Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 21:1-25

21  Wàyí o, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà+ pé: “Ọkùnrin kankan lára wa kì yóò fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún Bẹ́ńjámínì ṣe aya.”+  Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà wá sí Bẹ́tẹ́lì,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní jíjókòó síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run tòótọ́+ títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ń bá a lọ ní gbígbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì jọ̀wọ́ ara wọn fún ẹkún sísun lọ́pọ̀lọpọ̀.+  Wọn a sì wí pé: “Èé ṣe, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì, tí ẹ̀yà kan yóò fi di àwátì lónìí ní Ísírẹ́lì?”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì  pé àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí dìde ní kùtùkùtù, wọ́n sì mọ pẹpẹ kan níbẹ̀, wọ́n sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀.+  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé: “Ta ni nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò gòkè wá nínú ìjọ sọ́dọ̀ Jèhófà, nítorí pé ìbúra+ ńlá ti wáyé ní ti ẹni tí kò gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà, pé, ‘Kí a fi ikú pa á láìkùnà.’”+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́dùn nítorí Bẹ́ńjámínì arákùnrin wọn. Nítorí náà, wọ́n wí pé: “A ti gé ẹ̀yà kan kúrò ní Ísírẹ́lì lónìí.  Kí ni a ó ṣe sí àwọn tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ti aya, ní èyí tí àwa fúnra wa ti fi Jèhófà búra+ nísinsìnyí láti má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ṣe aya?”+  Wọ́n sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà?”+ Sì  wò ó! kò sí ẹni tí ó wá sínú ibùdó náà láti Jabẹṣi-gílíádì+ sí ìjọ náà.  Nígbà tí a ka àwọn ènìyàn náà, tóò, wò ó! kò sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ láti inú àwọn olùgbé Jabẹṣi-gílíádì. 10  Nítorí náà, àpéjọ náà tẹ̀ síwájú láti rán ẹgbẹ̀rún méjì lá lára àwọn ọkùnrin akíkanjú jù lọ síbẹ̀, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì fi ojú idà kọlu àwọn olùgbé Jabẹṣi-gílíádì, àní àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá.+ 11  Èyí sì ni ohun tí ẹ ó ṣe: Gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí ó ti mọ bí a ti ń sùn ti ọkùnrin ni kí ẹ yà sọ́tọ̀ fún ìparun.”+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n rí irínwó ọ̀dọ́mọbìnrin, wúńdíá,+ nínú àwọn olùgbé Jabẹṣi-gílíádì,+ tí kò tíì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin nípa sísùn ti ọkùnrin. Nítorí náà, wọ́n kó wọn wá sí ibùdó ní Ṣílò,+ èyí tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì. 13  Wàyí o, gbogbo àpéjọ ránṣẹ́, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó wà lórí àpáta gàǹgà Rímónì+ sọ̀rọ̀, wọ́n sì nawọ́ àlàáfíà sí wọn. 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bẹ́ńjámínì padà wá ní ìgbà yẹn. Nígbà náà ni wọ́n fún wọn ní àwọn obìnrin tí wọ́n pa mọ́ láàyè lára àwọn obìnrin Jabẹṣi-gílíádì;+ ṣùgbọ́n wọn kò rí iye tí ó tó fún wọn.+ 15  Àwọn ènìyàn náà sì kẹ́dùn nítorí Bẹ́ńjámínì,+ nítorí pé Jèhófà ti ṣe ìyànípa láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 16  Nítorí náà, àwọn àgbà ọkùnrin àpéjọ náà wí pé: “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ti aya, nítorí tí a ti pa ẹ̀dá obìnrin rẹ́ ráúráú ní Bẹ́ńjámínì?” 17  Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Ohun ìní ní láti wà fún àwọn tí ó sá àsálà ní Bẹ́ńjámínì,+ kí a má bàa nu ẹ̀yà kan kúrò ní Ísírẹ́lì. 18  Ní tiwa, a kò yọ̀ǹda fún wa láti fún wọn ní aya láti inú àwọn ọmọbìnrin wa, nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti búra pé, ‘Ègún ni fún ẹni tí ó bá fún Bẹ́ńjámínì ní aya.’”+ 19  Níkẹyìn, wọ́n wí pé: “Wò ó! Àjọyọ̀ Jèhófà wà láti ọdún dé ọdún ní Ṣílò,+ èyí tí ó wà ní àríwá Bẹ́tẹ́lì, síhà ìlà-oòrùn òpópó tí ó gòkè lọ láti Bẹ́tẹ́lì sí Ṣékémù+ àti síhà gúúsù Lẹ́bónà.” 20  Nítorí náà, wọ́n pàṣẹ fún àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì lúgọ sínú àwọn ọgbà àjàrà. 21  Kí ẹ sì wò, kíyè sí i, nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣílò bá jáde wá láti jó+ ijó àjóyípo, kí ẹ̀yin pẹ̀lú jáde wá láti inú àwọn ọgbà àjàrà, kí olúkúlùkù yín sì fi ipá gbé aya tirẹ̀ lọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ọmọbìnrin Ṣílò, kí ẹ sì lọ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. 22  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí baba wọn tàbí arákùnrin wọn bá wá bá wa ṣe ẹjọ́ òfin, dájúdájú, àwa pẹ̀lú yóò sọ fún wọn pé, ‘Ẹ fi ojú rere hàn sí wa nítorí tiwọn, nítorí pé a kò mú aya olúkúlùkù fún un nípa ogun,+ nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó fi fún wọn, ní ìgbà náà, ẹ̀yin ì bá jẹ̀bi.’”+ 23  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé aya lọ fún iye wọn+ láti inú àwọn obìnrin tí ń jó+ yí ká, àwọn tí wọ́n jágbà lọ; lẹ́yìn èyí tí wọ́n lọ tí wọ́n sì padà sí ogún wọn, wọ́n sì kọ́ àwọn ìlú ńlá náà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú wọn. 24  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ́n ká níbẹ̀ ní ìgbà yẹn, olúkúlùkù sí ẹ̀yà tirẹ̀ àti ìdílé tirẹ̀; wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níbẹ̀, olúkúlùkù sí ogún tirẹ̀.+ 25  Kò sí ọba ní Ísírẹ́lì ní ọjọ́ wọnnì.+ Ohun tí ó tọ̀nà ní ojú tirẹ̀ ni ó ti mọ́ olúkúlùkù lára láti máa ṣe.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé