Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 7

Ta Ni Jésù?

Ta Ni Jésù?

Jèhófà rán Jésù wá sí ayé. 1 Jòhánù 4:9

Ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ẹnì kan tóun náà ṣe pàtàkì. Tipẹ́tipẹ́ kí Jèhófà tó dá Ádámù ló ti dá ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan ní ọ̀run.

Nígbà tó yá, Jèhófà mú kí wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà bí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n sọ orúkọ ọmọ náà ní Jésù.—Jòhánù 6:38.

Nígbà tí Jésù jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù láìkù síbì kan. Ó jẹ́ onínúure, onífẹ̀ẹ́, ó sì jẹ́ni tó ṣeé sún mọ́. Ó fìgboyà kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà.

 Jésù ṣe ohun rere àmọ́ àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀. 1 Pétérù 2:21-24

Jésù tún wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì jí àwọn kan tó ti kú dìde.

Àwọn aṣáájú ìsìn kórìíra Jésù nítorí pé ó tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ìwà ibi wọn síta.

Àwọn aṣáájú ìsìn náà mú káwọn ará Róòmù na Jésù kí wọ́n sì pa á.