Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 9

Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Àwọn wàhálà tó wà nínú ayé jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó dá sí ọ̀ràn náà. Lúùkù 21:10, 11; 2 Tímótì 3:1-5

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé àwọn èèyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ owó, aṣàìgbọràn sí òbí, òǹrorò àti olùfẹ́ adùn.

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára yóò wà, ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn. Gbogbo nǹkan yìí ló ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

Bákan náà, Jésù sọ pé a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé.—Mátíù 24:14.

 Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò. 2 Pétérù 3:13

Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo ẹni búburú run.

Jèhófà yóò fìyà jẹ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.

Àwọn tí wọ́n bá tẹ́tí sí Ọlọ́run yóò bọ́ sínú ayé tí òdodo yóò wà, níbi tí kò ti ní sí ìbẹ̀rù mọ́, táwọn èèyàn máa finú tán ara wọn, tí wọ́n sì máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn.