Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 19:1-30

19  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ọmọ Léfì kan ń gbé fún ìgbà díẹ̀ ní àwọn apá ibi jíjì nnàréré jù lọ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù.+ Nígbà tí ó ṣe, ó fẹ́ wáhàrì+ kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà ṣe aya.  Wáhàrì rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgbèrè+ sí i. Níkẹyìn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ó sì ń bá a lọ ní wíwà níbẹ̀ fún oṣù mẹ́rin gbáko.  Nígbà náà ni ọkọ rẹ̀ dìde, ó sì tọ̀ ọ́ lọ láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un láti lè mú un padà wá; ẹmẹ̀wà+ rẹ̀ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, ó mú kí ó wá sí ilé baba rẹ̀. Nígbà tí baba ọ̀dọ́bìnrin náà rí i, kíákíá ni ó yọ̀ pàdé rẹ̀.  Nítorí náà, baba ìyàwó rẹ̀, baba ọ̀dọ́bìnrin náà, mú un, tí ó fi ń bá a lọ ní gbígbé pẹ̀lú rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta; wọn a sì jẹ, wọn a sì mu, òun a sì sun ibẹ̀ mọ́jú.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin, nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ti tẹ́lẹ̀ rí, ó dìde láti lọ wàyí, ṣùgbọ́n baba ọ̀dọ́bìnrin náà wí fún ọkọ ọmọ rẹ̀ pé: “Fi oúnjẹ díẹ̀ gbé ọkàn-àyà rẹ ró,+ lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ lè máa lọ.”  Nítorí náà, wọ́n jókòó, àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì ń mu pa pọ̀; lẹ́yìn èyí tí baba ọ̀dọ́bìnrin náà wí fún ọkùnrin náà pé: “Dákun, jọ̀wọ́, sùn mọ́jú,+ kí o sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ̀gbádùn.”+  Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti lọ, baba ìyàwó rẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá, tí ó fi tún sun ibẹ̀ mọ́jú.+  Nígbà tí ó dìde láti lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ karùn-ún, nígbà náà ni baba ọ̀dọ́bìnrin náà wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, jẹ ohun ìgbẹ́mìíró fún ọkàn-àyà rẹ.”+ Wọ́n sì dúró títí di ìpofírí ọjọ́. Àwọn méjèèjì sì ń bá a nìṣó ní jíjẹun.  Ọkùnrin náà+ dìde láti lọ wàyí, òun àti wáhàrì+ rẹ̀ àti ẹmẹ̀wà rẹ̀;+ ṣùgbọ́n baba ìyàwó rẹ̀, baba ọ̀dọ́bìnrin náà, wí fún un pé: “Wàyí o, wò ó! Ọjọ́ ti rọ̀, ó ti di ọwọ́ alẹ́. Jọ̀wọ́, ẹ sùn mọ́jú.+ Kíyè sí i ọjọ́ ń re ibi àná. Sun ìhín mọ́jú, kí o sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ̀gbádùn.+ Ní ọ̀la kí ẹ sì dìde ní kùtùkùtù fún ìrìn àjò yín, kí o sì lọ sí àgọ́ rẹ.” 10  Bí ó ti wù kí ó rí, ọkùnrin náà kò gbà láti sùn mọ́jú, ṣùgbọ́n ó dìde, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó sì lọ títí dé iwájú Jébúsì,+ èyíinì ni, Jerúsálẹ́mù;+ àwọn akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a dì ní gàárì, àti wáhàrì rẹ̀ àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 11  Nígbà tí wọ́n sún mọ́ tòsí Jébúsì, bí ojúmọmọ ti lọ tán,+ wàyí o, ẹmẹ̀wà náà wí fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Wá, nísinsìnyí, sì jẹ́ kí a yà sí ìlú ńlá yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jébúsì+ kí a sì sun ibẹ̀ mọ́jú.” 12  Ṣùgbọ́n ọ̀gá rẹ̀ wí fún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí a yà sí ìlú ńlá àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; a sì ní láti kọjá lọ títí dé Gíbíà.”+ 13  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Wá, sì jẹ́ kí a sún mọ́ ọ̀kan lára ibí wọ̀nyí, kí a sì sùn mọ́jú bóyá ní Gíbíà tàbí ní Rámà.”+ 14  Nítorí náà, wọ́n kọjá lọ, wọ́n sì ń bá ọ̀nà wọn nìṣó, oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀ bá wọn nígbà tí wọ́n sún mọ́ Gíbíà, èyí tí ó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì. 15  Nítorí náà, wọ́n yà síbẹ̀ láti wọlé lọ sun Gíbíà mọ́jú. Wọ́n sì wọlé, wọ́n sì jókòó sí ojúde ìlú ńlá náà, kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó gbà wọ́n sínú ilé láti sùn mọ́jú.+ 16  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wò ó! ọkùnrin arúgbó kan ń wọlé bọ̀ ní alẹ́+ láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ ní pápá, ọkùnrin náà sì wá láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ ó sì ń gbé fún ìgbà díẹ̀ ní Gíbíà; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ibẹ̀ jẹ́ ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì.+ 17  Nígbà tí ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó rí ọkùnrin náà, arìnrìn-àjò náà, ní ojúde ìlú ńlá náà. Nítorí náà, ọkùnrin arúgbó náà sọ pé: “Ibo ni o ń lọ, ibo sì ni o ti wá?”+ 18  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún un pé: “A ń kọjá lọ láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà sí àwọn apá ibi jíjì nnàréré jù lọ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù.+ Ibi tí mo ti wá nìyẹn, ṣùgbọ́n mo lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà;+ ilé mi sì ni mo ń lọ, kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó gbà mí sínú ilé.+ 19  Èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran+ sì wà fún àwọn akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa, oúnjẹ+ àti wáìnì sì wà fún èmi àti ẹrúbìnrin+ rẹ àti fún ẹmẹ̀wà+ tí ó wà pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ. Kò sí àìní ẹyọ ohun kan.” 20  Bí ó ti wù kí ó rí, ọkùnrin arúgbó náà wí pé: “Àlàáfíà fún ọ!+ Sáà jẹ́ kí àìní rẹ èyíkéyìí wà lórí mi.+ Kì kì pé kí o má sun ojúde ìlú mọ́jú.” 21  Pẹ̀lú ìyẹn, ó mú un wá sínú ilé rẹ̀,+ ó sì da àdàpọ̀ oúnjẹ sí àwọn akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.+ Nígbà náà ni wọ́n wẹ ẹsẹ̀ wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì ń mu. 22  Bí wọ́n ti ń mú kí ọkàn-àyà wọn jẹ̀gbádùn,+ wò ó! àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà, àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun+ rárá, yí ilé náà ká,+ wọ́n ń taari ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì lu ilẹ̀kùn; wọ́n sì ń wí ṣáá fún ọkùnrin arúgbó, tí ó ni ilé náà pé: “Mú ọkùnrin tí ó wá sínú ilé rẹ jáde, kí a lè ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”+ 23  Látàrí ìyẹn, ẹni tí ó ni ilé náà jáde lọ bá wọn, ó sì wí fún wọn pé:+ “Rárá, ẹ̀yin arákùnrin mi,+ ẹ má ṣe ohun àìtọ́ kankan, ẹ jọ̀wọ́, níwọ̀n bí ọkùnrin yìí ti wá sínú ilé mi. Ẹ má hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini yìí.+ 24  Ọmọbìnrin mi, wúńdíá, àti wáhàrì ọkùnrin náà wà níbí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde wá, kí ẹ sì fipá bá wọn lò pọ̀,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú yín sí wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ má ṣe ohun òmùgọ̀, tí ń dójú tini yìí sí.” 25  Àwọn ọkùnrin náà kò sì fẹ́ fetí sí i. Nítorí náà, ọkùnrin náà di wáhàrì rẹ̀ mú,+ ó sì mú un jáde tọ̀ wọ́n wá ní òde; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní lílò ó ní ìlòkúlò+ láti òru mọ́jú títí di òwúrọ̀, lẹ́yìn èyí tí wọ́n rán an lọ nígbà tí ọ̀yẹ̀ là. 26  Nígbà náà ni obìnrin náà dé bí ó ti ń di òwúrọ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà ilé ọkùnrin náà níbi tí ọ̀gá rẹ̀ wà,+—títí di ojúmọmọ. 27  Lẹ́yìn náà, ọ̀gá rẹ̀ dìde ní òwúrọ̀, ó sì ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé, ó sì jáde lọ láti mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, sì wò ó! obìnrin náà, wáhàrì rẹ̀,+ ṣubú sí ẹnu ọ̀nà ilé náà pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lórí ibi àtiwọlé! 28  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Dìde, jẹ́ kí a lọ.” Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó dáhùn.+ Látàrí ìyẹn, ọkùnrin náà gbé e sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dìde lọ sí ipò rẹ̀.+ 29  Nígbà náà ni ó wọ ilé rẹ̀, ó sì mú ọ̀bẹ ìpẹran, ó sì di wáhàrì rẹ̀ mú, ó sì gé e ní ìbámu pẹ̀lú egungun rẹ̀ sí ègé méjì lá,+ ó sì fi í ránṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 30  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbogbo ènìyàn tí ó rí i, wí pé: “Irú ohun kan bí èyí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí tàbí kí a rí i rí láti ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gòkè lọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní yìí. Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí i, ẹ gbìmọ̀+ kí ẹ sì sọ̀rọ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé