Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 8

Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Jésù kú torí kí á lè wà láàyè. Jòhánù 3:16

Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn obìnrin kan lọ síbi ibojì rẹ̀, wọ́n sì rí i pé ibẹ̀ ṣófo. Jèhófà ti jí Jésù dìde.

Nígbà tó yá, Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà jí Jésù dìde, Jésù sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan tí kò lè kú mọ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí i bó ṣe ń lọ sí ọ̀run.

 Ọlọ́run jí Jésù dìde ó sì sọ ọ́ di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Dáníẹ́lì 7:13, 14

Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ kó lè fi san ìràpadà fún aráyé. (Mátíù 20:28) Lọ́lá ìràpadà yẹn, Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé.

Jèhófà fi Jésù jẹ Ọba tó máa ṣàkóso ayé. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] olóòótọ́ èèyàn tí Ọlọ́run jí dìde ní orí ilẹ̀ ayé tó sì mú wọn lọ sí ọ̀run ni yóò ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yìí ló máa para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, èyí tí yóò fi òdodo ṣàkóso.—Ìṣípayá 14:1-3.

Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì àti ebi mọ́. Àwọn èèyàn á láyọ̀ gan-an ni.—Sáàmù 145:16.