Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 13:1-25

13  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún kó wọnú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà fi wọ́n lé àwọn Filísínì+ lọ́wọ́ fún ogójì ọdún.  Láàárín àkókò yìí, ó ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin ará Sórà+ kan wà, láti inú ìdílé àwọn ọmọ Dánì,+ orúkọ rẹ̀ sì ni Mánóà.+ Aya rẹ̀ sì yàgàn, kò sì bímọ.+  Nígbà tí ó ṣe, áńgẹ́lì Jèhófà fara han obìnrin náà,+ ó sì wí fún un pé: “Wò ó, nísinsìnyí, ìwọ yàgàn, o kò sì bímọ. Dájúdájú, ìwọ yóò sì lóyún, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan.+  Wàyí o, ṣọ́ ara rẹ, jọ̀wọ́, má sì mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani,+ má sì jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ àìmọ́.+  Nítorí, wò ó! dájúdájú, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, kí abẹ fẹ́lẹ́ má sì kan orí rẹ̀,+ nítorí pé Násírì+ Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò dà bí ó bá ti jáde láti inú ikùn wá;+ òun sì ni ẹni tí yóò mú ipò iwájú nínú gbígba Ísírẹ́lì là kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.”+  Nígbà náà ni obìnrin náà lọ, ó sì sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ sì dà bí ìrísí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́,+ ó múni kún fún ẹ̀rù gidigidi.+ Èmi kò sì béèrè ibi tí ó ti wá gan-an lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.+  Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé, ‘Wò ó! Ìwọ yóò lóyún, dájúdájú, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.+ Wàyí o, má mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani, má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò dà bí ó bá ti jáde láti inú ikùn wá títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’”+  Mánóà sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà sí Jèhófà, ó sì wí pé: “Dákun, Jèhófà.+ Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó tún tọ̀ wá wá, kí ó sì fún wa ní ìtọ́ni+ ní ti ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí ọmọ náà tí a óò bí.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run tòótọ́ fetí sí ohùn Mánóà,+ áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ sì tún tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó jókòó ní pápá, Mánóà ọkọ rẹ̀ kò sì sí lọ́dọ̀ rẹ̀. 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin náà ṣe wéré, ó sì sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀,+ ó sì wí fún un pé: “Wò ó! Ọkùnrin tí ó tọ̀ mí wá ní ìjọ́sí ti fara hàn mí.”+ 11  Látàrí ìyẹn, Mánóà dìde ó sì bá aya rẹ̀ lọ, ó sì tọ ọkùnrin náà wá, ó sì wí fún un pé: “Ṣé ìwọ ní ọkùnrin náà tí ó bá obìnrin náà sọ̀rọ̀?”+ ó dáhùn pé: “Èmi ni.” 12  Nígbà náà ni Mánóà wí pé: “Wàyí o, kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó ṣẹ. Kí ni ọ̀nà ìgbésì ayé ọmọ náà àti iṣẹ́ rẹ̀ yóò jẹ́?”+ 13  Nítorí náà, áńgẹ́lì Jèhófà wí fún Mánóà pé: “Kí obìnrin náà pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ohun gbogbo tí mo mẹ́nu kàn fún un.+ 14  Kí ó má jẹ nǹkan kan tí ó ti ara àjàrà wáìnì jáde wá, kí ó má sì mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani,+ kí ó má sì jẹ ohun àìmọ́ irú èyíkéyìí.+ Gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún un ni kí ó pa mọ́.”+ 15  Wàyí o, Mánóà wí fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a dá ọ dúró, kí a sì pèsè ọmọ ewúrẹ́ kan sílẹ̀ níwájú rẹ.”+ 16  Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì Jèhófà wí fún Mánóà pé: “Bí o bá dá mi dúró, èmi kì yóò fi oúnjẹ rẹ bọ́ ara mi; ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà,+ o lè rú u.” Nítorí Mánóà kò mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni. 17  Nígbà náà ni Mánóà wí fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Kí ni orúkọ rẹ,+ kí a lè bọlá fún ọ dájúdájú nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” 18  Bí ó ti wù kí ó rí, áńgẹ́lì Jèhófà wí fún un pé: “Èé sì ti ṣe tí o fi ń béèrè nípa orúkọ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé àgbàyanu ni?” 19  Mánóà sì tẹ̀ síwájú láti mú ọmọ ewúrẹ́ àti ọrẹ ẹbọ ọkà, ó sì fi í rúbọ lórí àpáta sí Jèhófà.+ Ó sì ń ṣe ohun kan ní ọ̀nà àgbàyanu bí Mánóà àti aya rẹ̀ ti ń wò ó níran. 20  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, bí ọwọ́ iná ti ń gòkè láti orí pẹpẹ síhà ọ̀run, nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà gòkè nínú ọwọ́ iná pẹpẹ náà bí Mánóà àti aya rẹ̀ ti ń wò ó níran.+ Kíákíá, wọ́n dojú bolẹ̀.+ 21  Áńgẹ́lì Jèhófà kò sì tún fara han Mánóà àti aya rẹ̀ mọ́ rárá. Ìgbà náà ni Mánóà wá mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni.+ 22  Nítorí náà, Mánóà wí fún aya rẹ̀ pé: “Dájúdájú, àwa yóò kú,+ nítorí pé àwa ti rí Ọlọ́run.”+ 23  Ṣùgbọ́n aya rẹ̀ wí fún un pé: “Ká ní Jèhófà ní inú dídùn sí kìkì láti fi ikú pa wá ni, kì bá ti tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà ní ọwọ́ wa,+ kì bá sì ti fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá, kì bá sì ti jẹ́ kí a gbọ́ ohunkóhun bí èyí nísinsìnyí.”+ 24  Lẹ́yìn náà, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúsìnì;+ ọmọdékùnrin náà sì ń bá a nìṣó ní dídàgbà sí i, Jèhófà sì ń bá a lọ ní bíbùkún fún un.+ 25  Nígbà tí ó ṣe, ẹ̀mí+ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sún un ṣiṣẹ́ ní Mahane-dánì+ láàárín Sórà+ àti Éṣítáólì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé