Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 18:1-31

18  Kò sí ọba ní Ísírẹ́lì ní ọjọ́ wọnnì.+ Ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì+ sì ń wá ogún fún ara rẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì láti máa gbé níbẹ̀; nítorí pé títí di ọjọ́ yẹn, ogún kò tíì bọ́ sọ́wọ́ wọn láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ọmọ Dánì rán ọkùnrin márùn-ún lára ìdílé wọn, àwọn ọkùnrin láti àárín wọn, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ akíkanjú, jáde láti Sórà+ àti Éṣítáólì,+ láti ṣe amí+ ilẹ̀ náà àti láti yẹ̀ ẹ́ wò. Nítorí náà, wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.” Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù+ títí dé ilé Míkà,+ wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú.  Nígbà tí wọ́n sún mọ́ tòsí ilé Míkà, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́kùnrin náà, ọmọ Léfì mọ̀, wọ́n sì yà síbẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Ta ní mú ọ wá síhìn-ín, kí sì ni ohun tí o ń ṣe níbí, kí sì ni o lọ́kàn-ìfẹ́ sí níhìn-ín?”  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Báyìí báyìí ni Míkà ṣe fún mi kí ó lè háyà mi,+ àti pé kí n lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà+ fún un.”  Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, wádìí+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run+ kí a lè mọ̀ bóyá ọ̀nà wa tí àwa ń lọ yóò yọrí sí rere.”  Nítorí náà, àlùfáà náà wí fún wọn pé: “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Iwájú Jèhófà ni ọ̀nà yín tí ẹ̀yin ń lọ wà.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tẹ̀ síwájú, wọ́n sì dé Láíṣì,+ wọ́n sì rí bí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú rẹ̀ ti ń gbé lọ́nà ìgbẹ́kẹ̀lé ara-ẹni gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ọmọ Sídónì, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti láìfura,+ kò sì sí aṣẹ́gun tí ń nini lára tí ń fìtínà ohunkóhun ní ilẹ̀ náà, bí wọ́n ti wà ní ibi jíjì nnàréré sí àwọn ọmọ Sídónì,+ wọn kò sì ní nǹkan kan láti ṣe pẹ̀lú aráyé.  Níkẹyìn wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Sórà+ àti Éṣítáólì,+ àwọn arákùnrin wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Báwo ni ẹ ti rí i sí?”  Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ gbéjà kò wọ́n; nítorí tí a ti rí ilẹ̀ náà, wò ó! ó dára gidigidi.+ Ẹ sì ń lọ́ tìkọ̀. Ẹ má ṣe lọ́ra nípa rírìn wọlé wá láti gba ilẹ̀ náà.+ 10  Nígbà tí ẹ bá wọlé wá, ẹ̀yin yóò wá bá àwọn ènìyàn tí ó wà láìfura,+ ilẹ̀ náà sì gbòòrò díẹ̀; nítorí tí Ọlọ́run ti fi í lé yín lọ́wọ́,+ ibì kan tí kò ṣe aláìní ohunkóhun tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.”+ 11  Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí a fi àwọn ohun ìjà ogun dì lámùrè, láti inú ìdílé àwọn ọmọ Dánì,+ gbéra lọ láti ibẹ̀, èyíinì ni, láti Sórà àti Éṣítáólì.+ 12  Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n gòkè lọ, wọ́n sì lọ dó sí Kiriati-jéárímù+ ní Júdà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Mahane-dánì+ títí di òní yìí. Wò ó! Ó wà ní ìwọ̀-oòrùn Kiriati-jéárímù. 13  Lẹ́yìn náà, wọ́n kọjá lọ láti ibẹ̀ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, wọ́n sì lọ títí dé ilé Míkà.+ 14  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tí ó lọ ṣe amí+ ilẹ̀ Láíṣì+ dáhùn, wọ́n sì wí fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé éfódì àti ère tẹ́ráfímù+ àti ère gbígbẹ́+ àti ère dídà+ wà nínú ilé wọ̀nyí? Wàyí o, ẹ ní ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe lọ́kàn.”+ 15  Nítorí náà, wọ́n yà síbẹ̀, wọ́n sì wá sí ilé ọ̀dọ́kùnrin náà, ọmọ Léfì,+ ní ilé Míkà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè nípa bí ó ti ń ṣe sí.+ 16  Ní gbogbo àkókò náà, ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí a fi àwọn ohun ìjà ogun+ wọn dì lámùrè, tí wọ́n jẹ́ ara àwọn ọmọ Dánì,+ dúró sí ibi àbáwọ ẹnubodè. 17  Àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tí ó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà+ gòkè lọ wàyí, kí wọ́n lè wọ ibẹ̀ láti kó ère gbígbẹ́+ àti éfódì+ àti ère tẹ́ráfímù+ àti ère dídà náà.+ (Àlùfáà náà+ sì dúró sí ibi àbáwọ ẹnubodè pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọkùnrin náà tí a fi àwọn ohun ìjà ogun dì lámùrè.) 18  Àwọn wọ̀nyí sì wọnú ilé Míkà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ère gbígbẹ́ náà, éfódì àti ère tẹ́ráfímù àti ère dídà náà.+ Látàrí ìyẹn, àlùfáà náà+ wí fún wọn pé: “Kí ni ẹ ń ṣe yìí?” 19  Ṣùgbọ́n wọ́n wí fún un pé: “Dákẹ́. Fi ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ, kí o sì bá wa lọ, kí o sì di baba+ àti àlùfáà+ fún wa. Èwo ni ó sàn jù, pé kí o máa bá a lọ bí àlùfáà fún ilé ọkùnrin kan+ tàbí kí o di àlùfáà fún ẹ̀yà àti ìdílé kan ní Ísírẹ́lì?”+ 20  Látàrí èyí, ó dùn mọ́ ọkàn-àyà àlùfáà náà,+ ó sì kó éfódì àti ère tẹ́ráfímù àti ère gbígbẹ́+ náà wàyí, ó sì wá sí àárín àwọn ènìyàn náà. 21  Nígbà náà ni wọ́n yí padà, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n sì fi àwọn ọmọ kéékèèké àti ohun ọ̀sìn àti àwọn ohun tí ó níye lórí ṣáájú wọn.+ 22  Àwọn fúnra wọn ti rìn jì nnà díẹ̀ sí ilé Míkà nígbà tí àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà ní àwọn ilé tí ó wà nítòsí ilé Míkà+ péjọ, tí wọ́n sì gbìyànjú láti lé àwọn ọmọ Dánì bá. 23  Nígbà tí wọ́n ń ké jáde sí àwọn ọmọ Dánì ṣáá, nígbà náà ni wọ́n yíjú padà, wọ́n sì wí fún Míkà pé: “Kí ní ṣe yín+ tí ẹ fi péjọ?” 24  Nítorí náà, ó wí pé: “Àwọn ọlọ́run mi+ tí mo ṣe+ ni ẹ ti kó, àlùfáà+ náà pẹ̀lú, ẹ sì bá ọ̀nà yín lọ, kí sì ni mo tún ní?+ Báwo wá ni ẹ ṣe lè sọ fún mi pé, ‘Kí ní ṣe ọ́?’” 25  Látàrí èyí, àwọn ọmọ Dánì wí fún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí a gbọ́ ohùn rẹ ní etí ọ̀dọ̀ wa, kí àwọn ọkùnrin tí ó ní ìkorò+ ọkàn má bàa fipá kọlù yín, tí ẹ ó sì pàdánù ọkàn tiyín àti ọkàn agbo ilé yín dájúdájú.” 26  Àwọn ọmọ Dánì sì ń bá ọ̀nà wọn lọ; Míkà sì wá rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ,+ nípa báyìí, ó yí padà, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀. 27  Ní tiwọn, wọ́n kó ohun tí Míkà ṣe àti àlùfáà+ tí ó di tirẹ̀, wọ́n sì ń lọ síhà Láíṣì,+ láti gbéjà ko àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà láìfura.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlù wọ́n,+ ìlú ńlá náà ni wọ́n sì fi iná sun.+ 28  Kò sì sí olùdáǹdè, nítorí tí ó jì nnàréré sí Sídónì,+ wọn kò sì ní nǹkan kan láti ṣe rárá pẹ̀lú aráyé; ó sì wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ tí ó jẹ́ ti Bẹti-réhóbù.+ Nígbà náà ni wọ́n kọ́ ìlú ńlá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀.+ 29  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n pe orúkọ ìlú ńlá náà ní Dánì nípa orúkọ baba wọn, Dánì,+ tí a bí fún Ísírẹ́lì.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Láíṣì ni orúkọ ìlú ńlá náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá.+ 30  Lẹ́yìn èyíinì, àwọn ọmọ Dánì gbé ère gbígbẹ́+ náà nà ró fún ara wọn; Jònátánì+ ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù,+ ọmọkùnrin Mósè, òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, sì di àlùfáà fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì títí di ọjọ́ tí a kó ilẹ̀ náà lọ sí ìgbèkùn.+ 31  Wọ́n sì gbé ère gbígbẹ́ Míkà, èyí tí ó ṣe, kalẹ̀ fún ara wọn ní gbogbo ọjọ́ tí ilé+ Ọlọ́run tòótọ́ fi ń bá a lọ ní wíwà ní Ṣílò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé