Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọlọ́run jẹ́ baba onífẹ̀ẹ́. 1 Pétérù 5:6, 7

Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún gan-an. Bí baba tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó sì tún jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe ń kọ́ gbogbo èèyàn níbi gbogbo nípa bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ.

Ọlọ́run ń jẹ́ ká mọ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó ń fún wa láyọ̀ tó sì jẹ́ ká nírètí.

Tó o bá tẹ́tí sí Ọlọ́run, yóò tọ́ ọ sọ́nà, yóò dáàbò bò ọ́, yóò sì jẹ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro.

Kò tán síbẹ̀ o, wàá tún wà láàyè títí láé!

 Ọlọ́run sọ fún wa pé: ‘Ẹ . . . wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ ó sì máa wà láàyè nìṣó.’ Aísáyà 55:3