Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Àwọn Onídàájọ́ 1:1-36

1  Lẹ́yìn ikú+ Jóṣúà, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ta ni nínú wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, láti bá wọn jà?”  Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni yóò gòkè lọ.+ Wò ó! Dájúdájú, èmi yóò fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”  Nígbà náà ni Júdà wí fún Síméónì arákùnrin rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí a jọ gòkè lọ sí ìpín mi+ kí a sì bá àwọn ọmọ Kénáánì jà, èmi alára ẹ̀wẹ̀, yóò sì bá ọ lọ sí ìpín tìrẹ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Síméónì bá a lọ.+  Pẹ̀lú ìyẹn, Júdà gòkè lọ, Jèhófà sì fi àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì lé wọn lọ́wọ́,+ tí wọ́n fi ṣẹ́gun wọn ní Bésékì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin.  Nígbà tí wọ́n rí Adoni-bésékì ní Bésékì, wọ́n wá bá a jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì.+  Nígbà tí Adoni-bésékì fẹsẹ̀ fẹ, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ àti àwọn àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀ kúrò.  Látàrí èyí, Adoni-bésékì wí pé: “Àádọ́rin ọba tí a ti gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti àwọn àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn kúrò ni wọ́n wà, tí wọ́n ń ṣa oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run san án padà fún mi.”+ Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n mú un wá sí Jerúsálẹ́mù,+ ó sì kú níbẹ̀.  Síwájú sí i, àwọn ọmọ Júdà ń bá Jerúsálẹ́mù+ ja ogun nìṣó, wọ́n sì wá gbà á, wọ́n sì wá fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì gbé ìlú ńlá náà lé iná lọ́wọ́.  Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọmọ Júdà sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti Négébù+ àti Ṣẹ́fẹ́là+ jà. 10  Báyìí ni Júdà lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní Hébúrónì+ (wàyí o, orúkọ Hébúrónì ṣáájú ìyẹn ni Kiriati-ábà),+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Ṣéṣáì àti Áhímánì àti Tálímáì+ balẹ̀. 11  Wọ́n sì ti ibẹ̀ lọ gbéjà ko àwọn olùgbé Débírì.+ (Wàyí o, orúkọ Débírì ṣáájú ìyẹn ni Kiriati-séférì.)+ 12  Nígbà náà ni Kálébù+ sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọlu Kiriati-séférì, tí ó sì gbà á, họ́wù, èmi yóò fi Ákúsà+ ọmọbìnrin mi fún un ṣe aya.”+ 13  Ótíníẹ́lì+ ọmọkùnrin Kénásì,+ àbúrò+ Kálébù, sì gbà á. Nítorí ìyẹn, ó fi Ákúsà ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ṣe aya.+ 14  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sí ilé, ó ń ru ú lọ́kàn sókè ṣáá pé kí ó béèrè pápá kan lọ́wọ́ baba òun. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà pàtẹ́wọ́ bí ó ti wà lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ Látàrí èyí, Kálébù sọ fún un pé: “Kí ni o ń fẹ́?” 15  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Yọ̀ǹda ìbùkún+ kan fún mi, nítorí ilẹ̀ kan ní ìhà gúúsù ni o fún mi, kí o sì fún mi ní Guloti-máímù.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Kálébù fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì+ Ìsàlẹ̀. 16  Àwọn ọmọ ẹni tí í ṣe Kénì,+ tí Mósè jẹ́ ọkọ ọmọ rẹ̀,+ sì gòkè pẹ̀lú àwọn ọmọ Júdà láti ìlú ńlá onígi ọ̀pẹ+ wá sí aginjù Júdà, èyí tí ó wà ní gúúsù Árádì.+ Nígbà náà ni wọ́n lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn náà.+ 17  Ṣùgbọ́n Júdà ń lọ pẹ̀lú Síméónì arákùnrin rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé Séfátì, wọ́n sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Nípa bẹ́ẹ̀, orúkọ ìlú ńlá náà ni a pè ní Hóómà.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, Júdà gba Gásà+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti Ékírónì+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀. 19  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Júdà, tí wọ́n fi gba ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà, ṣùgbọ́n kò lè lé àwọn olùgbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ kúrò, nítorí tí wọ́n ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ onídòjé irin.+ 20  Nígbà tí wọ́n fi Hébúrónì fún Kálébù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti ṣèlérí,+ nígbà náà ni ó lé àwọn ọmọkùnrin Ánákì+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde níbẹ̀. 21  Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kò sì lé àwọn ará Jébúsì tí ń gbé Jerúsálẹ́mù+ jáde; ṣùgbọ́n àwọn ará Jébúsì ń bá a nìṣó ní gbígbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.+ 22  Láàárín àkókò yìí, ilé Jósẹ́fù+ pẹ̀lú gòkè lọ lòdì sí Bẹ́tẹ́lì,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn.+ 23  Ilé Jósẹ́fù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe amí+ Bẹ́tẹ́lì (ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ìlú ńlá náà ṣáájú ìyẹn ni Lúsì),+ 24  àwọn olùṣọ́ sì wá rí ọkùnrin kan tí ń jáde lọ láti ìlú ńlá náà. Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà láti gbà wọnú ìlú ńlá yìí hàn wá, àwa yóò sì ṣe inú rere sí ọ dájúdájú.”+ 25  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọkùnrin náà fi ọ̀nà láti gbà wọnú ìlú ńlá náà hàn wọ́n; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà+ kọlu ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ kí ó lọ.+ 26  Látàrí ìyẹn, ọkùnrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ ó sì tẹ ìlú ńlá kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì. Orúkọ rẹ̀ níyẹn títí di òní yìí. 27  Mánásè+ kò sì gba Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé ilẹ̀ yìí.+ 28  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Ísírẹ́lì di alágbára,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọmọ Kénáánì ṣe òpò àfipámúniṣe,+ wọn kò sì lé wọn jáde pátápátá.+ 29  Bẹ́ẹ̀ ni Éfúráímù kò lé àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní Gésérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín wọn ní Gésérì.+ 30  Sébúlúnì+ kò lé àwọn olùgbé Kítírónì àti àwọn olùgbé Náhálólì+ jáde, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín wọn,+ wọ́n sì wá fi wọ́n ṣe òpò àfipámúniṣe.+ 31  Áṣérì+ kò lé àwọn olùgbé Ákò àti àwọn olùgbé Sídónì+ àti Álábù àti Ákísíbù+ àti Hélíbà àti Áfíkì+ àti Réhóbù+ jáde. 32  Àwọn ọmọ Áṣérì sì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ilẹ̀ náà, nítorí tí wọn kò lé wọn jáde.+ 33  Náfútálì+ kò lé àwọn olùgbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti àwọn olùgbé Bẹti-ánátì+ jáde, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ ní gbígbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ilẹ̀ náà;+ àwọn olùgbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti ti Bẹti-ánátì sì di tiwọn fún òpò àfipámúniṣe.+ 34  Àwọn Ámórì sì ń bá a lọ láti ti àwọn ọmọ Dánì+ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, nítorí wọn kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.+ 35  Nítorí náà, àwọn Ámórì ń bá a lọ ní gbígbé ní Òkè Ńlá Hérésì àti Áíjálónì+ àti Ṣáálíbímù.+ Ṣùgbọ́n ọwọ́ ilé Jósẹ́fù rinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi fi ipá mú wọ́n wọnú iṣẹ́ ìmúnisìn.+ 36  Ìpínlẹ̀ àwọn Ámórì sì jẹ́ láti ìgòkè Ákírábímù,+ láti Sẹ́ẹ́là sókè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé