Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 16:1-31

16  Nígbà kan, Sámúsìnì lọ sí Gásà,+ ó sì rí obìnrin kárùwà kan níbẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́.+  A sì ròyìn fún àwọn ará Gásà pé: “Sámúsìnì ti wọlé wá síhìn-ín.” Nítorí náà, wọ́n yí i ká,+ wọ́n sì lúgọ dè é láti òru mọ́jú ní ẹnubodè ìlú ńlá náà.+ Wọ́n sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní gbogbo òru náà, pé: “Gbàrà tí ilẹ̀ bá mọ́ ní òwúrọ̀, àwa yóò sì pa á.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, Sámúsìnì ń bá a nìṣó ní dídùbúlẹ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru, ó sì wá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó sì gbá àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú ńlá náà+ mú àti àwọn arópòódògiri ẹ̀gbẹ́ méjèèjì , ó sì fà wọ́n tu pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì gbé+ wọn sórí èjì ká rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn gòkè lọ sí orí òkè ńlá tí ó wà níwájú Hébúrónì.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn pé ó kó sínú ìfẹ́ fún obìnrin kan ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Sórékì, orúkọ rẹ̀ sì ni Dẹ̀lílà.+  Àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé: “Tàn+ án kí o sì rí inú ohun tí agbára ńlá rẹ̀ wà àti ohun tí a lè fi borí rẹ̀ àti ohun tí a lè fi dè é kí a sì kápá rẹ̀; àwa, ní tiwa, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ẹyọ fàdákà.”+  Lẹ́yìn náà, Dẹ̀lílà wí fún Sámúsìnì pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, Inú kí ni agbára ńlá rẹ wà, kí sì ni a lè fi dè ọ́ kí ẹnì kan tó lè kápá rẹ?”+  Nígbà náà ni Sámúsìnì wí fún un pé: “Bí wọ́n bá fi fọ́nrán iṣan méje tí ó ṣì ní ọ̀rinrin+ tí kò tíì gbẹ dè mí, èmi pẹ̀lú yóò di aláìlera, èmi a sì dà bí ọkùnrin ṣákálá kan.”  Nítorí náà, àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì mú fọ́nrán iṣan méje tí ó ṣì ní ọ̀rinrin tí kò tíì gbẹ gòkè wá fún un. Lẹ́yìn náà, ó fi wọ́n dè é.  Wàyí o, àwọn abadeni jókòó sí yàrá rẹ̀ ti inú lọ́hùn-ún,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Àwọn Filísínì+ dé bá ọ, Sámúsìnì!” Látàrí ìyẹn, ó fa fọ́nrán iṣan náà já sí méjì , gan-an gẹ́gẹ́ bí fọ́nrán òwú èétú okùn lílọ́ ti máa ń já sí méjì bí ó bá ti gbóòórùn iná.+ Agbára rẹ̀ kò sì di mímọ̀.+ 10  Lẹ́yìn náà, Dẹ̀lílà+ wí fún Sámúsìnì pé: “Wò ó! O ti fi mí ṣeré kí o lè pa irọ́ fún mi.+ Wàyí o, jọ̀wọ́, sọ ohun tí a lè fi dè ọ́ fún mi.” 11  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Bí wọ́n bá fi àwọn ìjàrá tuntun tí a kò tíì fi ṣe iṣẹ́ rárá dè mí dan-in dan-in, èmi pẹ̀lú yóò di aláìlera, èmi a sì dà bí ọkùnrin ṣákálá kan.” 12  Nítorí náà, Dẹ̀lílà mú àwọn ìjàrá tuntun, ó sì fi wọ́n dè é, ó sì wí fún un pé: “Àwọn Filísínì dé bá ọ, Sámúsìnì!” Ní gbogbo àkókò náà, àwọn abadeni jókòó sí inú yàrá inú lọ́hùn-ún.+ Látàrí ìyẹn, ó fà wọ́n já sí méjì kúrò ní apá rẹ̀ bí fọ́nrán òwú.+ 13  Lẹ́yìn ìyẹn, Dẹ̀lílà wí fún Sámúsìnì pé: “Títí di ìsinsìnyí, o ti fi mí ṣeré kí o lè pa irọ́ fún mi.+ Sọ ohun tí a lè fi dè ọ́ fún mi.”+ Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “Bí ìwọ yóò bá fi fọ́nrán òwú títa+ di ìdì-irun méje orí mi.” 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fi ìkànlẹ̀ dè wọ́n pinpin, lẹ́yìn èyí tí ó wí fún un pé: “Àwọn Filísínì dé bá ọ, Sámúsìnì!”+ Nítorí náà, ó jí lójú oorun rẹ̀, ó sì fa ìkànlẹ̀ òfì àti fọ́nrán òwú títa náà yọ. 15  Wàyí o, ó wí fún un pé: “Kí ló mú ọ dá a láṣà pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ,’+ nígbà tí ọkàn-àyà rẹ kò wà pẹ̀lú mi? Ìgbà mẹ́ta yìí ni o ti fi mí ṣeré, ìwọ kò sì sọ inú ohun tí agbára ńlá rẹ wà fún mi.”+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí pé ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ pin ín lẹ́mìí+ ní gbogbo ìgbà, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá, ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀ títí dé ojú àtikú.+ 17  Níkẹyìn, ó sọ gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ di mímọ̀ fún un,+ ó sì wí fún un pé: “Abẹ fẹ́lẹ́+ kò kan orí mi rí, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni mí láti inú ikùn ìyá mi.+ Bí mo bá fárí, dájúdájú agbára mi pẹ̀lú yóò lọ kúrò lára mi, èmi yóò sì di aláìlera ní tòótọ́, èmi yóò sì dà bí gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn.”+ 18  Nígbà tí Dẹ̀lílà wá rí i pé ó ti sọ gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ di mímọ̀ fún un, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó ránṣẹ́ pe àwọn olúwa+ alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì pé: “Ẹ gòkè wá lọ́tẹ̀ yìí, nítorí ó ti sọ gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ di mímọ̀ fún mi.”+ Àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì sì gòkè tọ̀ ọ́ wá kí wọ́n lè mú owó náà gòkè wá ní ọwọ́ wọn.+ 19  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí ó sùn sórí eékún rẹ̀. Nígbà náà ni ó pe ọkùnrin náà, ó sì mú kí ó fá ìdì-irun méje orí rẹ̀ kúrò, lẹ́yìn èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kápá rẹ̀, agbára rẹ̀ sì ń bá a nìṣó ní lílọ kúrò lára rẹ̀. 20  Wàyí o, ó wí pé: “Àwọn Filísínì dé bá ọ, Sámúsìnì!” Látàrí ìyẹn, ó jí lójú oorun rẹ̀, ó sì wí pé: “Èmi yóò jáde lọ bí ti àtẹ̀yìnwá,+ èmi yóò sì gbọn ara mi bọ́.” Òun fúnra rẹ̀ kò sì mọ̀ pé Jèhófà ni ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ òun.+ 21  Nítorí náà, àwọn Filísínì gbá a mú, wọ́n sì yọ àwọn ojú rẹ̀ jáde,+ wọ́n sì mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Gásà,+ wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é;+ ó sì di olùlọ-ọlọ+ ní ilé ẹ̀wọ̀n.+ 22  Láàárín àkókò yìí, irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí hù ṣàkìtì-ṣàkìtì ní gbàrà tí a ti fárí rẹ̀.+ 23  Ní ti àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì, wọ́n kóra jọpọ̀ láti rú ẹbọ ńlá sí Dágónì+ ọlọ́run wọn àti fún ayọ̀ yíyọ̀, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní wíwí pé: “Ọlọ́run wa ti fi Sámúsìnì ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́!”+ 24  Nígbà tí àwọn ènìyàn náà wá rí i, kíákíá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yin ọlọ́run wọn,+ wọ́n wí pé, “nítorí pé, ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa+ lé wa lọ́wọ́ àti olùpa ilẹ̀ wa run di ahoro+ àti ẹni tí ó sọ àwọn tí a pa nínú wá di púpọ̀ sí i.”+ 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí ọkàn-àyà wọn kún fún àríyá,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ pe Sámúsìnì wá kí ó lè dá wa nínú dùn.”+ Nítorí náà, wọ́n pe Sámúsìnì jáde ní ilé ẹ̀wọ̀n kí ó lè ṣe eré ìdárayá níwájú wọn;+ wọ́n sì tẹ̀ sìwájú láti mú un dúró láàárín àwọn ọwọ̀n. 26  Nígbà náà ni Sámúsìnì sọ fún ọmọdékùnrin tí ó dì í ní ọwọ́ mú pé: “Jẹ́ kí n fọwọ́ ba àwọn ọwọ̀n tí ilé náà fìdí múlẹ̀ lé gbọn-in gbọn-in, sì jẹ́ kí n fara tì wọ́n.” 27  (Ó ṣẹlẹ̀ pé, ilé náà kún fún ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì sì wà níbẹ̀;+ nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin àti obìnrin ni ó sì wà lórí òrùlé náà tí wọ́n ń wòran bí Sámúsìnì ti ń dá wọn nínú dùn.)+ 28  Sámúsìnì+ ké pe Jèhófà+ wàyí, ó sì wí pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, rántí mi,+ jọ̀wọ́, kí o sì fún mi lókun,+ jọ̀wọ́, lẹ́ẹ̀kan yìí péré, ìwọ Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì jẹ́ kí n gbẹ̀san ara mi lára àwọn Filísínì nípa gbígbẹ̀san ọ̀kan nínú ojú mi méjèèjì .”+ 29  Pẹ̀lú ìyẹn, Sámúsìnì fara ti ọwọ̀n méjèèjì tí ó wà ní àárín, tí ilé náà fìdí múlẹ̀ lé gbọn-in gbọn-in, ó sì gbá wọn mú, ọ̀kan pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti èkejì pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀. 30  Sámúsìnì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Jẹ́ kí ọkàn mi kú+ pẹ̀lú àwọn Filísínì.” Nígbà náà ni ó tẹ̀ tagbára-tagbára, ilé náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wó lé àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ lórí àti lé gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ lórí,+ tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó kú, tí ó fi ikú pa nígbà ikú tirẹ̀, wá pọ̀ ju àwọn tí ó fi ikú pa nígbà ayé rẹ̀.+ 31  Lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo agbo ilé baba rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ wá, wọ́n sì gbé e gòkè wá, wọ́n sì sin ín sáàárín Sórà+ àti Éṣítáólì,+ ní ibi ìsìnkú Mánóà+ baba rẹ̀. Ní tirẹ̀, ó ti ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogún ọdún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé