Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 12:1-15

12  Nígbà náà ni a pe àwọn ọkùnrin Éfúráímù jọ, wọ́n sì sọdá síhà àríwá, wọ́n sì wí fún Jẹ́fútà pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé o sọdá lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà, tí o kò sì ránṣẹ́ pè wá láti bá ọ lọ?+ Ilé rẹ ni àwa yóò fi iná sun mọ́ ọ lórí.”+  Ṣùgbọ́n Jẹ́fútà wí fún wọn pé: “Èmi di àkànṣe abánijà, èmi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú àwọn ọmọ Ámónì.+ Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pè yín fún ìrànlọ́wọ́, ẹ kò sì gbà mí là lọ́wọ́ wọn.  Nígbà tí mo wá rí i pé ìwọ kì í ṣe olùgbàlà, nígbà náà ni mo pinnu láti fi ọkàn mi sí àtẹ́lẹwọ́ mi,+ mo sì sọdá lọ láti dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Ámónì.+ Látàrí ìyẹn, Jèhófà fi wọ́n lé mi lọ́wọ́. Nítorí náà, èé ṣe ti ẹ fi gòkè wá bá mi lónìí yìí láti bá mi jà?”  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jẹ́fútà kó gbogbo àwọn ọkùnrin Gílíádì jọpọ̀,+ ó sì bá Éfúráímù jà; àwọn ọkùnrin Gílíádì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Éfúráímù balẹ̀, nítorí wọ́n ti wí pé: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà láti inú Éfúráímù ni yín, Gílíádì, nínú Éfúráímù, nínú Mánásè.”  Gílíádì sì gba àwọn ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Jọ́dánì+ ṣáájú Éfúráímù; ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ọkùnrin Éfúráímù tí ń sá àsálà bá wí pé: “Jẹ́ kí n ré kọjá,” nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Gílíádì a wí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan pé: “Ṣé ọmọ Éfúráímù ni ọ́?” Nígbà tí ó bá wí pé: “Rárá!”  Nígbà náà, wọn a wí fún un pé: “Jọ̀wọ́ sọ pé Ṣíbólẹ́tì.”+ Òun a sì sọ pé: “Síbólẹ́tì,” níwọ̀n bí òun kò ti lè pe ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ó tọ̀nà. Wọn a sì gbá a mú, wọn a sì pa á ní àwọn ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Jọ́dánì. Nítorí náà, ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbàá láti Éfúráímù ṣubú ní àkókò yẹn.+  Jẹ́fútà sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́fà, lẹ́yìn èyí ni Jẹ́fútà ọmọ Gílíádì kú, a sì sin ín sí ìlú ńlá rẹ̀ ní Gílíádì.  Íbísánì láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì lẹ́yìn rẹ̀.+  Ó sì wá ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin. Ó sì ránṣẹ́ lọ sí òde, ó sì mú ọgbọ̀n ọmọbìnrin wá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti òde wá. Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méje. 10  Nígbà náà ni Íbísánì kú, a sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 11  Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Élónì ọmọ Sébúlúnì+ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì. Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá. 12  Nígbà náà ni Élónì ọmọ Sébúlúnì kú, a sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Sébúlúnì. 13  Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Ábídónì ọmọkùnrin Hílẹ́lì ará Pírátónì+ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì. 14  Ó sì wá ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ-ọmọ tí ń gun àádọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán.+ Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́jọ. 15  Nígbà náà ni Ábídónì ọmọkùnrin Hílẹ́lì ará Pírátónì kú, a sì sin ín sí Pírátónì ní ilẹ̀ Éfúráímù ní òkè ńlá ọmọ Ámálékì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé