Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn ọ̀dọ́ bi ara wọn ní ìbéèrè pàtàkì yìí, ‘Kí ni mo fẹ́ fi ayé mi ṣe?’ Fara balẹ̀ ro ohun tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe bó o ṣe ń wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Andre, ọ̀dọ́kùnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èwo ló máa mú? Èwo ló máa jẹ́ káyé ẹ̀ nítumọ̀? Nínú àwọn fídíò kéékèèké míì tó bá fídíò yìí rìn, wàá rí àwọn ọ̀dọ́ tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, á sì jẹ́ kíwọ náà lè tún inú rò.