Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 17:1-13

17  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan báyìí wà, ará ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà.  Nígbà tí ó ṣe, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ẹyọ fàdákà náà tí a mú lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì tìtorí rẹ̀ gégùn-ún,+ tí o sì tún sọ ọ́ ní etí-ìgbọ́ mi—wò ó! fàdákà náà wà lọ́dọ̀ mi. Èmi ni ó mú un.”+ Látàrí ìyẹn, ìyá rẹ̀ wí pé: “Alábùkún ni kí ọmọkùnrin mi jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ẹyọ fàdákà náà fún ìyá rẹ̀ padà;+ ìyá rẹ̀ sì ń bá a lọ láti wí pé: “Láìkùnà, èmi yóò sọ fàdákà náà di mímọ́ fún Jèhófà láti ọwọ́ mi fún ọmọkùnrin mi, láti lè ṣe ère gbígbẹ́+ àti ère dídà;+ wàyí o, èmi yóò fi í fún ọ padà.”  Nítorí náà, ó dá fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba ẹyọ fàdákà, ó sì fi í fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ère gbígbẹ́+ kan àti ère dídà;+ ó sì wà ní ilé Míkà.  Ní ti ọkùnrin náà Míkà, ó ní ilé kan fún àwọn ọlọ́run,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe éfódì+ kan àti ère tẹ́ráfímù,+ ó sì fi agbára kún ọwọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ kí ó lè máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún un.+  Ní ọjọ́ wọnnì, kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì.+ Ní ti olúkúlùkù, ohun tí ó tọ̀nà ní ojú tirẹ̀ ni ó ti mọ́ ọn lára láti máa ṣe.+  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́kùnrin kan wà, ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, láti inú ìdílé Júdà, ọmọ Léfì+ sì ni. Ó sì ń gbé níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.  Ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ìlú ńlá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà láti lọ gbé fún ìgbà díẹ̀ ní ibikíbi tí ó bá ti lè rí àyè. Níkẹyìn, bí ó ti ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù títí dé ilé Míkà.+  Nígbà náà ni Míkà wí fún un pé: “Ibo ni o ti wá?” Látàrí ìyẹn, ó wí fún un pé: “Ọmọ Léfì ni mí, láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, mo sì ń bá ọ̀nà mi lọ láti gbé fún ìgbà díẹ̀ ní ibikíbi tí mo bá ti lè rí àyè.” 10  Nítorí náà, Míkà wí fún un pé: “Máa bá mi gbé, kí o sì máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí baba+ àti àlùfáà+ fún mi, èmi, ní tèmi, yóò sì fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá lọ́dún àti àwọn ẹ̀wù wíwọ̀ bí àṣà àti ohun ìgbẹ́mìí rẹ ró.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọmọ Léfì náà wọlé. 11  Bí ọmọ Léfì náà ti dáwọ́ lé àtimáa bá ọkùnrin náà gbé nìyẹn, ọ̀dọ́kùnrin náà sì wá dà bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sí i. 12  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Míkà fi agbára kún ọwọ́ ọmọ Léfì náà,+ kí ọ̀dọ́kùnrin náà lè máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà+ fún un, kí ó sì lè máa bá a lọ ní wíwà ní ilé Míkà. 13  Nítorí náà, Míkà wí pé: “Ìsinsìnyí ni mo mọ̀ pé Jèhófà yóò ṣe rere sí mi, nítorí pé ọmọ Léfì ti di àlùfáà fún mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé