Ìwà búburú làwọn èèyàn tó pọ̀ jù nígbà ayé Nóà ń hù. Jẹ́nẹ́sísì 6:5

Ádámù àti Éfà ní àwọn ọmọ, àwọn èèyàn sì di púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìdìtẹ̀ rẹ̀.

Wọ́n wá sí ayé wọ́n sì gbé àwọ̀ ọkùnrin wọ̀ kí wọ́n lè fi àwọn obìnrin ṣe aya. Àwọn obìnrin yìí bí àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ òmìrán, ìyẹn àwọn ọmọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì ya ẹhànnà.

Ayé wá kún fún àwọn èèyàn tó ń hùwà ibi. Bíbélì sọ pé: “Ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”

 Nóà tẹ́tí sí Ọlọ́run, ó sì kan ọkọ̀ áàkì kan. Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14, 18, 19, 22

Èèyàn rere ni Nóà. Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa fi ìkún-omi pa àwọn èèyàn búburú náà run.

Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé kí ó kan ọkọ̀ ojú omi ńlá kan, tí Bíbélì pè ní áàkì, àti pé kí ó kó ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko lóríṣiríṣi sínú ọkọ̀ náà.

Nóà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa Ìkún-omi tó máa wáyé náà, àmọ́ àwọn èèyàn kò tẹ́tí sí ohun tó ń sọ. Àwọn kan fi Nóà rẹ́rìn-ín; àwọn míì sì kórìíra rẹ̀.

Nígbà tí Nóà parí ọkọ̀ áàkì náà, ó kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀.