pé, ‘Rárá!’” 21  Jáẹ́lì aya Hébà sí tẹ̀ síwájú láti mú ìkànlẹ̀ àgọ́, ó sì fi òòlù sí ọwọ́ rẹ̀. Nígbà náà ni ó yọ́ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì gbá ìkànlẹ̀ náà wọnú àwọn ẹ̀bátí rẹ̀,+ ó sì gbá a wọ ilẹ̀, bí ó ti sùn lọ fọnfọn tí àárẹ̀ sì ti mú un. Nítorí náà, ó kú.+ 22  Sì  wò ó! Bárákì rèé tí ń lépa Sísérà. Wàyí o, Jáẹ́lì jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Wá, èmi yóò sì fi ọkùnrin tí o ń wá hàn ọ́.” Nítorí náà, ó wọlé lọ bá a, sì wò ó! Sísérà rèé tí ó ṣubú síbẹ̀ ní òkú, pẹ̀lú ìkànlẹ̀ náà nínú àwọn ẹ̀bátí rẹ̀. 23  Bí Ọlọ́run ṣe tẹ Jábínì ọba Kénáánì lórí ba+ nìyẹn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọjọ́ yẹn. 24  Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní títúbọ̀ le sí i ní ìdojú-ìjà-kọ Jábínì ọba Kénáánì,+ títí wọ́n fi ké Jábínì ọba+ Kénáánì kúrò.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé