Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 12

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?

Ìfẹ́ ló máa jẹ́ kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀. Éfésù 5:33

Ìlànà Ọlọ́run ni pé ọkùnrin kan àti obìnrin kan ni kí ó fẹ́ ara wọn.

Ọkọ tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ máa ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú aya rẹ̀, ó sì máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀.

Aya ní láti fọwọ́ so wọ́pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.

Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn.

 Ẹ jẹ́ onínúure àti olóòótọ́, ẹ má ṣe jẹ́ òǹrorò, ẹ má sì jẹ́ aláìṣòótọ́. Kólósè 3:5, 8-10

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bí ara òun fúnra rẹ̀ àti pé kí aya náà máa bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.

Kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ ẹni burú jáì. Ìkóbìnrinjọ náà sì burú jáì.

Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń jẹ́ kí ìdílé mọ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ aláyọ̀.