Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 14:1-20

14  Nígbà náà ni Sámúsìnì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà,+ ó sì rí obìnrin kan ní Tímúnà lára àwọn ọmọbìnrin àwọn Filísínì.  Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó sì sọ fún baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, ó sì wí pé: “Obìnrin kan wà tí mo rí ní Tímúnà, lára àwọn ọmọbìnrin àwọn Filísínì, wàyí o, ẹ fẹ́ ẹ fún mi kí n fi ṣe aya.”+  Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ wí fún un pé: “Kò ha sí obìnrin kankan láàárín àwọn ọmọbìnrin arákùnrin rẹ àti láàárín gbogbo àwọn ènìyàn mi ni,+ tí ó fi jẹ́ pé ìwọ yóò lọ fẹ́ aya láti inú àwọn Filísínì aláìdádọ̀dọ́?”+ Síbẹ̀ Sámúsìnì wí fún baba rẹ̀ pé: “Òun gan-an ni kí o fẹ́ fún mi, nítorí pé òun gan-an ló ṣe wẹ́kú ní ojú mi.”  Ní ti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, wọn kò mọ̀ pé ìyẹn jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ pé ó ń wá àyè lòdì sí àwọn Filísínì, ní àkókò yẹn gan-an, àwọn Filísínì ní ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúsìnì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà+ pẹ̀lú baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀. Nígbà tí ó lọ títí dé àwọn ọgbà àjàrà Tímúnà, họ́wù, wò ó! ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ kan ń ké ramúramù nígbà tí ó pàdé rẹ̀.  Nígbà náà ni ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀,+ tí ó fi ya á sí méjì , gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹni ya akọ ọmọ ẹran sí méjì , kò sì sí nǹkan kan rárá ní ọwọ́ rẹ̀. Kò sì sọ ohun tí ó ṣe fún baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀.  Ó sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin náà sọ̀rọ̀; ó sì ṣe wẹ́kú síbẹ̀ ní ojú Sámúsìnì.+  Wàyí o, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó padà lọ láti mú un wá sí ilé.+ Láàárín àkókò náà, ó yà láti bojú wo òkú kìnnìún náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kòkòrò oyin sì ń bẹ níbẹ̀ nínú òkú kìnnìún náà, àti oyin.+  Nítorí náà, ó fá a sínú àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó sì ń rìn lọ, ó ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń rìn lọ.+ Nígbà tí ó tún dara pọ̀ mọ́ baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, lójú ẹsẹ̀, ó fún wọn lára rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Kò sì sọ fún wọn pé láti inú òkú kìnnìún ni òun ti fá oyin náà. 10  Baba rẹ̀ sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà, Sámúsìnì sì bẹ̀rẹ̀ sí se àkànṣe àsè níbẹ̀;+ nítorí bí àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn ti máa ń ṣe nìyẹn. 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti rí i, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n mú ọgbọ̀n ọ̀rẹ́kùnrin abọ́kọ-ìyàwó-rìn wá, pé kí àwọn wọ̀nyí wà pẹ̀lú rẹ̀. 12  Nígbà náà ni Sámúsìnì wí fún wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún yín.+ Bí ẹ bá lè já a fún mi láìkùnà láàárín ọjọ́ méje+ àkànṣe àsè yìí, tí ẹ sì rí ojútùú rẹ̀, nígbà náà, èmi yóò ní láti fún yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ọgbọ̀n aṣọ wíwọ̀.+ 13  Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lè já a fún mi, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú fún mi ní ọgbọ̀n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ọgbọ̀n aṣọ wíwọ̀.” Látàrí èyí, wọ́n wí fún un pé: “Pa àlọ́ rẹ, kí a gbọ́.” 14  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Láti inú olùjẹ nǹkan+ ni nǹkan jíjẹ ti jáde wá, Láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn ti jáde wá.”+ Wọn kò sì lè já àlọ́ náà fún ọjọ́ mẹ́ta. 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún aya Sámúsìnì pé: “Tan ọkọ rẹ kí ó lè já àlọ́ náà fún wa.+ Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò fi iná sun ìwọ àti ilé baba rẹ.+ Ṣé láti gba ohun ìní wa+ ni ẹ ṣe ké sí wa wá sí ìhín ni?” 16  Nítorí náà, aya Sámúsìnì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lé e lórí,+ ó sì wí pé: “Ìwọ sáà kórìíra mi, o kórìíra mi,+ o kò sì nífẹ̀ẹ́ mi. Àlọ́ kan wà tí o pa fún àwọn ọmọ àwọn ènìyàn mi,+ ṣùgbọ́n o kò já a fún mi.” Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Họ́wù, èmi kò já a fún baba tèmi àti ìyá tèmi,+ ó ha yẹ kí n já a fún ọ bí?” 17  Ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní sísunkún lé e lórí fún ọjọ́ méje tí àkànṣe àsè náà ń bá a lọ fún wọn, ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé ó já a fún un níkẹyìn, nítorí pé ó ti pin ín lẹ́mìí.+ Lẹ́yìn náà, ó já àlọ́ náà fún àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 18  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà wí fún un ní ọjọ́ keje ṣáájú kí ó tó lọ rárá sínú yàrá inú lọ́hùn-ún pé:+ “Kí ni ó dùn ju oyin lọ,+ Kí sì ni ó lágbára ju kìnnìún lọ?” Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ká ní ẹ kò fi ẹgbọrọ abo màlúù mi túlẹ̀ ni,+ Ẹ kì bá ti rí ojútùú àlọ́ mi.”+ 19  Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀,+ tí ó fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Áṣíkẹ́lónì,+ ó sì ṣá ọgbọ̀n ọkùnrin balẹ̀ lára wọn, ó sì kó ohun tí ó bọ́ kúrò lára wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wíwọ̀ náà fún àwọn tí ó já àlọ́ náà.+ Ìbínú rẹ̀ sì ń bá a lọ ní gbígbóná, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gòkè lọ sí ilé baba rẹ̀. 20  Aya Sámúsìnì+ sì wá di ti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ abọ́kọ-ìyàwó-rìn+ tí ó ti bá a kẹ́gbẹ́ rí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé