Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 10

Àwọn Ìbùkún Wo Làwọn Tó Bá Tẹ́tí sí Ọlọ́run Máa Rí Gbà?

Àwọn Ìbùkún Wo Làwọn Tó Bá Tẹ́tí sí Ọlọ́run Máa Rí Gbà?

Ọlọ́run yóò jí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òkú dìde sí orí ilẹ̀ ayé. Ìṣe 24:15

Ìwọ wo ìbùkún ọjọ́ ọ̀la tó o máa gbádùn tó o bá tẹ́tí sí Jèhófà! Wàá ní ìlera pípé, kò ní sẹ́nikẹ́ni tí yóò máa ṣàìsàn mọ́. Kò ní sáwọn èèyàn burúkú mọ́, wàá sì lè fọkàn tán gbogbo èèyàn.

Kò ní sí ìrora, ìbànújẹ́ àti ẹkún mọ́. A ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní kú mọ́.

 Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ni yóò yí ọ ká. Párádísè yóò dùn-ún gbé gan-an ni.

Kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́. Àwọn èèyàn á máa láyọ̀ gan-an.

Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Ìṣípayá 21:3, 4