Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 1

Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?

Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?

Bíbélì ni Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀. 2 Tímótì 3:16

Ọlọ́run tòótọ́ mú kí àwọn èèyàn kọ èrò òun sínú ìwé mímọ́ kan. Ìwé náà ni Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó tí Ọlọ́run fẹ́ kó o mọ̀ ló wà nínú rẹ̀.

Ọlọ́run mọ ohun tó dára jù lọ fún wa, òun sì ni Orísun gbogbo ọgbọ́n. Bó o bá ń tẹ́tí sí i, ó dájú pé wàá jẹ́ ọlọ́gbọ́n.—Òwe 1:5.

Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn tó wà láyé máa ka Bíbélì. Bíbélì ti wà ní ọ̀pọ̀ èdè báyìí.

Bó o bá fẹ́ tẹ́tí sí Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì, kó o sì lóye rẹ̀.

 Níbi gbogbo ni àwọn èèyàn ti ń tẹ́tí sí Ọlọ́run. Mátíù 28:19

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye Bíbélì.

Kárí ayé ni à ń fi òtítọ́ nípa Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn.

A kì í gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn torí pé à ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. O tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó o bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.