Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 11

Ǹjẹ́ Jèhófà Máa Ń Tẹ́tí Gbọ́ Wa?

Ǹjẹ́ Jèhófà Máa Ń Tẹ́tí Gbọ́ Wa?

Ó dájú pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa. 1 Pétérù 3:12

“Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. (Sáàmù 65:2) Ó fẹ́ ká máa sọ gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn wa fún òun.

Jèhófà ni kó o máa gbàdúrà sí, má ṣe gbàdúrà sí ẹlòmíì.

 A lè mẹ́nu kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nínú àdúrà wa. 1 Jòhánù 5:14

Gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.

Máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù kó o lè fi hàn pé o mọyì ohun tó ṣe fún ọ.

Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè máa ṣe ohun tó dáa. O tún lè gbàdúrà fún oúnjẹ, iṣẹ́, ilé gbígbé, aṣọ àti ìlera rẹ.