Torí pé ara èèyàn àti tàwọn ẹranko jọra láwọn ọ̀nà kan, Irène gbà pé ìyẹn bá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n mu. Àmọ́ iṣẹ́ eegun títò tó ń ṣe mú kó tún inú rò lórí ohun tó gbà gbọ́.