Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 6

Kí La Rí Kọ́ Nínú Ìkún-omi Tó Wáyé?

Kí La Rí Kọ́ Nínú Ìkún-omi Tó Wáyé?

Ọlọ́run pa àwọn èèyàn búburú yẹn run, àmọ́ kò jẹ́ kí Nóà àti ìdílé rẹ̀ kú. Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 12, 23

Òjò rọ̀ fún odindi ogójì [40] ọ̀sán àti ogójì òru, omi sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé. Gbogbo àwọn èèyàn búburú ló kú.

Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà bọ́ àwọ̀ èèyàn sílẹ̀, wọ́n wá di ẹ̀mí èṣù.

Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ áàkì náà kò kú nígbà ìkún-omi yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ kú nígbà tó yá, Ọlọ́run yóò tún mú wọn pa dà wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n á sì lè wà láàyè títí láé.

 Ọlọ́run ṣì tún máa pa àwọn ẹni búburú run, yóò sì dá àwọn ẹni rere sí. Mátíù 24:37-39

Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣì ń bá a nìṣó láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.

Bí àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Nóà ṣe kọ etí ikún sí ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kọ etí ikún sí i lónìí. Láìpẹ́, Jèhófà yóò pa gbogbo àwọn ẹni búburú run.—2 Pétérù 2:5, 6.

Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n dà bíi Nóà. Wọ́n tẹ́tí sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ; àwọn èèyàn náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà..