Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

“Máa Retí Ohun Tí A Kò Rí”

Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì fi ń wá bó ṣe máa ba ìwà títọ́ wa jẹ́, ó sì ń fẹ́ ká sọ̀rètí nù pátápátá. Báwo la ṣe lè máa pa ìwà títọ́ wa mọ́ nìṣó tá ò sì ní jẹ́ kí ìṣòro mú ká ṣe ohun tí kò tọ́?

“Máa Retí Ohun Tí A Kò Rí”—Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀

Ìdílé kan ń kojú ìṣòro kan tó jọ ti Jóòbù tí ìtàn rẹ̀ wà nínú ìwé Jóòbù nínú Bíbélì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè borí àdánwò ìgbàgbọ́ bíi ti ìdílé yìí.

“Máa Retí Ohun Tí A Kò Rí”

Fídíò tó wọni lọ́kàn gan-an yìí á mú kó o pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin, kí ìrètí tí Ọlọ́run ń fúnni sì máa gbé ọ ró.