Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 20:1-48

20  Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ,+ àpéjọ náà sì pe ara wọn jọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo,+ láti Dánì+ títí lọ dé Bíá-ṣébà+ pa pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gílíádì,+ sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà.+  Nítorí náà, àwọn gíríkì ọkùnrin nínú gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì mú ìdúró wọn nínú ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin afẹsẹ̀rìn tí ń fa idà yọ.+  Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì wá gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gòkè lọ sí Mísípà.+ Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé: “Ẹ sọ̀rọ̀. Báwo ni ohun búburú yìí ṣe ṣẹlẹ̀?”+  Látàrí èyí, ọkùnrin náà, ọmọ Léfì,+ ọkọ obìnrin tí a ṣìkà pa náà dáhùn, ó sì wí pé: “Gíbíà,+ tí ó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì, ni mo wá, èmi àti wáhàrì mi,+ láti sùn mọ́jú.  Àwọn onílẹ̀ Gíbíà sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí mi, wọ́n sì yí ilé ká mọ́ mi ní òru. Èmi ni wọ́n gbèrò láti pa, ṣùgbọ́n wáhàrì mi ni wọ́n fipá bá lò pọ̀,+ ó sì kú ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.+  Nítorí náà, mo mú wáhàrì mi, mo gé e sí wẹ́wẹ́, mo sì fi í ránṣẹ́ sí gbogbo pápá ogún Ísírẹ́lì,+ nítorí pé wọ́n ti hu ìwà àìníjàánu+ àti ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini ní Ísírẹ́lì.+  Wò ó! Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ fúnni ní ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ràn+ yín níhìn-ín.”  Nítorí náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà dìde gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo,+ wọ́n wí pé: “Èyíkéyìí nínú wa kì yóò lọ sínú àgọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èyíkéyìí nínú wa kì yóò yà sí ilé rẹ̀.+  Wàyí o, ohun tí a ó ṣe sí Gíbíà nìyí. [Ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ] gbéjà kò ó nípa kèké.+ 10  Àwa yóò sì mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àti ọgọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ̀rún, àti ẹgbẹ̀rún nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, láti wá àwọn ìpèsè oúnjẹ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n lè gbé ìgbésẹ̀ nípa lílọ gbéjà ko Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, lójú ìwòye gbogbo ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini+ tí wọ́n hù ní Ísírẹ́lì.” 11  Bí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣe kó jọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo, gẹ́gẹ́ bí alájọṣepọ̀, láti gbéjà ko ìlú ńlá náà nìyẹn. 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo àwọn ọkùnrin ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì+ pé: “Irú ohun búburú wo ni èyí tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín yín?+ 13  Wàyí o, ẹ fi àwọn ọkùnrin náà lé wa lọ́wọ́,+ àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun,+ tí ó wà ní Gíbíà,+ kí a lè fi ikú pa wọ́n,+ kí a sì mú ohun tí ó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.”+ Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kò sì fẹ́ fetí sí ohùn àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 14  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọpọ̀ láti inú àwọn ìlú ńlá Gíbíà, láti jáde lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ja ìjà ogun. 15  Nítorí náà, a pe àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jọ ní ọjọ́ náà láti àwọn ìlú ńlá, ẹgbàá mẹ́tàlá ọkùnrin tí ń fa idà yọ,+ yàtọ̀ sí àwọn olùgbé Gíbíà, nínú èyí tí a ti pe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin jọ. 16  Nínú gbogbo àwọn ènìyàn yìí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin ń bẹ tí ó jẹ́ alòsì.+ Olúkúlùkù àwọn wọ̀nyí jẹ́ olùfi kànnàkànnà gbọn òkúta+ ba ìbú fọ́nrán irun tí kò sì ní tàsé. 17  A sì pe àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ yàtọ̀ sí Bẹ́ńjámínì, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin tí ń fa idà yọ.+ Olúkúlùkù àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọkùnrin ogun. 18  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde, wọ́n sì gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé: “Ta ni nínú wa ni kí ó ṣáájú ní gígòkè lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ja ìjà ogun?”+ Jèhófà fèsì pé: “Kí Júdà ṣáájú.”+ 19  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìde ní òwúrọ̀, wọ́n sì dó ti Gíbíà. 20  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde lọ wàyí láti bá Bẹ́ńjámínì ja ìjà ogun; àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ìtẹ́gun lòdì sí wọn ní Gíbíà. 21  Nítorí náà, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jáde wá láti inú Gíbíà,+ wọ́n sì run ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá ọkùnrin nínú Ísírẹ́lì sórí ilẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.+ 22  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, fi ara wọn hàn ní onígboyà, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ìtẹ́gun ní ibi tí wọ́n tẹ́ ìtẹ́gun sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. 23  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè lọ, wọ́n sì sunkún+ níwájú Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé kí n tún tọ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi lọ fún ìjà ogun?”+ Jèhófà fèsì pé: “Gòkè lọ gbéjà kò ó.” 24  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì .+ 25  Ẹ̀wẹ̀, Bẹ́ńjámínì jáde wá láti inú Gíbíà láti pàdé wọn ní ọjọ́ kejì , wọ́n sì run ẹgbàásàn-án ọkùnrin síwájú sí i lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sórí ilẹ̀,+ gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ń fa idà yọ.+ 26  Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ àní gbogbo àwọn ènìyàn náà, gòkè lọ, wọ́n sì wá sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì sunkún,+ wọ́n sì jókòó níbẹ̀ níwájú Jèhófà, wọ́n sì gbààwẹ̀+ ní ọjọ́ yẹn títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀+ níwájú Jèhófà. 27  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ibẹ̀ ni àpótí májẹ̀mú+ Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọjọ́ wọnnì. 28  Wàyí o, Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì, ọmọkùnrin Áárónì, dúró níwájú rẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì,+ ó wí pé: “Ṣé kí n ṣì tún jáde lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi ja ìjà ogun tàbí kí n dáwọ́ dúró?”+ Jèhófà fèsì pé: “Gòkè lọ, nítorí pé lọ́la, èmi yóò fi í lé ọ lọ́wọ́.”+ 29  Nígbà náà ni Ísírẹ́lì fi àwọn ènìyàn sí ibùba+ yí ká Gíbíà. 30  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti gòkè lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun lòdì sí Gíbíà bí ti àtẹ̀yìnwá.+ 31  Nígbà tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jáde lọ pàdé àwọn ènìyàn náà, a fà wọ́n lọ kúrò ní ìlú ńlá náà.+ Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣá nǹkan bí ọgbọ̀n ọkùnrin nínú Ísírẹ́lì+ balẹ̀ ní pápá, lára àwọn ènìyàn tí ó gbọgbẹ́ lọ́nà tí wọ́n lè fi kú ní àwọn òpópó, èyí tí ọ̀kan nínú rẹ̀ gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì+ tí èkejì sì lọ sí Gíbíà.+ 32  Nítorí náà, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “A ti ń ṣẹ́gun wọn níwájú wa bí ti ìgbà àkọ́kọ́.”+ Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a sá lọ,+ dájúdájú, àwa yóò sì fà wọ́n lọ kúrò nínú ìlú ńlá sí àwọn òpópó.” 33  Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì dìde láti ipò wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ìtẹ́gun ní Baali-támárì, nígbà tí àwọn tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì tí ó wà ní ibùba+ ń ṣe ìgbóguntini láti ipò wọn ní tòsí Gíbíà.+ 34  Bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àṣàyàn ọkùnrin nínú gbogbo Ísírẹ́lì ṣe wá sí iwájú Gíbíà nìyẹn, ìjà náà sì le kú; àwọn ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì kò sì mọ̀ pé ìyọnu àjálù+ rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí wọn. 35  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì+ níwájú Ísírẹ́lì, tí ó fi jẹ́ pé ní ọjọ́ yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run ẹgbàá méjì lá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ọkùnrin ní Bẹ́ńjámínì, gbogbo àwọn wọ̀nyí ń fa idà yọ.+ 36  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì lérò pé àwọn ti fẹ́ ṣẹ́gun àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń bì ṣẹ́yìn+ ṣáá fún Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ibùba tí wọ́n dẹ de Gíbíà. 37  Ní ti àwọn abadeni náà, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kíákíá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ gììrì sí Gíbíà.+ Nígbà náà ni àwọn abadeni+ náà tàn kálẹ̀, wọ́n sì fi ojú idà kọlu gbogbo ìlú ńlá náà.+ 38  Wàyí o, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti ní ìṣètò pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní ibùba pé kí wọ́n mú kí èéfín àmì àfiyèsí gòkè lọ láti inú ìlú ńlá náà.+ 39  Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yíjú padà nínú ìjà ogun náà, Bẹ́ńjámínì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá nǹkan bí ọgbọ̀n ọkùnrin balẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì+ tí wọ́n gbọgbẹ́ lọ́nà tí wọ́n lè fi kú, nítorí tí wọ́n wí pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n a ń ṣẹ́gun wọ́n níwájú wa gan-an gẹ́gẹ́ bí ti ìjà ogun àkọ́kọ́.”+ 40  Àmì àfiyèsí+ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ láti inú ìlú ńlá náà gẹ́gẹ́ bí ọwọ̀n èéfín.+ Nítorí náà, nígbà tí Bẹ́ńjámínì yí ojú rẹ̀ padà, wò ó! gbogbo ìlú ńlá náà lọ sókè síhà ọ̀run.+ 41  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yíjú padà,+ ìyọlẹ́nu sì bá àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì,+ nítorí tí wọ́n rí i pé ìyọnu àjálù ti dé bá wọ́n.+ 42  Nítorí náà, wọ́n yí padà níwájú àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sí ìhà aginjù, ìjà ogun náà sì tẹ̀ lé wọn pẹ́kípẹ́kí, bí àwọn ọkùnrin láti inú àwọn ìlú ńlá náà ti ń run wọ́n ní àárín wọn. 43  Wọ́n yí Bẹ́ńjámínì ká.+ Wọ́n lépa rẹ̀ láìsí ibi ìsinmi kankan.+ Wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní tààràtà ní iwájú Gíbíà,+ níhà yíyọ oòrùn. 44  Níkẹyìn, ẹgbàásàn-án ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ni ó ṣubú, gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ akíkanjú ọkùnrin.+ 45  Bí wọ́n ṣe yí padà nìyẹn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí aginjù sórí àpáta gàǹgà Rímónì.+ Wọ́n sì pèéṣẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin lára wọn ní àwọn òpópó,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní títẹ̀lé wọn pẹ́kípẹ́kí títí dé Gídómù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣá ẹgbàá ọkùnrin sí i balẹ̀ lára wọn. 46  Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì, tí ó ṣubú ní ọjọ́ yẹn nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí ń fa idà yọ,+ gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ akíkanjú ọkùnrin. 47  Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta ọkùnrin yí padà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí aginjù, sórí àpáta gàǹgà Rímónì, wọ́n sì ń bá a lọ ní gbígbé lórí àpáta gàǹgà Rímónì+ fún oṣù mẹ́rin. 48  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà wá gbéjà ko àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlu àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá, láti orí ènìyàn dé orí ẹran agbéléjẹ̀ títí dé orí ohun gbogbo tí wọ́n rí.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ìlú ńlá tí wọ́n rí ni wọ́n gbé lé iná lọ́wọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé