Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 3

Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Àìmọye nǹkan rere ni Jèhófà fún Ádámù àti Éfà. Jẹ́nẹ́sísì 1:28

Jèhófà dá Éfà tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi í fún Ádámù pé kó fi ṣe aya.—Jẹ́nẹ́sísì 2:21, 22.

Jèhófà fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé, wọn kò ní àbùkù kankan rárá.

Ọgbà Édẹ́nì ni ilé wọn, ọgbà tó lẹ́wà gan-an ni. Àwọn odò, àwọn igi eléso àtàwọn ẹranko wà níbẹ̀.

Jèhófà máa ń bá wọn sọ̀rọ̀; ó máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n á wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

 Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà náà. Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17

Jèhófà fi igi eléso kan tó wà nínú ọgbà náà han Ádámù àti Éfà, ó wá sọ fún wọn pé tí wọ́n bá jẹ nínú èso igi náà, ṣe ni wọn yóò kú.

Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Sátánì Èṣù ni áńgẹ́lì búburú yẹn.

Sátánì kò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Nítorí náà, ó lo ejò kan láti sọ fún Éfà pé tó bá jẹ èso igi náà, kò ní kú, ṣe ló máa dà bí Ọlọ́run. Ó dájú pé irọ́ ni Sátánì pa.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé àti ìgbà tí ìyà máa dópin àti bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí àti àwọn tó máa gbé nínú lórí ilẹ̀ ayé.