Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 13

Kí La Lè Ṣe Láti Múnú Ọlọ́run Dùn?

Kí La Lè Ṣe Láti Múnú Ọlọ́run Dùn?

Yàgò fún ohun tó burú. 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10

Bá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní ṣe àwọn ohun tó kórìíra.

Jèhófà kò fẹ́ ká jalè, kò fẹ́ ká mutí para, kò sì fẹ́ ká máa lo oògùn nílòkulò.

Ọlọ́run kórìíra ìpànìyàn, ìṣẹ́yún àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Kò fẹ́ ká jẹ́ oníwọra, kò sì fẹ́ ká máa jà.

A kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn ère tàbí ká lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò.

Kò ní sáyè fún àwọn tó ń hùwà búburú nínú Párádísè orílẹ̀-ayé tó ń bọ̀.

 Máa ṣe àwọn ohun tó dára. Mátíù 7:12

áti lè múnú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ sapá láti dà bíi rẹ̀.

Máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nípa jíjẹ́ onínúure àti ọ̀làwọ́.

Jẹ́ olóòótọ́.

Jẹ́ aláàánú kó o sì máa dárí jini.

Máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ fún àwọn èèyàn.—Aísáyà 43:10.