Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 15:1-20

15  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ní àwọn ọjọ́ ìkórè àlìkámà, pé Sámúsìnì mú ọmọ ewúrẹ́ kan+ lọ bẹ aya rẹ̀ wò. Nítorí náà, ó wí pé: “Èmi yóò wọlé lọ bá aya mi nínú yàrá inú lọ́hùn-ún.”+ Baba obìnrin náà kò sì yọ̀ǹda fún un láti wọlé.  Ṣùgbọ́n baba obìnrin náà wí pé: “Ní tòótọ́, mo wí fún ara mi pé, ‘Láìsí àní-àní, ìwọ ti ní láti kórìíra rẹ̀.’+ Nítorí náà, mo fi í fún ọ̀rẹ́kùnrin tí ó bá ìwọ ọkọ-ìyàwó rìn.+ Àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha sàn jù ú lọ bí? Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó di tìrẹ dípò èkejì .”  Bí ó ti wù kí ó rí, Sámúsìnì wí fún wọn pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, èmi yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi lòdì sí àwọn Filísínì bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé èmi yóò bá wọn lò sí ìṣeléṣe wọn.”+  Sámúsìnì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú ọ̀ọ́dúnrún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,+ ó sì kó àwọn ògùṣọ̀, ó sì yí ìrù sí ìrù, ó sì fi ògùṣọ̀ kan sáàárín ìrù méjì , ní àárín gan-an.  Pẹ̀lú ìyẹn, ó fi iná sí àwọn ògùṣọ̀ náà, ó sì rán wọn jáde sínú àwọn pápá ọkà tí ó wà ní ìdúró, tí ó jẹ́ ti àwọn Filísínì. Bí ó ṣe dáná ran ohun gbogbo nìyẹn, láti orí ìtí sí ọkà tí ó wà ní ìdúró àti àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn oko olífì.+  Àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ta ní ṣe èyí?” Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Sámúsìnì ọkọ ọmọ ará Tímúnà náà ni, nítorí pé ó gba aya rẹ̀, ó sì fi í fún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ abọ́kọ-ìyàwó-rìn.”+ Látàrí ìyẹn, àwọn Filísínì gòkè lọ, wọ́n sì fi iná sun òun àti baba rẹ̀.+  Ẹ̀wẹ̀, Sámúsìnì wí fún wọn pé: “Bí ẹ bá ṣe bí èyí, kò sí nǹkan mìíràn ju pé kí n gbẹ̀san ara mi lára yín,+ lẹ́yìn ìgbà náà, èmi yóò sì jáwọ́.”  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, ní títo àwọn ẹsẹ̀ lórí àwọn itan jọ pelemọ pẹ̀lú ìpakúpa ńláǹlà, lẹ́yìn èyí tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní pàlàpálá àpáta gàǹgà náà Étámì.+  Lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì+ gòkè wá, wọ́n sì dó sí Júdà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn káàkiri Léhì.+ 10  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Júdà wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi gòkè wá láti gbéjà kò wá?” wọ́n fèsì pé: “Nítorí àtide Sámúsìnì ni a ṣe gòkè wá, láti ṣe sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí wa.” 11  Nítorí náà, ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin Júdà sọ̀ kalẹ̀ lọ sí pàlàpálá àpáta gàǹgà náà Étámì,+ wọ́n sì wí fún Sámúsìnì pé: “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn Filísínì ni ń ṣàkóso lórí wa ni?+ Nítorí náà, kí ni èyí tí o ṣe sí wa yìí túmọ̀ sí?” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí mi gan-an ni bí mo ti ṣe sí wọn.”+ 12  Ṣùgbọ́n wọ́n wí fún un pé: “Nítorí àtidè ọ́ ni a ṣe sọ̀ kalẹ̀ wá, láti fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn Filísínì.” Látàrí ìyẹn, Sámúsìnì wí fún wọn pé: “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin fúnra yín kì yóò fipá kọlù mí.” 13  Wọ́n sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò wulẹ̀ dè ọ́ ni, a ó sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́; ṣùgbọ́n àwa kì yóò fi ikú pa ọ́ lọ́nàkọnà.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n fi ìjàrá tuntun méjì  dè é,+ wọ́n sì gbé e gòkè wá láti inú àpáta gàǹgà náà. 14  Òun, ní tirẹ̀, sì ń bọ̀ wá títí ó fi dé Léhì, àwọn Filísínì, ní tiwọn, sì kígbe ayọ̀ ńláǹlà bí wọ́n ti pàdé rẹ̀.+ Ẹ̀mí+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, àwọn ìjàrá tí ó wà ní apá rẹ̀ sì wá dà bí àwọn fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná ti jó gbẹ,+ tí àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ̀ fi yọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. 15  Wàyí o, ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ tútù kan ti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣá ẹgbẹ̀rún ọkùnrin balẹ̀.+ 16  Nígbà náà ni Sámúsìnì wí pé: “Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́—òkìtì kan, òkìtì méjì ! Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, mo ti ṣá ẹgbẹ̀rún ọkùnrin balẹ̀.”+ 17  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ sísọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nù, ó sì pe ibẹ̀ ní Ramati-léhì.+ 18  Wàyí o, òùngbẹ ń gbẹ ẹ́ gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà, ó sì wí pé: “Ìwọ ni ó fi ìgbàlà ńláǹlà yìí lé ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ,+ àti nísinsìnyí, èmi yóò ha kú nítorí òùngbẹ kí n sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́?”+ 19  Nítorí náà, Ọlọ́run pín ibi kótópó onírìísí odó tí ó wà ní Léhì níyà, omi+ sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá láti inú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mumi, lẹ́yìn èyí tí ẹ̀mí+ rẹ̀ padà, ó sì sọ jí.+ Ìdí nìyẹn tí ó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹn-hákórè, èyí tí ó wà ní Léhì títí di òní yìí. 20  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogún ọdún ní ọjọ́ àwọn Filísínì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé