Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 2:1-23

2  Nígbà náà ni áńgẹ́lì+ Jèhófà gòkè lọ láti Gílígálì+ sí Bókímù,+ ó sì wí pé: “Mo tẹ̀ síwájú láti mú yín gòkè wá láti Íjíbítì, mo sì mú yín wá sínú ilẹ̀ náà nípa èyí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín.+ Síwájú sí i, mo wí pé, ‘Èmi kì yóò ba májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín jẹ́ láé.+  Àti ní tiyín, ẹ kò gbọ́dọ̀ bá àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí dá májẹ̀mú.+ Pẹpẹ wọn ni kí ẹ bì wó.’+ Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sí ohùn mi.+ Èé ṣe tí ẹ fi ṣe èyí?+  Nítorí náà, èmi, ẹ̀wẹ̀, ti wí pé, ‘Èmi kì yóò lé wọn kúrò níwájú yín, wọn yóò sì di ìdẹkùn fún yín,+ àwọn ọlọ́run wọn yóò sì jẹ́ ohun adẹnilọ fún yín.’”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí áńgẹ́lì Jèhófà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún.+  Nípa báyìí, wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Bókímù. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀.  Nígbà tí Jóṣúà rán àwọn ènìyàn náà lọ, nígbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ọ̀nà wọn lọ, olúkúlùkù sí ogún rẹ̀, láti gba ilẹ̀ náà.+  Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbà ọkùnrin tí ọjọ́ wọ́n gùn ré kọjá ti Jóṣúà, tí wọ́n sì ti rí gbogbo iṣẹ́ ńlá Jèhófà tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì.+  Nígbà náà, Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì, ìránṣẹ́ Jèhófà, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún.+  Nítorí náà, wọ́n sin ín sí ìpínlẹ̀ ogún rẹ̀ ní Timunati-hérésì+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, ní àríwá Òkè Ńlá Gááṣì.+ 10  Gbogbo ìran yẹn pẹ̀lú ni a sì kó jọ sọ́dọ̀ àwọn baba wọn,+ ìran mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde lẹ́yìn wọn, tí kò mọ Jèhófà tàbí iṣẹ́ tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì.+ 11  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣubú sínú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n sì ń sin àwọn Báálì.+ 12  Báyìí ni wọ́n pa Jèhófà tì, Ọlọ́run àwọn baba wọn, tí ó mú wọn jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n sì lọ ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti inú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn náà tí ó yí wọn ká,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún wọn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi mú Jèhófà bínú.+ 13  Báyìí ni wọ́n pa Jèhófà tì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì.+ 14  Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì,+ tí ó fi fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn akóni-ní-ìkógun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ní ìkógun;+ ó sì tẹ̀ síwájú láti tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn yíká-yíká,+ wọn kò sì tún lè dúró mọ́ níwájú àwọn ọ̀tá wọn.+ 15  Níbi gbogbo tí wọ́n bá jáde lọ, ọwọ́ Jèhófà a sì wà lára wọn fún ìyọnu àjálù,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ àti gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe búra fún wọn;+ wọ́n sì wá wà nínú hílàhílo gidigidi.+ 16  Nítorí náà, Jèhófà a sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde,+ wọn a sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ń kó wọn ní ìkógun.+ 17  Àní àwọn onídàájọ́ wọn pàápàá ni wọn kò fetí sí, ṣùgbọ́n wọ́n ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe+ pẹ̀lú àwọn ọlọ́run mìíràn,+ wọ́n sì lọ ń tẹrí ba fún wọn. Wọ́n yà kíákíá kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba ńlá wọn rìn nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà.+ Wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. 18  Nígbà tí Jèhófà bá sì gbé àwọn onídàájọ́+ dìde fún wọn, Jèhófà a sì wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n là ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àwọn ọjọ́ onídàájọ́ náà; nítorí Jèhófà a máa kẹ́dùn+ nítorí ìkérora wọn nítorí àwọn tí ń ni wọ́n lára+ àti àwọn tí ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kiri. 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí onídàájọ́ náà bá kú, wọn a yíjú padà, wọn a sì gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun ju ti àwọn baba wọn nípa títọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n àti láti tẹrí ba fún wọn.+ Wọn kò fà sẹ́yìn nínú ìṣe wọn àti ìwà agídí wọn.+ 20  Níkẹyìn, ìbínú Jèhófà ru+ sí Ísírẹ́lì, ó sì wí pé: “Nítorí ìdí náà pé orílẹ̀-èdè yìí ti tẹ májẹ̀mú mi tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wọn lójú,+ tí wọn kò sì fetí sí ohùn mi,+ 21  èmi pẹ̀lú, ní tèmi, kì yóò tún lé ẹyọ kan jáde kúrò níwájú wọn mọ́ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí Jóṣúà fi sílẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí ó kú,+ 22  láti lè fi wọ́n dán Ísírẹ́lì wò,+ bóyá wọn yóò jẹ́ olùpa ọ̀nà Jèhófà mọ́ nípa rírìn nínú rẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ti pa á mọ́, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.” 23  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fi orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sílẹ̀ nípa ṣíṣàìlé wọn jáde kíákíá,+ kò sì fi wọ́n lé Jóṣúà lọ́wọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé