Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Onídàájọ́ 10:1-18

10  Wàyí o, lẹ́yìn Ábímélékì, Tólà ọmọkùnrin Púà, ọmọkùnrin Dódò, ọkùnrin kan láti inú Ísákárì, dìde láti gba Ísírẹ́lì là,+ ó sì ń gbé ní Ṣámírù ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù.+  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́tàlélógún, lẹ́yìn èyí tí ó kú, a sì sin ín sí Ṣámírù.  Nígbà náà ni Jáírì ọmọ Gílíádì+ dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó sì ń bá a lọ láti ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méjì lélógún.  Ó sì wá ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin tí ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán,+ wọ́n sì ní ọgbọ̀n ìlú ńlá. Ìwọ̀nyí ni wọ́n ń bá a lọ láti pè ní Hafotu-jáírì+ títí di òní yìí; wọ́n wà ní ilẹ̀ Gílíádì.  Lẹ́yìn ìyẹn, Jáírì kú, a sì sin ín sí Kámónì.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn Báálì+ àti àwọn ère Áṣítórétì+ àti àwọn ọlọ́run Síríà+ àti àwọn ọlọ́run Sídónì+ àti àwọn ọlọ́run Móábù+ àti àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ọlọ́run àwọn Filísínì.+ Nítorí náà, wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọn kò sì sìn ín.+  Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì,+ tí ó fi tà+ wọ́n sí ọwọ́ àwọn Filísínì+ àti sí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì.+  Nítorí náà, wọ́n fọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túútúú, wọ́n sì ni wọ́n lára lọ́nà bíbùáyà ní ọdún yẹn—fún ọdún méjì dínlógún, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ní ìhà Jọ́dánì ní ilẹ̀ àwọn Ámórì tí ó wà ní Gílíádì.  Àwọn ọmọ Ámónì a sì sọdá Jọ́dánì láti bá Júdà pàápàá àti Bẹ́ńjámínì àti ilé Éfúráímù jà; wàhálà-ọkàn sì bá Ísírẹ́lì gidigidi.+ 10  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ pé: “A ti ṣẹ̀+ sí ọ, nítorí tí a ti fi Ọlọ́run wa sílẹ̀, a sì ń sin àwọn Báálì.”+ 11  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì  í ha ṣe láti ọwọ́ Íjíbítì+ àti láti ọwọ́ àwọn Ámórì+ àti láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì+ àti láti ọwọ́ àwọn Filísínì+ 12  àti àwọn ọmọ Sídónì+ àti Ámálékì+ àti Mídíánì,+ nígbà tí wọ́n ń ni yín lára+ tí ẹ sì ń ké jáde sí mi, ni mo bẹ̀rẹ̀ sí gbà yín là kúrò ní ọwọ́ wọn? 13  Ẹ̀yin ní tiyín, ẹ pa mí tì,+ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn ọlọ́run mìíràn.+ Ìdí nìyẹn tí èmi kì yóò tún gbà yín là mọ́.+ 14  Ẹ lọ ké pe àwọn ọlọ́run+ tí ẹ ti yàn+ fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn ni kí ó gbà yín là ní àkókò wàhálà yín.” 15  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún Jèhófà pé: “A ti ṣẹ̀.+ Kí ìwọ fúnra rẹ ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ohunkóhun tí ó bá dára ní ojú rẹ.+ Kì kì pé kí o dá wa nídè, jọ̀wọ́, ní òní yìí.”+ 16  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò ní àárín wọn,+ wọ́n sì ń sin Jèhófà,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ọkàn+ rẹ̀ kò fi lélẹ̀ nítorí ìdààmú Ísírẹ́lì.+ 17  Nígbà tí ó ṣe, a pe àwọn ọmọ Ámónì+ jọ, wọ́n sì pabùdó sí Gílíádì.+ Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ara wọn jọpọ̀, wọ́n sì pabùdó sí Mísípà.+ 18  Àwọn ènìyàn àti àwọn ọmọ aládé Gílíádì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ọkùnrin wo ni yóò mú ipò iwájú ní bíbá àwọn ọmọ Ámónì+ jà? Kí ó di olórí gbogbo àwọn olùgbé Gílíádì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé