Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 3:1-31

3  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà fi sílẹ̀ láti fi wọ́n dán Ísírẹ́lì wò,+ ìyẹn ni, gbogbo àwọn tí kò tíì ní ìrírí èyíkéyìí nínú àwọn ogun Kénáánì;+  ó jẹ́ kìkì nítorí kí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìrírí, kí a bàa lè kọ́ wọn ní ogun, ìyẹn ni, kìkì àwọn tí wọ́n kò tíì ní ìrírí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣáájú ìyẹn:  Àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ márùn-ún+ ti àwọn Filísínì,+ àti gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì,+ àní àwọn ọmọ Sídónì+ àti àwọn Hífì+ tí ń gbé Òkè Ńlá Lẹ́bánónì+ láti Òkè Ńlá Baali-hámónì+ títí dé àtiwọ Hámátì.+  Wọ́n sì ń bá a lọ ní ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti fi dán Ísírẹ́lì wò,+ láti lè mọ̀ bóyá wọn yóò ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà tí ó ti pa láṣẹ fún àwọn baba wọn nípasẹ̀ Mósè.+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,+ àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì àti àwọn Pérísì àti àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya fún ara wọn,+ àwọn ọmọbìnrin tiwọn ni wọ́n sì fi fún àwọn ọmọkùnrin wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn ọlọ́run wọn.+  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ wọ́n sì lọ ń sin àwọn Báálì+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀.+  Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì,+ tí ó fi tà+ wọ́n sí ọwọ́ Kuṣani-ríṣátáímù ọba Mesopotámíà;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti sin Kuṣani-ríṣátáímù fún ọdún mẹ́jọ.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.+ Nígbà náà ni Jèhófà gbé olùgbàlà+ kan, Ótíníẹ́lì+ ọmọkùnrin Kénásì,+ àbúrò Kálébù,+ dìde fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ó lè gbà wọ́n là. 10  Ẹ̀mí+ Jèhófà wá bà lé e, ó sì di onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó jáde lọ sínú ìjà ogun, nígbà náà ni Jèhófà fi Kuṣani-ríṣátáímù ọba Síríà lé e lọ́wọ́, tí ọwọ́ rẹ̀ fi borí+ Kuṣani-ríṣátáímù. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, ilẹ̀ náà kò ní ìyọlẹ́nu fún ogójì ọdún. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ótíníẹ́lì ọmọkùnrin Kénásì kú. 12  Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Látàrí ìyẹn, Jèhófà jẹ́ kí Ẹ́gílónì ọba Móábù+ di alágbára ní ìdojú-ìjà-kọ Ísírẹ́lì,+ nítorí tí wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ 13  Síwájú sí i, ó kó àwọn ọmọ Ámónì+ àti Ámálékì+ jọ láti gbéjà kò wọn. Nígbà náà ni wọ́n lọ, wọ́n sì kọlu Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú ńlá onígi+ ọ̀pẹ. 14  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní sísin Ẹ́gílónì ọba Móábù fún ọdún méjì dínlógún.+ 15  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.+ Nítorí náà, Jèhófà gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, Éhúdù+ ọmọkùnrin Gérà, ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì,+ ọkùnrin alòsì.+ Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi owó òde ránṣẹ́ nípa ọwọ́ rẹ̀ sí Ẹ́gílónì ọba Móábù. 16  Láàárín àkókò yìí, Éhúdù ṣe idà kan fún ara rẹ̀, ó sì ní ojú méjì ,+ gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó wá sán an mọ́ itan+ rẹ̀ ọ̀tún, lábẹ́ aṣọ rẹ̀. 17  Ó sì gbé owó òde náà wá fún Ẹ́gílónì ọba Móábù.+ Wàyí o, Ẹ́gílónì jẹ́ ọkùnrin tí ó sanra gan-an. 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó ti parí gbígbé owó òde náà wá,+ ní kíákíá ó rán àwọn ènìyàn náà lọ, àwọn tí ó ru owó òde náà. 19  Òun fúnra rẹ̀ sì yí padà ní àwọn ibi ìfọ́-òkúta tí ó wà ní Gílígálì,+ ó sì wí pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí kan láti bá ọ sọ, ìwọ ọba.” Nítorí náà, ó wí pé: “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́!” Látàrí èyí, gbogbo àwọn tí ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 20  Éhúdù sì tọ̀ ọ́ wá bí ó ti jókòó sí ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ títutù tí ó jẹ́ ti òun nìkan. Éhúdù sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo fẹ́ bá ọ sọ.” Látàrí ìyẹn, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀. 21  Nígbà náà ni Éhúdù ti ọwọ́ òsì rẹ̀ bọnú aṣọ, ó sì yọ idà náà kúrò ní itan rẹ̀ ọ̀tún, ó sì tì í bọ ikùn rẹ̀. 22  Èèkù rẹ̀ pẹ̀lú sì ń wọlé tẹ̀ lé abẹ idà náà lọ tí ó fi jẹ́ pé ọ̀rá bo abẹ idà náà, nítorí tí kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn rẹ̀, ìgbẹ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá. 23  Éhúdù sì gba ti ihò afẹ́fẹ́ jáde lọ, ṣùgbọ́n ó pa àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé dé nígbà tí ó jáde, ó sì tì wọ́n pa. 24  Òun alára sì jáde lọ.+ Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wò, àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé ni ìwọ̀nyí tí a sì tì pa. Nítorí náà, wọ́n wí pé: “Ó kàn ń gbọnsẹ̀+ ni nínú yàrá títutù inú lọ́hùn-ún.” 25  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní dídúró títí ìtìjú fi bá wọn, sì wò ó! kò sí ẹnì kankan tí ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé. Látàrí èyí, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí wọn, sì wò ó! olúwa wọ́n ti ṣubú sí ilẹ̀ ní òkú! 26  Ní ti Éhúdù, ó sa lọ nígbà tí wọ́n ń dúró, òun fúnra rẹ̀ sì kọjá gba ti àwọn ibi ìfọ́-òkúta,+ ó sì sá àsálà lọ sí Séírà. 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti inú àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, ó sì wà ní iwájú wọn. 28  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀ lé mi,+ nítorí tí Jèhófà ti fi àwọn ọ̀tá yín, àwọn ọmọ Móábù, lé yín lọ́wọ́.”+ Wọ́n sì ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì gba ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò+ Jọ́dánì mọ́ àwọn ọmọ Móábù lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ré kọjá. 29  Àkókò yẹn sì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Móábù balẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin,+ tí gbogbo wọn sanra bọ̀kíbọ̀kí,+ gbogbo wọn sì jẹ́ akíkanjú ọkùnrin; kò sì sí ẹyọ kan tí ó sá àsálà.+ 30  A sì wá tẹ Móábù lórí ba ní ọjọ́ yẹn lábẹ́ ọwọ́ Ísírẹ́lì; ilẹ̀ náà kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan mọ́ fún ọgọ́rin ọdún.+ 31  Lẹ́yìn rẹ̀, Ṣámúgárì+ ọmọkùnrin Ánátì sì wà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn Filísínì+ balẹ̀, ẹgbẹ̀ta ọkùnrin, pẹ̀lú ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù; òun náà sì gba Ísírẹ́lì là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé