Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 11:1-40

11  Wàyí o, Jẹ́fútà+ ọmọ Gílíádì+ ti di alágbára ńlá, akíkanjú ọkùnrin,+ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin kárùwà+ obìnrin kan, Gílíádì sì wá bí Jẹ́fútà.  Aya Gílíádì sì ń bí àwọn ọmọkùnrin fún un. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin aya náà wá dàgbà, wọ́n tẹ̀ síwájú láti lé Jẹ́fútà jáde, wọ́n sì wí fún un pé: “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní agbo ilé baba wa,+ nítorí ọmọkùnrin obìnrin mìíràn ni ọ́.”  Nítorí náà, Jẹ́fútà fẹsẹ̀ fẹ nítorí àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ilẹ̀ Tóbù.+ Àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan sì ń bá a nìṣó ní kíkó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ Jẹ́fútà, wọn a sì bá a jáde lọ.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì bẹ̀rẹ̀ sí bá Ísírẹ́lì jà.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà+ ní ti gidi, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì lọ láti mú Jẹ́fútà láti ilẹ̀ Tóbù.+  Nígbà náà ni wọ́n wí fún Jẹ́fútà pé: “Wá jẹ ọ̀gágun wa, kí o sì jẹ́ kí a bá àwọn ọmọ Ámónì jà.”  Ṣùgbọ́n Jẹ́fútà wí fún àwọn àgbà ọkùnrin+ Gílíádì pé: “Ẹ̀yin ha kọ́ ni ẹ kórìíra mi tí ẹ fi lé mi jáde ní ilé baba mi?+ Èé sì ti ṣe tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nísinsìnyí, kìkì nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”+  Látàrí èyí, àwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì wí fún Jẹ́fútà pé: “Ìdí nìyẹn tí a fi padà+ sọ́dọ̀ rẹ nísinsìnyí, kí o sì bá wa lọ láti bá àwọn ọmọ Ámónì jà, kí o sì di olórí gbogbo àwọn olùgbé Gílíádì+ fún wa.”  Nítorí náà, Jẹ́fútà wí fún àwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì pé: “Bí ẹ bá ń mú mi padà láti bá àwọn ọmọ Ámónì jà, tí Jèhófà sì jọ̀wọ́+ wọn fún mi, èmi, ní tèmi, yóò di olórí yín!” 10  Ẹ̀wẹ̀, àwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì wí fún Jẹ́fútà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ olùfetísílẹ̀ láàárín wa+ bí kì í bá ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ ni bí àwa yóò ti ṣe.”+ 11  Nítorí náà, Jẹ́fútà bá àwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi í ṣe olórí àti ọ̀gágun+ lórí wọn. Jẹ́fútà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ níwájú Jèhófà+ ní Mísípà.+ 12  Nígbà náà ni Jẹ́fútà rán àwọn ońṣẹ́ sí ọba àwọn ọmọ Ámónì+ pé: “Kí ni ó pa tèmi tìrẹ pọ̀,+ nítorí pé o wá bá mi jà ní ilẹ̀ mi?” 13  Nítorí náà, ọba àwọn ọmọ Ámónì sọ fún àwọn ońṣẹ́ Jẹ́fútà pé: “Ó jẹ́ nítorí pé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ mi nígbà tí wọ́n gòkè wá láti Íjíbítì,+ láti Áánónì+ títí dé Jábókù àti títí dé Jọ́dánì.+ Wàyí o, dá a padà ní àlàáfíà.” 14  Ṣùgbọ́n Jẹ́fútà rán àwọn ońṣẹ́ sí ọba àwọn ọmọ Ámónì lẹ́ẹ̀kan sí i 15  ó sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jẹ́fútà wí, ‘Ísírẹ́lì kò gba ilẹ̀ Móábù+ àti ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì.+ 16  Nítorí nígbà tí wọ́n gòkè wá láti Íjíbítì, Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí rìn la aginjù kọjá títí dé Òkun Pupa,+ ó sì wá dé Kádéṣì.+ 17  Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn ońṣẹ́ sí ọba Édómù+ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá,” ọba Édómù kò sì fetí sílẹ̀. Wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba Móábù+ pẹ̀lú, òun kò sì gbà. Ísírẹ́lì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Kádéṣì.+ 18  Nígbà tí wọ́n ń rìn la aginjù kọjá, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ yí ilẹ̀ Édómù+ àti ilẹ̀ Móábù ká, tí wọ́n fi lọ síhà yíyọ oòrùn ní ti ilẹ̀ Móábù,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dó sí ẹkùn ilẹ̀ Áánónì; wọn kò sì dé inú ààlà Móábù,+ nítorí Áánónì ni ààlà Móábù.+ 19  “‘Lẹ́yìn ìyẹn, Ísírẹ́lì rán àwọn ońṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn Ámórì, ọba Hẹ́ṣíbónì,+ Ísírẹ́lì sì wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá sí àyè tèmi.”+ 20  Síhónì kò sì ní ìdánilójú nípa gbígbà tí Ísírẹ́lì fẹ́ gba ìpínlẹ̀ rẹ̀ sọdá, Síhónì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọpọ̀, ó sì dó sí Jáhásì,+ ó sì ń bá Ísírẹ́lì jà.+ 21  Látàrí èyí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi Síhónì àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, tí wọ́n fi kọlù wọ́n, Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámórì tí ń gbé ilẹ̀ yẹn.+ 22  Báyìí ni wọ́n gba gbogbo ìpínlẹ̀ àwọn Ámórì láti Áánónì títí dé Jábókù àti láti aginjù títí dé Jọ́dánì.+ 23  “‘Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó lé àwọn Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì,+ tí ìwọ, ní tìrẹ, yóò sì lé wọn kúrò. 24  Kì  í ha ṣe ẹnì yòówù tí Kémóṣì+ ọlọ́run rẹ bá mú kí o lé kúrò ni ìwọ yóò lé kúrò bí? Àti olúkúlùkù ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá lé kúrò níwájú wa ni ẹni tí àwa yóò lé kúrò.+ 25  Wàyí o, ṣé o sàn ju Bálákì ọmọkùnrin Sípórì, ọba Móábù+ lọ ni? Òun ha bá Ísírẹ́lì fà á rí, tàbí ó ha bá wọn jà rí bí? 26  Nígbà tí Ísírẹ́lì ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì àti àwọn àrọko rẹ̀+ àti ní Áróérì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti ní gbogbo ìlú ńlá tí ó wà lẹ́bàá àwọn bèbè Áánónì fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún, kí wá ni ìdí tí ẹ kò fi fìgbà kan rí já wọn gbà ní àkókò yẹn?+ 27  Ní tèmi, èmi kò ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ń fi àìtọ́ bá mi lò nípa bíbá mi jà. Kí Jèhófà Onídàájọ́+ ṣe ìdájọ́ lónìí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Ámónì.’” 28  Ọba àwọn ọmọ Ámónì kò sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ Jẹ́fútà tí ó fi ránṣẹ́ sí i.+ 29  Ẹ̀mí Jèhófà bà lé Jẹ́fútà+ wàyí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí la Gílíádì àti Mánásè kọjá, ó sì la Mísípè ti Gílíádì+ kọjá, àti láti Mísípè ti Gílíádì ó kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì. 30  Nígbà náà ni Jẹ́fútà jẹ́ ẹ̀jẹ́+ kan fún Jèhófà, ó sì wí pé: “Bí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́ láìkùnà, 31  yóò sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé ẹni tí ó bá ń jáde bọ̀, tí ó jáde wá láti àwọn ilẹ̀kùn ilé mi láti pàdé mi nígbà tí mo bá padà dé ní àlàáfíà+ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, òun pẹ̀lú yóò di ti Jèhófà,+ èmi yóò sì fi ẹni náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.”+ 32  Nítorí náà, Jẹ́fútà kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì láti bá wọn jà, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n lé e lọ́wọ́. 33  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpakúpa púpọ̀ gan-an kọlù wọ́n láti Áróérì dé iyàn-níyàn Mínítì+—ogún ìlú ńlá—àti títí dé Ebẹli-kérámímù. Bí a ṣe tẹ àwọn ọmọ Ámónì lórí ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn. 34  Níkẹyìn, Jẹ́fútà wá sí Mísípà,+ sí ilé rẹ̀, sì wò ó! ọmọbìnrin rẹ̀ ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú lílu ìlù tanboríìnì àti ijó jíjó!+ Wàyí o, òun ni ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo gíro. Yàtọ̀ sí i kò ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. 35  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó tajú kán rí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí fa ara rẹ̀ lẹ́wù ya,+ ó sì wí pé: “Págà, ọmọbìnrin mi! O ti mú mi tẹ̀ ba ní tòótọ́, ìwọ fúnra rẹ sì ti di ẹni tí mo ń ta nù lẹ́gbẹ́. Èmi—èmi sì ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí padà.”+ 36  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Baba mi, bí o bá ti la ẹnu rẹ sí Jèhófà, ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde,+ níwọ̀n bí Jèhófà ti mú ìgbẹ̀san ṣẹ ní kíkún fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọ Ámónì.” 37  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún baba rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí a ṣe nǹkan yìí fún mi: Jọ̀wọ́ mi jẹ́ẹ́ fún oṣù méjì , sì jẹ́ kí n lọ, dájúdájú, èmi yóò sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sórí àwọn òkè ńlá, kí n sì sunkún lórí ipò wúńdíá mi,+ èmi àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi.’” 38  Látàrí èyí, ó wí pé: “Máa lọ!” Nítorí náà, ó rán an lọ fún oṣù méjì ; ó sì ń bá a nìṣó ní lílọ, òun pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ní sísunkún lórí ipò wúńdíá rẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá. 39  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin oṣù méjì pé ó padà wá sọ́dọ̀ baba rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí ó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó ti fi í jẹ́ ṣẹ.+ Ní tirẹ̀, kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí láé. Ó sì wá jẹ́ ìlànà ní Ísírẹ́lì pé: 40  Láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì a lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì, ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé